Lai Mohammed: A ti gba 800 bílíọ̀nù padà lọ́wọ́ àwọn tó jíi kó, àwọn 1,400 ti dèrò ẹ̀wọ̀n

Lai

Oríṣun àwòrán, @thebridgenewsng

Ijọba apapọ ti sọ pe oun ti gba owo to le ni ẹgbẹrin bilọnu naira pada lọwọ awọn to jii ko.

Minisita fun eto iroyin at aṣa, Lai Mohammed lo kede bẹẹ nibi ipade awọn akọroyin kan to waye ni ilu Abuja.

O fi kun un pe egbeje eeyan lo ti n faṣọ penpe roko ọba bayii lẹyin ti aje iwa ajẹbanmu ṣi mọ wọn lori.

O ṣalaye pe "Gẹgẹ bi mo ṣe sọ tẹlẹ, ijọba to wa lode yii n doju ija kọ iwa jẹgudujẹra, a si ni ẹri lati gbe e lẹsẹ."

Minisita ọhun tẹ siwaju pe "Ijọba yii ni akọsilẹ awọn egbeje eeyan to wa ni ahamọ, bẹẹ ni a si ti gba owo to le ni ẹgbẹrin bilọnu naira pada, yatọ si awọn ohun ini ti agbẹsẹle."

Lai

Oríṣun àwòrán, @ScooperNG

O ni yatọ si gbigba owo ijọba ti awọn eeyan kan lu ni ponpo pada, ijọba to wa lode yii tun n ṣeto iyipada ọkan fun awọn ọmọ Naijiria ki iwa ajẹbanu lee di ohun igbagbe.

Lai pari ọrọ rẹ pe ki awọn to n bu ẹnu atẹ lu akitiyan ijọba to wa lode yii ronupiwada, ki wọn si dojukọ aṣeyọri ti ijọba n ṣe lati pana iwa jẹgudujẹra lorilẹ-ede yii.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun