Alaafin Adeyemi: Lára àwọn òrékelẹ́wà ayaba náà ló dẹnu ìfẹ́ kọ Ọba Adeyemi fúnra wọn kí Kabiesi tó wàjà

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi 111 Facebook
Ojọ Abameta, ọjọ́ ketalelogun, osu kerin, ọdun 2022 ni Oba Atanda Lamidi Adeyemi kẹta dagbere faye pe o digbose.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
Ni kete ti Alówólódù si ti wọ káà ilẹ̀ ni awọn eeyan ti n beere pe melo ninu awọn orekelewa, ti ọpọ n pe ni 'Oxygen' afẹfẹ ti Oba Olayiwola Atanda fi n mi lo maa ṣe opo ipapoda olowo ori gbogbo wọn?
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Eyi lo je ki BBC Yoruba se akojopo iroyin nipa awọn 'ẹ̀lẹ̀ Daddy' naa wo.
- Àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí tó ń pèsè àdó olóró fún IPOB
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Emmanuel Macron borí Le Pen ní ìbò ààrẹ France
- Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi wọ káà ilẹ̀ lọ ní Báárà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀
- Èyí lohun tí Aisha Buhari sọ fáwọn olùdíje dupò ààrẹ ní Nàìjíríà níbi àpèjẹ ìṣínu Iftah tó pè
Wo ọ̀nà tí àwọn 'ẹ̀lẹ̀ Daddy' gbà dé ààfin Ọyọ
Ni ọjọ mẹta diẹ sẹyin, a mu iroyin kan wa fun un yin, ninu eyi ti Alaafin ti kede nigba aye rẹ pe, oun kii dẹnu kọ obinrin, o wu awọn iyawo oun, ni wọn fẹ oun funra wọn.
Bakan naa, laipẹ yii la tun kọ iroyin miran nipa awọn olo, ẹlẹjẹ tutu mẹjọ ti wọn n gbe ẹmi Alaafin tilu Ọyọ Èyí ni àwọn arẹwà ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’, àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí .
Awọn ẹlẹ wọnyii lo n gbe ẹmi Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ro, ni aafin rẹ lọwọlọwọ.
Bawo ni alaafin ṣe n dẹnu ifẹ kọ awọn ọdọmọde arẹwa wọnyii?
Amọ, ọpọ eeyan to ka iroyin naa lo n beere pe, bawo ni Alaafin, ẹni to ti le ni ọdun mọkanlelọgọrin loke eepẹ, se dẹnu ifẹ kọ awọn arẹwa yii?
Wọn ni niwọn igba to se pe Alaafin kọ lo dẹnu kọ awọn obinrin naa, bawo ni awọn ẹlẹ Daddy se n de inu aafin lati di olori?
Ọna lati wa idahun sawọn ibeere yii lo mu ki BBC Yoruba fi imu finlẹ, lati mọ bi ọpọ awọn ayaba naa se di olori laafin.

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi 111 Facebook
Gẹgẹ bi iwadii wa ti safihan rẹ, diẹ lara awọn olori yii lo jẹ akẹkọọ nilu Oyọ, ti ifẹ Ọba Adeyemi si gba ọkan wọn.
A gbọ pe lati ile ẹkọ ni diẹ lara awọn olori naa ti n pohungbẹ lati di ayaba, ti wọn si n sunmọ awọn eeyan to wa ni aafin Ọyọ.
Iroyin naa fi kun un pe, diẹ diẹ imu ẹlẹdẹ wọn wọ ọgba tan, ti wọn raye sunmọ aafin, ti wọn si ni nọmba Kabiyesi lọwọ.
Asiko ti wọn si ri aaye sunmọ Ọba Adeyemi ni wọn n fi ọrọ ransẹ lori aago pe awọn nifẹ rẹ, to si wu awọn lati di olori laafin rẹ.
- MKO Abiola, iṣẹ́ aṣẹ́gità ló fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò
- Iṣọla Oyenusi rèé, ẹnití ìfẹ́ obìnrin ṣun dé ìwà ìdigunjalè
- Taiwo Akinkunmi, ọmọ Ibadan tó ya àsìá Naijiria
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...’ rèé
- Afọnja, ẹni tó finú wénú ní Ilọrin, àmọ́ tó jẹ iwọ
Niwọn igba to si jẹ pe ọba kii kọ obinrin, agbalagba si maa n gba mọra ni.
Idi ree ti Alaafin fi jẹ hoo fun awọn agunlẹyinju obinrin yii, ti wọn si di ayaba ni Aafin Ọyọ.
Koda, mẹta ninu awọn olori naa la gbọ pe o wa nile ẹkọ olukọni onipo kinni to wa nilu Ọyọ, ( Emmanuel Alayande College of Education, Oyo) lasiko ti wọn fi ifẹ han si Alaafin pe, awọn fẹ jẹ olori rẹ.

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi 111 Facebook
Koda, Alaafin funra rẹ gan an sisọ loju rẹ nigba kan pe, oun maa n ran awọn olori yii lọ sile iwe lẹyin ti wọn ba de ọdọ oun tan, ki wọn le tẹsiwaju lẹnu ẹkọ wọn.
Bẹẹ si ni diẹ lara awọn ọdọmọde arẹwa olori yii lo ti kẹkọọ jade nile ẹkọ fasiti pẹlu oye imọ ijinlẹ akọkọ.
Ati pe wọn kii pa mọra lati jẹ ki araye mọ pe Ọba Adeyemi lo n se atilẹyin fun awọn Olori rẹ.
Nibayi aya ti mọ oju ọkọ, ọkọ naa si ti mọ oju aya, awọn iyawo naa ti bi isun, wọn ti bi iwalẹ fun Alaafin, awọn alarena naa si ti yẹba.














