Chrisland school girl video: Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọ gbì tó mi àwọn ilẹ ẹ̀kọ́ girama tìtì ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Other
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori fidio awọn akẹkọọ Chrisland Schools to lu jade lojo opo Twitter lọjọ Aje nibi ti awọn akẹkọọ kan ti ni ibalopọ.
Iroyin ni ilu Dubai, ni United Arab Emirates ni wọn ti ṣe aṣemaṣe naa, ti wọn si tun ti ya fidion ọhun.
Ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ ni ipinlẹ Eko, ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọdọ ati ileeṣẹ eto idajọ ti darapọ mọ iwadii naa.
- Iṣẹ́ ilé kíkọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ Dejo Tunfulu lẹ́yìn tó jáde láyé
- kìí ṣe ẹ̀bi wa wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣemáṣe - ile ẹ̀kọ́ Chrisland
- Bí mo ṣe rí iṣẹ́ ní UK rèé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú - Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀
- Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹrín etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
- Ọlọ́run ló sọ fún mi kí n lọ dupò ààrẹ Naijiria ní 2023, ohun tó sọ fún mi rèé - Ìmàámù Afeez Akinola
- Ìjọba fìdíhẹẹ́ ló yẹ ká kéde lẹ́yìn sáà Buhari, Ìwé òfin Nàìjíríà kò kájúẹ̀ - Afe Babalola
- Kọjú sí iṣẹ́ ìwàásù táa fí rán ọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wà darapọ̀ mọ́ òṣèlú - Ilééṣé ààrẹ sí Father Kukah
Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii ni ijọba Eko kede pe awọn ti gbe awọn ẹka ile ẹkọ naa ti pa.
Ni bayii ti awọn ọmọ Naijiria ti n jẹ iṣẹlẹ ile ẹkọ Chrisland yii lẹnu, a ni ki a ṣe akojọpọ awọn iṣẹlẹ gbankọ gbi to waye lawọn ile ẹkọ ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii.
Iku Sylvester oromoni
Oromo ni ọmọ ile ẹkọ girama Dowen College to wa niluu Eko, iroyin iku ọmọ naa si mi Naijiria titi.
Oloogbe naa fẹsun kan awọn akẹgbẹ rẹ nile ẹkọ pe wọn fi iya jẹ oun lọna ti ko tọ, wọn si tun dunkoko mọ oun.
Ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ni Oromoni dagbere faye.
Ile ẹkọ Dowen sọ pe akẹkọọ ọhun ku lẹyin to farapa nibi to ti n gba bọọlu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ.
Amọ nnkan bii 180,000 eeyaq lo tọwọ bọwe pe awọn n fẹ idajọ ododo lori iku rẹ.
Iṣẹlẹ ile ẹkọ Deeper Life
Oṣu Kinni ọdun to kọja ni iya ọmọ ọdun mọkanla kan to wa ni ipele kinni nile ẹkọ Deeper Life to wa ni ipinlẹ Akwa Ibom ke gbajare pe awọn akẹgbẹ ọmọ oun fọwọ kan ọmọ naa lọna ti ko tọ nile ẹkọ.
Iṣẹlẹ naa mu inu bi ọpọ ọmọ Naijiria, wọn si fi erongba wọn lede lori ayelujara nitori wọn gbagbọ pe ọrọ naa ko ka ijọ Deeper Life lara to bi wọn ṣe fẹ.
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ni ki adari ile ẹkọ ọmọ ọhun lọ rọkun nile, ti wọn si gbe awọn ọmọ ti wọn fẹsun kan lọ sile ẹjọ to n gbọ ẹsun ọdaran awọn ọmọde.
Iroyin bi wọn ṣe fi ọbẹ rẹ ọrun akẹkọọ ni ile ẹkọ El Kanemi
Ilu Bornu ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iroyin ni akẹkọọ kan fi abẹrẹ razor rẹ ọrun ọmọ ọdun mejila kan to wa ni ipele kinni lẹyin ti ọmọ naa kọ lati jiṣẹ ro ran an.
Awọn eeyan kan lo ṣawari ọmọ ti wọn fi razor rẹ ọrun rẹ ninu agbara ẹjẹ.
Gẹgẹ bii ohun ti iya ọmọ naa sọ, ile ẹkọ naa san owo gba mabinu N2.5m fun akẹkọọ naa fun iṣẹ abẹ, ijọba ipinlẹ Borno si gbe ile ẹkọ naa ti pa.
Iku to waye ni ile ẹkọ ijọba apapọ ni Kwali
Ninu oṣu Kẹjọ ọdun to kọja ni akẹkọọ kan to jẹ ọmọ ọdun mẹtala, Nuhu Yahaya ku ni FGC Kwali, to wa niluu Abuja.
Iku ọhun mu ki ijọba gbe igbimọ oluwadii kalẹ.
Awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa gunle ifẹhonuhan lẹyin iṣẹlẹ ọhun.
Fidio ibalopọ fasiti Babcok

Oríṣun àwòrán, Babcock University
Lọdun 2019 ni fasiti Babcok fi ọwọ osi juwe ile fun akẹkọọbinrin kan ti oju rẹ han ninu fidio ibalopọ kan.
Agbẹnusọ fasiti ọhun, Joshua Suleiman ni inu ọgba ile ẹkọ naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye ninu oṣu Kẹrin ọdun kan naa.
O ni "A ti kọkọ le okunrin ti won jọ ni ibalopọ kuro nilẹ ẹkọ wa ninu oṣu kẹji lẹyin ti iwadi fi han pe o lọwọ ninu awọn wahala kan to waye ṣaaju."
Amọ ọpọ ọmọ Naijiria lo kọ ha lẹyin ti fidio naa jade lori ayelujara.















