Chrisland Sex Scandal: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣí gbogbo ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ Chrisland padà

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti pàṣẹ wí pé gbogbo ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ Chrisland tí wọ́n gbé tì pa nítorí ẹ̀sùn ìwà aṣemáṣe tí wọ́n fi kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà kan di ṣíṣí padà.
Àṣẹ yìí jáde ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Kẹrin ọdún 2022 nínú àtẹ̀jáde kan tí Kọmíṣọ́nà ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko, Folasade Adefisayo fi léde.
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 2022 tí sáà ètò ẹ̀kọ́ mìíràn yóò bẹ̀rẹ̀ káàkiri ìpínlẹ̀ Eko ni ìjọba ní kí ilé ẹ̀kọ́ náà jẹ́ ṣíṣí.
- Ìjọba Eko ti iléẹ̀kọ́ Chrisland pa torí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ láàrín àwọn àkẹ́kọ̀ọ́
- Kìí ṣe ẹ̀bi wa wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣemáṣe - ile ẹ̀kọ́ Chrisland
- Fídíò Chrisland, ikú Sylvester Oromoni, àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọ gbì tó wáyé láwọn ilẹ ẹ̀kọ́ girama
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Wo ìjìyà tó wà fún pínpín fọ́rán ìbálòpọ̀ ọmọdé lórí ayélujára
Àtẹ̀jáde ọ̀hún ní ìdarí náà wáyé lẹ́yìn tí ìjọba ṣe àgbéyẹ̀wò ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀sùn aṣemáṣe náà.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn kò fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù pàdánù ẹ̀kọ́ wọn ní kété tí sáà tuntun náà bá bẹ̀rẹ̀.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ní ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹrin ọdún 2022 ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko pàṣẹ wí pé kí wọ́n ti gbogbo ilé ẹ̀kọ́ náà tì pa.
Ẹ̀sùn wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọmọdé ti ẹ̀ka Victoria Garden City ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe aṣemáṣe nígbà tí wọ́n ṣe ìrìnàjò lọ sí ìlú Dubai láti lọ kópa níbi ìdíje eré àwọn ilé ẹ̀kọ́ àgbáyé ló fàá tí ìjọba fi ti gbogbo ẹ̀ka ilé ẹ̀kọ́ náà.
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Fayose kìí bá wọn jẹ ìjẹkújẹ, bí Aisha Buhari bá fẹ́ fún èèyàn l'Oúnjẹ ko wá aláìní lọ
- Àlè kun abilékọ bíi ẹran ọ̀yà láti fi ṣe òògùn owó, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ
- Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn òṣèré fíìmù Yorùbá ti gbé àwọn olólùfẹ́ wọn ní ‘handicap'
- Bí mo ṣe máa rí N100m tí mo fẹ́ fi gba fọ́ọ̀mù APC rèé...
- Tí mo bá dí ààrẹ, gbogbo àwọn agbébọn yóò pòórá tí wọ́n bá gbọ́ orúkọ mi - Nyesom Wike
- $5.39 ni INEC yóò ná lórí olùdìbò kọ̀ọ̀kan lọ́dún 2023
- Wo àwọn ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa gbajúgbajà olórin ẹ̀mí, Tope Alabi
Ìjọba ní àwọn ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà pa kí ìwádìí tó lòòrìn le wáyé lórí ẹ̀sùn náà àti wí pé kí àwọn má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù.
Ní báyìí tí wọ́n ti ṣí ilé ẹ̀kọ́ náà padà, ilé iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn òbí àti olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà láti ṣe àtìlẹyìn àti ṣe àmójútó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn.
Bákan ni wọ́n ní àwọn yóò ṣe àgbéyẹ̀wò gbogbo ìlànà ilé ẹ̀kọ́ náà pàápàá èyí tó níṣe pẹ̀lú ṣíṣe ìrìnàjò nítorí àti dènà irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ní àwọn yóò tún ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo òfin àti ìlànà tó de àwọn ilé ẹ̀kọ́ aládáni àti ti ìjọba káàkiri ìpínlẹ̀ Eko láìpẹ́.


















