Alaafin Ọyọ Queens: Ǹjẹ́ o mọ àwọn olorì àkọ́fẹ́ Aláàfin Adeyẹmi? Àwọn rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Ni ilẹ Yoruba, Ọbaọlọla Olowo, ẹni ti ọba yẹ loye ati eeyan nla ni Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta.
Atọbatẹlẹ si la lee pe Atanda Alowolodu bii iyere, nitori aati igba ewe lo ti n se bi ọba ati eeyan nla.

Oríṣun àwòrán, Mujidat Adeyemi facebook
Bi o tilẹ jẹ pe Kabiyesi ni ọpọ ayaba ninu aafin rẹ, tawọn olo, arẹwa ẹlẹyinju ẹgẹ ati ẹlẹ Daddy si kun inu agbala rẹ babi, sibẹ awọn obinrin miran wa to n gbe ẹmi ọba Adeyemi ro.
- A fura pé ejò lọ́wọ́ nínú ikú Tolu Arotile, ẹ ṣe ìwádìí ikú rẹ̀ - Afenifere, Gani Adams, Huriwa
- Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú
- Mo ti pinnu láti túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lóríì ìdí tí kò sí ìdàgbàsókè ní Niger Delta - Buhari
- Ènìyàn 156 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì ààrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Eko
Ki o to di pe awọn apọnbeporẹ olori de sinu aye Ọba Adeyemi, awọn obinrin to fẹ nigba ewe rẹ naa wa, ti wọn si jẹ igi lẹyin ọgba fun Alaafin.
Bi oriade yii si ti n ṣetọju awọn ẹlẹyinju ẹgẹ, naa ni ko gbagbe awọn aya igba ọdọ rẹ, to si n bu ọla ati iyi fun wọn pẹlu, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ wọn ti dagba, ti wọn si ti ni ọmọ-ọmọ.
Diẹ lara awọn aya igba ọdọ Alaafin ree, ti kii kọ iyan wọn kere rara:
Olori Abibat Nihinlola Adeyemi ( Iya Adodo) :

Oríṣun àwòrán, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta
Olori Abibat Nihinlola ni iyawo akọfẹ Ọba Adeyemi, ti Ọlọrun si fun awọn mejeeji ni ẹmi gigun, alaafia ati ọmọ rere lati ba ara wọn kalẹ.
Olori agba yii, ti ọpọ eeyan ninu aafin n pe ni Iya Adodo ko ni mọra, a si lee ni ori rẹ lo sunwọn, to ran igba awọn ayaba miran ti wọn tẹle lati wa fẹ Ọba Adeyemi.

Oríṣun àwòrán, Olori Abibat Adeyemi
Igba ti Ọba Adeyemi ko si ti ni owo tabi lọla ni olori Abibat ti fẹ, awọn mejeeji si dijọ pilẹ ọla ni gẹgẹ bii tọkọtaya.
Ọjọ ori Olori Abibat ko fi bẹẹ kere si ti Alaafin, koda, a gbọ pe ọjọ ori wọn sunmọ ara wọn nitori mama yii naa ti se ọjọ ibi ọdun kọkanlelọgọrin loke eepẹ.

Oríṣun àwòrán, Olori Abibat Adeyemi
Ọjọ Kẹtalelogun osu Kejila 1939 ni wọn bi Iya Adodo, ti o si ti ri ọmọ-ọmọ ati arọmọdọmọ rẹ, to si ti pe ọgọta ọdun ti oun ati Ọba Adeyemi ti fẹ ara wọn.
Olori Ramat Adedayo Adeyemi (Iya Koto):

Oríṣun àwòrán, Olori Ramat Adedayo Adeyemi
Olori Ramat Adedayo Adeyemi ni ayaba keji to dagba julọ ninu aafin Ọyọ, oun si ni Ọba Adeyemi fẹ sikeji ninu awọn olori rẹ.
Olori Adedayo ati iyale rẹ, Olori Nihinlola ni iyawo meji ti Olayiwola Adeyemi ni lọọdẹ, ko to di Alaafin tilu Ọyọ, awọn mejeeji si ni wọn wa pẹlu rẹ lasiko to n jẹ ọba.

Oríṣun àwòrán, Olori Ramat Adedayo Adeyemi
Ọpọ eeyan lo maa n pe Olori Adedayo ni Iya Ile Koto abi Iya Koto, ojuse rẹ si ni lati maa tọ awọn olori kekeke sọna nipa ise ati ihuwasi to yẹ olori, to fi mọ awọn asa adayeba ilẹ Yoruba.
Gẹ gẹ gẹ si ni awọn ayaba kekere maa n gbe olori agba yii nitori pataki ipo rẹ ninu aafin, ti iya naa si ti pe ẹni ọdun mẹtalelaadọrin loke eepẹ.
Ọgbọnjọ osu Kẹfa ọdun 1943 si lo de ile aye.
Ọba Adeyemi ati Olori Ramat Adedayo Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Olori Ramat Adedayo Adeyemi
Olori Adedayo ati Ọba Adeyemi kii fi ifẹ aarin wọn pamọ rara titi di akoko yii, paapaa, ti eeyan ba pade wọn ni ode ariya.
Awọn mejeeji jọ maa n lọ sode daada, ti wọn yoo dijọ fẹsẹ ra ijo, ti awọn ayaba kekeke to ba si wa nibẹ, yoo lọ wa ibi joko si, wọn a ni ọlọkọ lo n lo ọkọ rẹ.
Ayaba Suliat Motunrayo Adeyemi:

Oríṣun àwòrán, Ayaba Motunrayo Adeyemi
Ọkan lara awọn olori aagba to n sikẹ Ọba Adeyemi ni Ayaba Suliat Motunrayo Abeke Adeyemi.
Olori yii tutu niwa, ti awọn eeyan ko si fẹẹ mọ ohun pupọ nipa rẹ lori ayelujara.
Olori Mujidat Adeyemi:

Oríṣun àwòrán, Mujidat Adeyemi facebook
Olori miran ti ko si lara awọn Ẹlẹ Daddy, amọ ti Ọba Adeyemi ko jẹ fi sere ni Olori Mujidat Adeyemi.
Olori Mujidat naa kii pariwo amọ ojuse rẹ ni aafin Ọyọ ko se fi sere rara.













