Tiamiyu Kazeem: Gbogbo egungun Tiamiyu ló kán lẹ́yìn tí wọ́n tì í jábọ́ nínú ọkọ̀

Àkọlé fídíò, Saani: Gbogbo egungun Tiamiyu ló kán lẹ́yìn tí wọ́n tì í jábọ́ nínú ọkọ̀

Ọrẹ Tiamiyu, Sannni ni oun ni awọn ọlọpaa SARS kọkọ ri ninu ọkọ ni nkan bi aago mẹwa ninu ọkọ Tiamiyu.

Sanni sọ iriri rẹ fun BBC Yoruba lẹyin iku igbakeji Balogun Ikọ Remo Stars, Tiamiyu Kazeem ti wọn fẹsun kan pe awọn ọlọpaa SARS ṣekupa.

O ni inu ọkọ wọn ni wọn gbe Tiamiyu si, ti wọn si sọ wi pe ki oun joko sinu ọkọ Tiamiyu ti ọlọpaa SARS naa si n wa oun.

Sanni ni lojiji ni wọn ti ọrẹ oun jade kuro ninu ọkọ ti, ti ọkọ ti ohun bọ si gba a to fi fọ kọja si idakeji titI.

Ẹkunrẹrẹ fidio naa re e: