Hagia Sophia: Tayọ̀tayọ̀ làwọn Musulumi fi kí Jimọ níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọpọlọpọ Musulumi lo ya lọ si ile iṣembaye Hagai Sophia to wa ni Istanbul lorilẹ-ede Turkey.
Lẹyin ọdun marundinlaadọrun un ti wọn ti ti ile iṣẹmbaye yii pa fun awọn Musuilumi lo di ṣiṣi pada.
Gomina Ali Yerlikaya to n tukọ Istanbul ni gbogbo eeyan lo fẹ lọ kirun Jimọ akọkọ nile iṣembaye naa.
Aarẹ Erdogan lo ṣi gbongan naa pada lẹyin ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
- Ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ Iya Jogbo banújẹ́ lórí ìròyìn ikú rẹ̀
- Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn Adebayo Faleti, ìran Yorùbá ń ṣe ilédè rẹ!
- Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà dóòlà ẹ̀mí ẹni méjì ní Owena ní Ondo
- Wo àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abdulganiyu Abdulrasaq, bàbá gómìnà Kwara tó kú
- Ọ̀gá tíṣà rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he nílùú Eko fún ẹ̀sùn lílú jìbìtì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ìjọba ilẹ̀ Turkey yí ilé Ìṣẹ̀mbáyé tó ti lo ọdún 1,500 padà sí Mọ́ṣáláṣí
Hagia Sophia: Ìjọba ilẹ̀ Turkey yí ilé ìṣẹ̀mbáyé padà sí Mọ́ṣáláṣí
Ijọba ilẹ Turkey ti yi ile iṣembaye kan ti orukọ rẹ n jẹ Hagia Sophia si Mọṣalaṣi.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ ilẹ naa, Recep Tayyip Erdogan lo kede bẹẹ lẹyin ti ile ẹjọ kan fọwọ si pe ile naa ko yẹ ni aye ile iṣẹmbaye mọ.
Istanbul to jẹ olu ilu Turkey ni ibudo iṣẹmbaye yii wa ti wọn ko awọn nakn iṣura ati ohun itan orilẹ-ede Turkey si
Ile ọhun ti wọn kọ gẹgẹ bii Katidira ni nnkan bi ẹgbẹrun ọdun kan abọ ṣeyin ni wọn kọkọ yipada si Mọṣalaṣi lọdun 1453 lasiko ogun Ottoman.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin naa lo di ile iṣẹmbaye lọdun 1934 ti ajọ UNESCO si fọwọ si pe o jẹ ọkan lara awọn ile ti awọn eeyan le maa ṣabẹwo si.
Nigba to n sọrọ lori ayipada ile ọhun, oṣiṣẹ ijọba Turkey kan sọ pe awọn eeyan ṣi le maa ṣabẹwo si ile ọhun bo tilẹ jẹ pe o ti di Mọṣalaṣi bayii.
Awọn eeyan to le ni miliọnu mẹta abọ lo maa n ṣabẹwo silẹ naa lọdọọdun.
Kini ara ilu n sọ lori igbesẹ Aarẹ Turkey yii?
Adari ijọ Eastern Orthodox Church pẹlu awọn miran ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu igbesẹ Aarẹ Turkey yii.
Bakan naa ni minista fun àṣà ati iṣẹṣe, Lina Mendoni naa fi atẹjade sita pe igbesẹ naa ku diẹ kaa to.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni eyi fihan pe Aarẹ ko ka aṣa si mọ laye ode oni nitori ibudo iṣembaye naa ti wa fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Sugbọn ile ẹjọ to n ri si iṣẹlẹ apapọ ni Turkey ti ni Mọṣalaṣi ni iwe ilẹ ati fiorukó silé ibudo naa pẹlu ile iṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ilẹ pee lati ibẹrẹ.
Ile ẹjọ ni fun idi eyi, ko buru ti ijọba ba sọ ibudo iṣembaye naa di Mọṣalaṣi.
Ile ijọsin ni Russia to jẹ ibugbe awọn kristiẹni to pọju lọ naa ni o ṣeesẹ ki igbesẹ ijọba yii fa ẹlẹyamẹya ni eyi ti ko darar to lasiko yii.
Awọn musulumi kan ni Turkey fi idunnu wọn han lori igbese yii pe o dara.
Ibrahim Kalin to jẹ agbẹnusọ fun Aarẹ Turkey ni sisọ ibudo iṣẹmbaye yii di mọṣalaṣi ko di awọn arinrin ajo afẹ lọwo lati ṣi wa maa ṣe abẹwo sibẹ.
O ni koda, awọn ara ilu ṣi le maa yọju sibẹ nigba to ba wu wọn.












