Satguru Maharaj Ji: Lẹ́yìn tí wọ́n fi kakata hú gbogbo iṣú àti ẹ̀gẹ́ mí, wọ́n tún ṣá àwọn ọmọ mi ládàá

Àkọlé fídíò, Satguru Maharaj Ji: Awọn ọmọ onílẹ̀ àti ọlọ́pàá jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti gba ilẹ̀ mí

Satguru Maharaji ti fẹ̀sùn kan pé àjọ ọlọ́pàá ní ìpińlẹ̀ Oyo pé wọn gbìmọ ọ̀tẹ pẹlú àwọn ọmọ onílẹ̀ láti gba ilẹ̀ òun.

Agbẹnusọ Maharaj, ọgbẹni Ojo Peter lo sọ eyi lasiko to ń ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ọmọ onílẹ̀ àti àwọn ọlọ́pàá ṣe yabo abúlé Maharaj ti àwọn ọlọ́pàá naa sì dúró tìwọn.

Awon olopaa lori ilẹ

Oríṣun àwòrán, Guru Maharaj

O ní sáájú ni ilẹ̀ náà ti ń dá wàhálà sílẹ̀ láàrin Guru Maharaj àti Adegoke Amao pẹ̀lú Ṣoara Atere.

Ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọdún 2016 pé ebí ìyá Aláàdọ́rin, ló nilẹ̀ tí Guru Maharaj sì ti ràá lọ́wọ́ wọ́n.

Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Iragbiji tún de pe àwọn gan an ní àwọn nilẹ̀,

Wọn ni o sì di dandan kí Satguru tún ilẹ̀ náà rà, àti ìgbà yìí ni wọ́n ti maa ń wá láti da omí aláafia abúlé Guru Maharaj rú

agbẹnusọ fun Guru, Ojo ni: Sátide, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ní àwọn ọmọ onílẹ̀ kan wa pẹlu awọn ọlọ́pàá láti wá fi katakata hú gbogbo ǹkan ti wọ́n gbìn sórí ilẹ̀ náà ti wọ́n sì tún ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn Maharaj tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ níbẹ̀ léṣe yánayàna.

Ojo ni: "Nígbà kan ti a lọ fi ẹjọ́ sùn nilé iṣẹ ọlọ́pàá "Toll gate" wọ́n padà dá ẹjọ náà nù ni lẹ́yìn tí wọ́n gbà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀."

Lásìkò yìí bákan náà, àwọn ọmọ onílẹ̀ kó àwọn ọlọ́pàá leyin ni ti wọ́n sì ṣe àwọn tó n ṣiṣẹ́ lóri oko náà léṣe'

Ó rọ ìjọba àpapọ àti ijọba ìpińlẹ̀ Oyo láti dá si ọ̀rọ̀ náà nítori ìdájọ ilé ẹjọ to waye ni 13/07/2016 ti parí ọ̀rọ̀ sùgbọ́n ti àwọn ọmọ onílẹ̀ Iragbiji tún wá lọ ń kó ọlọ́pàá sodí láti wá gba ilẹ̀ náà.

omo ise Guru

Oríṣun àwòrán, Satguru Maharaj

Kini ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ lori ẹsun Guru yii?

Nigba ti ileṣẹ iroyin BBC kan si ọdọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo lati fi idi ọrọ yii mulẹ, awọn agbofinro ni ọrọ ko ri bẹẹ.

Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi, ṣalaye pe oun gan an ko gbọ iru nkan to jó bẹẹ ri.

Fadeyi ni iru rẹ ko le ṣẹlẹ pe ki awọn agbofinro tẹlẹ awọn ọmọ onilẹ lọ maa ja lẹyin idajọ ile ẹjọ.

Eyi fihan pe, agbọn n ṣe bayii, ikamọdu naa n ṣe, bẹẹ oju oloko ree to wu yii.

Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí