Ondo election: Rotimi Akeredolu ti yan Lucky Orimisan Aiyedetiwa gẹ́gẹ́ bíi igbákejì tí wọ́n yóò jọ díje ní Ondo

Oríṣun àwòrán, others
Ni yajoyajo ni iroyin yii jade pe Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede ẹni ti yoo ba dije gẹgẹ bii igbakeji rẹ ninu eto idibo ti yoo waye ni ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.
Ogbeni Lucky Orimisan Aiyedetiwa to jẹ ọmọ bibi ilu Ilajẹ ẹsẹ odo ni ade naa ṣi mọ lori bayii.
Awọn mejeeji ni yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo naa to m bọ lọna.
Lucky ti figba kan jẹ aṣoju ipinlẹ Ondo ninu igbimọ to n ṣamojuto idagbasoke awọn ipinlẹ ẹlẹpo rọbi ti a mọ si Niger Delta Development Commission (NDDC).
Ajọ NDDC yii ni awọn Minsita ati olori wọn ṣi n jẹjọ lori inakuna owo ajọ naa lọwọ ni Abuja pẹlu sinima orita awoowotan loriṣiiriṣii.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe Eyitayo Jẹgẹdẹ to maa dije dupo gomina Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP naa ko ni pẹ kede igbakeji tirẹ naa.
Iran lounjẹ oju ni o ba de bayii ni ipinlẹ Ondo lasiko yii
- Ọwọ́ tẹ́ àwọn ọkùnrin Fulani mẹ́ta tí wọ́n jí Màálù méjì kó ní Ogbomọṣọ- Àjọ NSCDC
- Ṣé lóòótọ́ ni Amcon gba ilé Toke Makinwa ti wọn ní bàbá olówó rà á fun?
- Ọmọ́ Yorùbá korò ojú sí Buhari bí kò ṣe fi orúkọ Obasanjo sọ ibùdókọ̀ ojú'rin
- Irọ́ ni o, kò sí ẹ̀rí pé Hydroxychloroquine leè kojú àrùn Coronavirus- Ẹgbẹ́ àwọn adarí ilé ìwòsàn ní Naijiria
- Ìjọba Nàìjíríà kéde ìsinmi ọlọ́jọ́ méjì f'ọdún Iléyá

Oríṣun àwòrán, others
Mo káàbámọ̀ pé mo yan Ajayi gẹ́gẹ́ bíi igbákejì mi- Akeredolu
Rotimi Akeredolu sọ pé àṣìṣe nla ni yíyan Ajayi ní igbákejì òun
Aṣiṣe nla gba a ti mo kabamọ ni bi mo ṣe yan Agboola Ajayi ni igbakeji mi.
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lo sọ bẹ ẹ lori awuyewuye to n waye laarin oun ati igbakeji rẹ.
Akeredolu sọ ọrọ yii lasiko to ṣe ipolongo ibo lọ si ilu Igbekebo, nijọba ibilẹ Ese-Odo, tii ṣe ilu Ajayi, ni imurasilẹ fun eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC.
A gbọ pe Gomina Akeredolu sọ pe inu oun dun si bi Ajayi ṣe fi iru eniyan to jẹ han.
Ati pe atunṣe to dara ni kikuro ti Ajayi kuro l'ẹgbẹ APC jẹ fun ẹgbẹ naa.
Aawọ bẹrẹ laarin awọn awọn mejeeji lẹyin ti Ajayi naa fi erongba rẹ lati dije fun ipo gomina, han.
Aarin awọn mejeeji ti ko tooro si ti n da omi alaafia ru l'agbo oṣelu paapaa ni ẹgbẹ oṣelu APC ti ipinlẹ Ondo, paapa bi Ajayi ṣe ti darapọ mọ ẹgbẹ alatako, PDP.
Ọsẹ to kọja ni igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi pe fun ki wọn yọ Abẹnugan Ile Aṣofin ni ipinlẹ Ondo, David Oloyelogun.
Eyi ko ṣẹyin igbesẹ Ile Igbimo Aṣofin naa lati yọ ọ ni ipo.
Ile Igbimọ Asofin ti kọ iwe ranṣẹ si Adajọ Agba ni ipinlẹ Ondo, Oluwatoyin Akeredolu pe ki o gbe igbimọ kalẹ ti yoo se iwadii ẹsun ti wọn fi kan Agboola Ajayi.
Amọ, Adajọ Agba naa ko gba iwe ti wọn fi ranṣẹ sii, nitori iye awọn to dibo lati yọ igbakeji naa ko to ida meji ninu mẹta awọn ọmọ Ile Igbimọ Aṣofin.
Ninu atẹjade ti Igbakeji Gomina naa fi lede gba ọwọ oluranlọwọ rẹ, Allen Sowore ni idi ti awọn fi n pe fun ki wọn yọ Abẹnugan naa ni wi pe iṣẹ rẹ ko kujuwọn to.
Agboola Ajayi ni aikunjuwọn Abẹnugan naa farahan pẹlu bii Adajọ Agba ni ipinlẹ Ondo ṣe da iwe ti wọn kọ si lati bẹrẹ igbesẹ lati yọ oun ni ipo pada.
Ajayi fikun un pe igbeṣẹ rẹ gẹgẹ bi Abẹnugan ti ko ẹrẹ ati idọti ba eto ofin ni ipinlẹ Ondo.
Bakan naa ni Igbakeji Gomina naa gboriyin fun Adajọ Agba ni ipinlẹ Ondo fun iduro sinsin rẹ, to si tẹle ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/AGBOOLA AJAYI
Àkọ̀tun ìṣòro tún ti súyọ fún gómìnà Akeredolu l'Ondo
Kaka ki ewe agbọn dẹ ni ọrọ ọpọ wahala oselu ati ti isejọba to n doju kọ gomina Rotimi Akeredolu lọwọlọwọ bayii, ko ko ko lo n le si.
Laipẹ yii ni ọgọọrọ awọn eekan oselu to wa ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ondo n fi ẹgbẹ naa silẹ tabi kọwe fi ipo silẹ lẹyin gomina.

Oríṣun àwòrán, @Rotimi Akeredolu
Amọ wahala miran tun ti n rugbo bọ nipinlẹ naa bayii, eyi to lee mu ki ohun gbogbo pakasọ ninu isejọba gomina Akeredolu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?
- Wọ́n fi ikú Tunde Braimoh dá wa lóró ni o - Ẹbí pariwo
- Ẹ̀yin ọmọ ìta tó ní Funke Akindele ra ilé fún mi, irọ́ ni o - Ajirebi
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Báwo ni Coronavirus ṣe n tànkálẹ̀ l'Afrika?
Idi ni pe agbarijọpọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ osisẹ nipinlẹ Ondo naa ti n kọrin owe pe, awọn yoo maa wo isẹ niran nipinlẹ naa.
Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọru ni ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ondo da isẹ silẹ nitori bi ọgọọrọ wọn se n ku nitori aisi aabo to peye fun wọn lọwọ arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA
Idi ni pe awọn ẹgbẹ osisẹ ọhun ni awọn fẹ doju ija kọ gomina Akeredolu lori ọwọ yẹpẹrẹ to fi mu arun Coronavirus.
Wọn ni arun naa ti gba ẹmi ọpọ osisẹ eleto ilera, paapaa nitori aisi idaabo bo to yẹ fun wọn, ti Kọmisana feto ilera nipinlẹ naa si ti ba arun naa lọ.
Atẹjade kan ti ẹgbẹ osisẹ nipinlẹ Ondo fisita ni irọlẹ ọjọ Ẹti, eyi ti wọn kọ si gomina Akeredolu, ti wọn si tun fi le awọn akọroyin lọwọ, lo sisọ loju rẹ nipa iyansẹlodi ti wọn fẹ gunle.

Atẹjade naa, wa n kesi gomina ipinlẹ Ondo pe ko tete wa wọrọkọ fi se ada lori didaabo bo awọn osisẹ eleto ilera nipinlẹ naa, ti ina arun Coronavirus ti bọ si ọpọ wọn labẹ asọ.
"Ọga, lootọ ni ajọsepọ wa pẹlu yin dan mọrin lati ẹyin wa, a ko si fẹ ki ẹ maa fi oju aja inu iwe, ti ko lee se ọdẹ wo wa, ko to di pe a gbe igbesẹ to yẹ, nitori igi gogoro ma gun ni loju, ati okeere la ti n lọ ọ."

Lara awọn ohun ti awọn agbarijọpọ ẹgbẹ osisẹ naa tun n beere fun, ni owo osu kejila fawọn osisẹ ijọba ibilẹ ati ajọ Subeb.
Bakan naa ni wọn fẹ gba owo osu kinni ọdun 2017 fun gbogbo osisẹ pata ati owo ajẹmọnu isinmi lẹnu isẹ.
Wọn tun n fẹ ki gomina san owo ti wọn n yọ ninu owo osu wọn lati osu keji titi de osu kẹfa ọdun 2020.

Atẹjade naa wa n fa gomina leti titi di ọjọru, ọjọ kẹẹdogun osu Keje ọdun 2020, pe ko tete pe awọn si ipade lati fi ori kori lori ọrọ yii.
Ẹgbẹ osisẹ nipinlẹ Ondo wa n leri leka pebi gomina Akeredolu ko ba ṣe bẹẹ, ojo wahala osisẹ to ṣu, yoo bẹrẹ si ni rọ nipinlẹ naa.
Ẹmi mejila ṣofo ninu ijamba ọkọ l'Ondo

Oríṣun àwòrán, SOLA ILESANMI/ORANGE FM
Ojo buruku esu gb'omimu ni, nipinlẹ Ondo, nigbati ijamba ọkọ meji ọtọọtọ pa eniyan mẹwa ni agbegbe Akungba Akoko ati oju-ọnọ Ajibamidele ni popona marose Benin-Ọrẹ-si Eko nipinlẹ Ondo.
Iroyin sọ pe eniyan marun pẹlu iya arugbo kan ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ ni wọn padanu ẹmi wọn ni Akungba-Akoko, nigba ti ọkọ akero kọlu wọn, ni ẹgbẹ ọnọ ọja Ibaka ni agbegbe Ile-ẹk giga fasiti ti Akungba Akoko.
Ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ, ọgbẹni Muritala Rauf salaye wi pe ọkọ akero naa to n bọ lati agbegbe Ikarẹ ni o padanu ijanu ọkọ rẹ, ti awakọ si duna-dura lati yẹwọ fun ọkọ ayọkẹlẹ ti o wa lẹgbẹ ọja naa.

Oríṣun àwòrán, SOLA ILESANMI
Rauf wi pe ọpọlọpọ awọn oluraja ati onisowo ti o farapa ninu ijamba naa ni wọn ti ko lọ si ile-iwosan, ti awọn osisẹ ajọ FRSC ati ọlọpa si korajọ lati da alafia pada si agbegbe naa.
Olori osisẹ ajọ to nrisi eto irina lojupopo, (FRSC) nipinle Ondo, ọgbẹni Vincent Jack nigba ti o fi idi isẹlẹ naa mulẹ, sọ wi pe eniyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn, ti eniyan meji si parapa.
Bakan naa, awọn ti ọrọ naa soju wọn sọ pe ijamba ọkọ ti o waye ni popona marose ọrẹ waye latari bi ọkọ ayọkẹlẹ meji se n sare asapajude lati le wọ iwaju ara wọn. Eleyi ti o jasi ikọlu lojiji, ti o si la ẹmi eniyan meje lọ.

Oríṣun àwòrán, SOLA ILESANMI
Olori awọn osisẹ FRSC lagbegbe naa, Olusẹgun Ogungbemi sọ pe sisare asapajude loju popo lo s'okunfa ijamba naa, ti o si parọwa fun awọn arinrinajo ati awakọ lati maa se pẹlẹ loju popo.













