Public Holiday: Ìjọba Nàìjíríà ya ọjọ́ méjì sọtọ̀ fún ìsinmi ọdún Iléyá

Aworan ọkunrin to gbe agbo kọrun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba Naijiria ti kede ọjọbọ ati ọjọ Ẹti gẹgẹ bi ọjọ isinmi fayajọ ọdun Eid-ul Adha lorileede Naijiria.

Ọdun yi tọpọ mọ si ọdun Ileya tabi Sallah jẹ ọdun kan pataki fawọn Musulumi Naijiria ati awọn akẹgbẹ wọn jakejado agbaye.

Minisita Naijiria feto ọrọ abẹle Rauf Aregbesola lo fi ikede ọrọ yi sita lorukọ ijọba.

Àkọlé fídíò, Saudi Arabia Hajj 2020: Alaga Hajj ni Naijiria ni inú wọn kò dùn sí bí Hajj kò ṣe ní wáyé.
Àkọlé fídíò, Ileya: Àgbò wọ́n torí ọjà ẹran mẹ́ta ni wọ́n tìpa lókè ọya torí Boko Haram

Ninu ọrọ rẹ Aregbesola rọ awon musulumi lati fasiko yii gbadura fun alaafia ati idagbasoke orileede Naijiria.

Bẹẹ lo fi ikini ranṣẹ si awọn ọmọ Naijiria nile loko lẹyin odi pe wọn ku ajọdun ọdun Ileya.

Lọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun yi ni ajọdun ileya tọdun yi bọ si.

Lọpọ igba awọn ayẹyẹ maa n tẹle ọdun ileya ṣugbọn nitori ajakalẹ arun Covid 19, ko ni fi bẹ si pọpọṣinṣin lasiko Ileya tọdun yi.

Ni awọn ipinlẹ bi Kano awọn alaṣẹ ti fofin de ṣiṣe awọn eto kan to maa n tẹle Sallah bi Durbar tawọn eeyan ti maa n gun ẹṣin ati awọn faaji miran.

Kọmisana feto iroyin Kano Mohammed Garba sọ pe nitori pe awọn fẹ dena itankalẹ Covid-19 lawọn fi ṣe bẹ.

Àkọlé fídíò, ''Ọjà ẹran àgbò kò yá bí ti ọdún tó lọ''

Ayẹyẹ ọdun Ileya a maa waye lati fi kasẹ eto Hajj nilẹ lẹyin tawọn to lọ irinajo mimọ ba ti dari lati Oke Arafat ni Makkah.

O le ni miliọnu meji alalaaji to maa n kopa ninu Hajj ọlọdọọdun yi.

Ẹ jókòó sí ilẹ̀ yín gbogbo ẹ̀yín tó fẹ́ lọ sí Mecca

Awọn ọmọ Naijiria to fẹ lọ si Mecca fun Hajj kekere,Unrah ni wọn ti sọ fun ki wọn joko si ile wọn ati orilẹede wọn.

Ijọba ilẹ Saudi Arabia lo kede naa lati dẹkun aarun coronavirus to ti pa ẹgbẹgbẹrun eniyan kaakiri agbaye.

Zikirullah Hassan to jẹ alaga ajọ to n risi ọrọ to niiṣẹ pẹlu awọn ẹlẹsin musulumi lorilẹede Naijiria, NAHCON ni ijọba Saudi gbe igbesẹ naa lati da abo bo awọn eniyan ilu naa nitori wọn ko i tii rojutu aisan naa.

Alaga ajọ NAHCON naa ni o le ni aadọta ọmọ Naijiria to wa ni Saudi lọwọlọwọ,ati wi pe ijọba ko le wọn kuro nilẹ naa nitori wọn ṣe ayẹwo fun wọn , ti wọn si mọ wi pe ko si aarun naa ni Naijiria.

Hassan ni lasiko ti awọn ṣe ipade pẹlu ijọba ilẹ Saudi ni wọn sọ fun awọn wi pe awọn eleto ilera awọn n ṣe eto ilẹra fun awọn eniyan, amọ awọn fẹ ri aridaju lati orilẹede toku wi pe wọn kapa arun naa ki wọn to gbe igbesẹ le e lori.

O gbadura wi pe arun naa yoo kaṣẹ̀ nilẹ ni kia, ki awọn eniyan ma ba a ni idiwọ idena pipa jijade ati iwọle si awọn ibi adura.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alaga ajọ NAHCON naa ni ipinnu rere ni nkan ti awọn alaṣẹ ijọba ilẹ naa ṣe lati da abo bo awọn ti wọn wa lorilẹede naa.

Ẹgbẹgbẹrun eniyan lo ti ku latari itankalẹ aarun coronavirus naa, to bẹ silẹ ni ilu Wuhan, lorilẹede China, to si ti tan kalẹ de awọn orilẹede miran lagbayẹ.

Amọ ko i ti si ẹni to lugbadi aarun naa lorilẹede Naijiria,awọn mọkanla ti wọn ṣe ayẹwo fun ni wọn ri wi pe ko ni aarun naa lara.