Cow rustlers caught: Ọwọ́ tẹ́ àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jí Màálù kó ní Ogbomọṣọ- Àjọ NSCDC

Oríṣun àwòrán, @IndependentNGR
Ajọ aabo ara ẹni laabo ilu ti a mọ si Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC) ti mu awọn ọkunrin mẹta ti wọn ji Maalu meji ko ni Ogbomọṣọ ni ipinlẹ Oyo to jẹ Guusu Iwọ oorun Naijiria.
Oga gba ajọ NSCDC ni Ibadan, Kọmandanti Iskilu Akinsanya lo fi iroyin yii to awọn akọroyin leti pe awọn ikọ akanṣe aabo lasiko yii ti wọn pe ni Agro Ranger lo gba awọn oniṣẹ ibi naa mu.
Akinsanya ṣalaye pe ninu ọja Kara to wa ni ilu Ogbomọsọ ni ọwọ ti tẹ wọn.
- Ọmọ́ Yorùbá korò ojú sí Buhari bí kò ṣe fi orúkọ Obasanjo sọ ibùdókọ̀ ojú'rin
- Ìjọba Nàìjíríà kéde ìsinmi ọlọ́jọ́ méjì f'ọdún Iléyá
- Irọ́ ni o, kò sí ẹ̀rí pé Hydroxychloroquine leè kojú àrùn Coronavirus - Ẹgbẹ́ àwọn adarí ilé ìwòsàn ní Naijiria
- Wọ́n kí irún Jimọ àkọ́kọ́ ní Hagai Sophia lẹ́yìn ọdún 85 ní Turkey
Orukọ awọn afurasi ti NSCDC fi sita naa ni ẹya Fulani ni awọn mẹtẹẹta ati pe orukọ wọn ni: Aliu Beidu ẹni ogun ọdun to wa lati ipinlẹ Niger, Buba Bello, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn to n gbe ni ipinlẹ Kwara ati Shatari Bello ẹni ogun ọdun lati Kwara.
Ogbeni Mohammed Bello labule Bolorunduro nijọba ibilẹ Oriire ni Ogbomọṣọ ni wọn lo ni Maalu meji ti awọn oniṣẹ ibi yii ko lọ.
Wọn ni awọn Maalu nla meji ti wọn ji ko naa to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ti wọn ba ta wọn (#500, 000) ti wọn ba ta wọn lasiko yii.
Akinsanya ṣalaye pe ọkan ninu wọn (Beidu) lo ranṣẹ pe awọn meji to ku ki wọn to jọ fọwọsowọpọ ji Maalu naa.
Bayii, wọn ti ko wọn si gbaga ni Olu ileeṣẹ NSCDC ni Agodi ni ilu Ibadan lẹyin ti ọwọ te wọn ni nkan bii aago meji ọsan ni Ogbomọṣọ.
Akinsanya ni wọn yoo foju ba ile ẹjọ ki Adajọ ṣe idajọ to yẹ fun wọn lẹyin ti iwadii ba pari pata ṣugbọn awọn mẹtẹẹta ti jẹwọ pe lootọ lawọn ji Maalu mejeeji.














