Aláàfin of Oyo dead: Wọ́n ti fẹ́ gbé Alaafin lọ ibi itẹ́, wo bí àwọn ènìyàn ìlú Oyo ṣe ń kẹ́dùn Ọba Adeyemi

Alaafin Oyo

Nibayii, awọn adari ẹsin Islam ti bẹrẹ eto lati ṣe idagbere ikẹhin fun Alaafin Oyo to waja.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ bíbí ìlú Oyo ló tú kẹ̀tíkẹ̀tí síwájú Ààfin ìlú Oyo láti ṣèdárò, Ọba Lamidi Layiwola Atanda Adeyemi kẹta tó darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.

Alaafin Oyo

Nígbà tí BBC Yorùbá ṣe àbẹ̀wò sí ààfin ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, iwájú ààfin kún fún ọ̀bítíbitì àwọn ènìyàn tí wọ́n wá kẹ́dùn àti láti fìdí òtítọ́ múlẹ̀ lórí ìròyìn wí pé Aláàfin gbésẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ilẹ̀kùn ààfin wà ní títì pa ní kùtùkùtù òwúrọ̀ náà, a lè sọ wí pé gbogbo ìlú Oyo ló dáríjọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin láti ṣelédè lẹ́yìn Ọba wọn tó wàjà.

Àbẹ̀wò sínú ìlú náà ṣàfihàn pé gbogbo inú ìlú dá páropáro tí àwọn ọjà náà kò sì kún tààrà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń wáyé lọ́jọ́ lásán.

Aafin Oyo

Púpọ̀ nínú àwọn tó wà lọ́já gan ní àwọn ti dé ọjà kí àwọn tó gbọ́ wí pé Ọba wàjà ni bí bẹ́ẹ̀kọ́, àwọn kò bá má wà sí ọjà ní irú ọjọ́ òní.

Kíni agbẹnusọ Aláàfin sọ?

Bode Durojaye, Agbẹnusọ Aláàfin tó dolóògbé

Agbẹnusọ Aláàfin tó dolóògbé, Bode Durojaye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdàgbàsókè ló bá ìlú Oyo lẹ́yìn tí Ọba Lamidi Adeyemi kẹta gun orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Aláàfin.

Durojaye ní gbogbo ìlú Oyo ni yóò ṣàfẹ́kù Ọba Adeyemi nítorí ìhà tó kọ sí àwọn ènìyàn kò kéré rárá.

Ó ṣàlàyé wí pé Ọba tó kó àwọn ènìyàn mọ́ra ní Aláàfin ń ṣe èyí tó fàá tí gbogbo kò fi gbèrò ní òwúrọ̀ yìí.

Alaafin

Ó fi kun wí pé Ọba tó fẹ́ràn Aláàfin ṣe èyí ló sì ṣe okùnfà ìdí tó fi jẹ́ bàbá ìsàlẹ̀ fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì mẹ́rin nígbà ayé rẹ̀.

Bákan náà ló júwe Ọba Lamidi bí ẹni tó fẹ́ràn àṣà àti ìṣe Yorùbá àti wí pé àwòkọ́ṣe ló jẹ́ fún àwọn Ọba Yorùbá yòókù àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Kí ni àwọn ará ìlú ń sọ nípa Ọba wọn tó wajà?

Àwọn èrò tó péjú síwájú ààfin

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Nínú àwọn ọmọ ìlú Oyo tó bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ní ó ṣe àwọn láàánú wí pé Aláàfin wájá lásìkò yìí.

Lára ènìyàn tó bá ikọ̀ ìròyìn wa sọ̀rọ̀ ní púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ìlú Oyo tí ọjọ́ orí wọn kò ì pé ọgọ́ta ọdún ní ó ṣeésẹ kí wọ́n máa tíì bá Aláàfin kankan lo ìgbà rí yàtọ́ sí Ọba Adeyemi III.

Wọ́n ní èyí yóò ṣe àjòjì lára nítorí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ì tíì ṣe àwọn rí.

Alaafin Oyo

Nígbà tí BBC Yorùbá tún kàn sínú ọjà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́já ní ó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn àti wí pé àdánù ńlá ni ikú Aláàfin jẹ́ fún ìlú Oyo lápapọ̀.

Àkọlé fídíò, Oru tí olóríibú máa ń di olóríire ni "Laylatul Qadr", tóo bá bẹ Ọlọ́hun, orú agbára gidi ni - Akeugbagold