Boko Haram: Ìjọba ń ṣètọ́jú àwọn Boko Haram tó rónúpìwàdà, àwọn àgbààgbà Yorùbá fà ìjọba létí

Oloye Olu Falae

Oríṣun àwòrán, PremiumTimes

Awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti fesi si igbesẹ ijọba lati da awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram kan pada saarin ilu wọn.

BBC Yoruba kan si agba ilẹ Yoruba ati eekan ninu oṣelu, Oloye Olu Falae to sọ wi pe lootọ o yẹ ki a tọju awọn agbesunmọmi to ba ronupiwada ṣugbọn ka ri i daju pe wọn ti ronupiwada ni tootọ.

O ni ṣugbọn o ṣeeṣe ki awọn akọluni nigba mii dibọn bii pe wọn ronupiwada ki wọn le wọ eeyan lara daadaa ṣugbọn awa gbudọ da ara wa loju pe wọn ti jẹwọ wọn si kọ ohun gbogbo to kọkọ ti wọn si didara pọ mọ Boko Haram patapata.

Ọmọ ẹgbẹ Boko Haram marunlelogun to yipada naa ti gunlẹ si ilu Maiduguri tii ṣe olu ilu ipinlẹ Borno lẹyin ti ijọba Naijiria da wọn silẹ lalafia.

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'

Iroyin sọ wi pe lara awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ti wọn da silẹ naa ni ọkunrin, obinrin atawọn ọmọde wa ti wọn da tọwọ wọn silẹ fun awọn ikọ ogun Niger Republic.

Awọn agbesunmọmi tẹlẹri yii gunlẹ si ilu Maiduguri ninu ọkọ baalu awọn ologun ti awọn ologun si sin wọn wa lati ko wọn lọ ibudo itọju ti ijọba pese fun wọn fun itọju, jijẹ mimu ati ẹkọṣẹ ki wọn to lee ko wọn lọ ba awọn mọlẹbi wọn.

"O yẹ ki awọn onimọ nipa aabo, imọ nipa ọpọlọ eeyan ba wọn sọrọ ki wọn si fun wa ni idaniloju pe wọn ti wẹ yan kainkain lati dara pọ mọ ilu ko ma lọ jẹ wipe bi ẹ ṣe n di mọ wọn gbagi, ọbẹ n bẹ lẹyin ṣokoto, ẹni bẹẹ dero ọrun niyẹn".

Falae ni "mo mọ tori mo ti b sọwọ awọn ajinigbe ri fun oṣu mẹrin mo si mọ ohun ti oju mi ri, ọpẹlọpẹ Ọlọrun to ko mi yọ tori eyi, a ni lati ṣọra gidi gan".

O tẹnu mọ ọ pe dida wọn pada saarin ilu gbudọ jẹ ni pẹlẹ kutu ni ko gbudọ jẹ asare ṣe.

Bakan naa, Ọmọwe Olajide ni ao lee faaye gba eleyii nibi ti aye le de lode oni yii. Oun naa mu ọrọ lati ibi ti Oloye Falae duro si.

"Koda bi wọn ba ṣẹṣẹ de, o yẹ ki kọ ibudo kan to jina tefetefe si ilu fun wọn na ki wọn tilẹ lo bi aadọta si ọgọrun ọdun titi a o fi bori awọn to ku wọn tori lana alana wọn ṣi kọlu ilu kan".

Olajide ni o ti ya ijọba ju lati ni awọn fẹ tete da wọn pada sinu ilu eyi yoo si maa ṣe moriya fun awọn ọdọ alainiṣẹ lati maa dara pọ mọ Boko Haram, wn tun pada wale pe awọn ronupiwada ki wọn lee tun jẹ owo lara ijọba.

O ni bi o tilẹ jẹ pe ootọ ni pe ara wa ni wọn tẹlẹ gẹgẹ bii ọmọ, ẹgbọn , aburo "hmmmn ṣugbọn a gbudọ ṣọra tori wọn lee pada di alami fun awọn Boko Haram ẹgbẹ wọn to ku nita".