Ambode probe: Ambode m'òfo nílé ẹjọ́ lóríi pé k'áwọn aṣòfin yéé tojú bọ ọ̀rọ̀ ọkọ̀ bọ́ọ̀sì 820 tó rà

Ambode

Oríṣun àwòrán, Google

Ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Eko ti fagile ipẹjọ kan ti gomina ana ti ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambode to n pe fun ki awọn aṣofin ipinlẹ ma ki oju bọ ọrọ pe o ra bọ́ọ̀sì ojilelẹgbẹrin fun akanṣe iṣẹ atunṣe to ṣe ni saa rẹ gẹgẹ bii gomina.

Lọdun to kọja ni iroyin tan ka pe ile aṣofin ipinlẹ Eko ti tutọ soke pe awọn yoo fi ọlọpaa mu Gomina ana ipinlẹ naa, Akinwumi Ambode lori ẹsun ṣiṣe owo ọba kumọkumọ.

Ile iṣẹ iroyin News Agency of Nigeria (NAN) fabọ jẹni pe adajọ Yetunde Adesanya fagile e wi pe igbimọ ti yoo wa ojulowo ọrọ ni igbimọ ti wọn gbe kalẹ.

Bi iroyin ṣe sọ, alaga igbimọ iwadii naa, aṣoju Fatai Mojeed lawọn rii wi pe Gomina Ambode ko tẹle ilana to yẹ ki wọn to ra awọn ọkọ akero 820

Gẹgẹ bi adajọ naa ṣe sọ ọ, iwadii yatọ fun fifi ẹsun kan eeyan.

O ni "ko tii di pe ẹsun ni wọn fi kan olupẹjọ naa (Ambode). Bi ileeṣẹ ijọba kan ba fiwe pe 'ni ko lee tumọ si pe wọn n dun mọhurumọhuru mọ ẹtọ olupẹjọ".

"Tori naa mo sọ wi pe igbesẹ olupẹjọ naa ni iwe ipe si ile ẹjọ lati ka agbara igbesẹ awọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ko eyi to ni ṣe pẹlu abala 128, 129 ninu iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999.

Adajọ ni eyi kii ṣe ojuṣe ile ẹjọ bẹẹ si ni ile ẹjọ kankan ko gbudọ gba iru ipe bẹẹ rara. "Fun idi eyi, a fagile iwe ipe olupẹjọ naa".

Awọn mii ti ọrọ yii kan ni Ọgbni Fatai Mojeed, alaga igbimọ sarenbaja atawọn ọmọ igbimọ ọhun mẹjọ mii ti ile aṣofin Eko gbe silẹ lati bojuwo rira awọn bọ́ọ̀sì naa.

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'