Adebayo Faleti: Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn Adebayo Faleti, ìran Yorùbá ń ṣe ilédè rẹ!

Adebayo Faleti

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ilẹ n jẹ eeyan!!!

Ọpọ eeyan lagbo akada ati lagbo oṣere lo n ṣe ilede lẹyin Baba Adebayo ọmọ Faleti to re iwalẹ asa lọdun mẹta sẹyin.

Aṣaaju ni Adebayo ará Ijilejee, Akande Oloyemọyin ninu awọn nkan àrà to pọ to gbe ṣe nigba aye rẹ.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 1930 ni wọn bi Adebayo ni Agbo-Oye ni Oyo, ni guusu Iwo oorun Naijiria.

Oun ni ohun akọkọ to dun ni ori amohunmaworan akọkọ nilẹ Adulawọ iyẹn WNTV, (Western Nigeria Television) to ti di NTA bayii.

Àkọlé fídíò, Peters Ijagbemi dá àrá lórí ètò 'Ṣé o láyà' ti BBC Yorùbá lọ̀sẹ̀ yìí

Ọmọ Faleti a maa dari ere, a tun maa kó ere oniṣe, o n kọ ewi, o n ka ewi, o tun n kọ itan arosọ.

Adebayo jẹ akọbi lọkunrin fun baba rẹ, Joseph Akanbi Faleti, o si jẹ eleti kan ṣoṣo lọwọ iya rẹ, Durowade Ayinkẹ Faleti nitori ko ni ẹgbọn niwaju, ko si ni aburo lẹ́yìn.

O wu u lati kawe lati kekere ṣugbọn ko si agbara lọwọ awọn obi rẹ ni eyi to fi ko awọn kan jọ ti wọn fi bẹrẹ ẹgbẹ elere ti wọn pe ni Oyo Operatic Society lọdun 1949.

Funra rẹ lo kọkọ tu owo jọ lẹyin to ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun ko to tun bẹrẹ ile iwe pada

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Adebayọ Faleti lo tumọ orin ogo orilẹ-ede Naijiria si ede Yoruba to si tun fi igba pipẹ kọ akọsilẹ akanṣe fun awọn eekan oloṣelu bii Bola Ige, Oloye Ọbafẹmi Awolowo, Ernest Shonekan si ede Yoruba.

Diẹ lara awọn eto ti Mosobolaje Akande Faleti bẹrẹ ni: Ẹ dide, ẹ mu saari jẹ; Baba Keresi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O kawe ni Fasiti Dakar ni Senegal to ti kọ nipa ede Faranse ko to lọ Fasiti Ibadan.

Faleti pada kawe ni Fasiti ọlọgba ẹranko nibi ti sanmọnti gbe dunlẹ ni Ibadan to ti gboye imọ nipa Litireṣọ ede oyinbo.

Diẹ lara awọn ere to ti kopa ni Magun Thunderbolt (2001); Afọnja (2002); Baṣorun Gaa (2004); Sawo-Sọgbẹri (2005)

Àkọlé fídíò, Itan Ilu gangan

Adebayo Faleti gba oye ati ami ẹyẹ to pọ loriṣiriṣi bii OON, Justice of Peace, Afro-Hollywood Award for outstanding Performance in Arts ni America lọdun 2002, Breeze Award (Baṣọrun Gaa) ni London lọdun (2004) ati awọn miran.

Lara awọn ewi Faleti to gbajumọ ni Onibode Lalupọn, Alagbara Ile ati Alagbara Oko, Ijamba Odo Ọba, Adebimpe Ojedokun ati awọn miran.

O jade laye lọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2017.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an ọdun 2017 ni wọn sin Baba Faleti ni First Baptist Church, Isokun ni ilu oyo ni ipinlẹ Oyo ni guusu Iwọ oorun Naijiria.

Biṣọọbu agba, ayọ Ladigbolu lo waasu nibẹ, oun naa jẹekan ninu igbagbọ to wa lati ile Oba Ladigbolu ni Oyo.

Ayoola Faleti to jẹ akọbi Adebayo Faleti sọ nipa gbogbo ipa baba rẹ lati fi tọ wọn ni ilana ẹkọ to yẹ nigba to wa laye gẹgẹ bii obi rere si ọmọ.

Koda, Adeniyi Faleti, ọmọ baba Faleti to wa nile lasiko ti baba papoda ṣalaye fun ile iṣẹ iroyin Punch pe baba wẹ, o tọju ara rẹ daadaa lẹyin adura owurọ a-gba-papọ gẹgẹ bii ẹbi kan ti awọn ṣe tan.

O si sọ pe oun fẹ lọ sinmi ati pe oun gbadura ki Ọlorun gbe eeyan mii dide to maa wa pari iṣẹ yii nibi ti oun ba a de.

Adeniyi ni, lẹsẹkẹsẹ ni oun rii pe Baba ko mi daadaa mọ ti wọn si sare gbe baba lọ sile iwosan UCH to jẹ ti Fasiti Ibadan nibi ti wọn ti fidiẹ mulẹ pe baba ti re ibi ti awọn agba maa n re.

Ọkan lara awọn aya Baba, Moteniola ni iya ko le jẹ ọmọ Baba kankan nitoir pe gbogbo wọn lo kọ ni ẹkọ iwe bo ṣe yẹ.

Iyawo meji (Olubunmi àti Motẹniọla) ati ọmọ ati ọmọ ọmọ lo gbẹyin Baba Adebayo Faleti.