Afe Babalola 2023 Elections: Wo ìdí tí àgbà amòfin fI ní ọ̀nà àbáyọ n kí Nàìjíríà ṣètò ìjọba fìdíhẹẹ́ àti ìwé òfin tuntun

Oríṣun àwòrán, @hartarmah1
Agbaọjẹ amofin Oloye Afe Babalola ti sọ pe ki wọn yan ijọba fidihẹ ni kete ti aarẹ Buhari ba pari saa rẹ lori oye ni dun 2023.
Babalola to fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n ba awọn akroyin sọrọ ni Ado Ekiti lọjọ Aje ni oṣu mẹfa ni ki wọn jẹ ki ijọba fidihẹ yi lo lori oye.
Ki wa lo de ti o fi mu iru aba yi wa?
Babalola ni eredi aba yi ni pe iwe ofin Naijiria to wa nilẹ bayi ko wa ni ibamu pẹlu igba taa wa yi.
Awọn ijọba ologun Naijiria lo ṣeto iwe ofin yi fun araalu lọdun 1999 ti awọn ijoba to tẹle si ti n wa ọna lati igba naa lati mu iyipada ba iwe ofin yi.
Ninu ero Babalola ''o yẹ ki wọn so iwe ofin 1999 rọ titi ti Naijiria yoo fi ni ''iwe ofin ti araalu'' eleyi ti yoo fi igbalaye fawọn atunṣe kọọkan.
Akọkọ ohun ti Babalola ni iwe ofin yi ni lati ṣayipada rẹ ni igbalaaye ki awọn aṣofin maa ṣe iṣẹ mi kun iṣẹ aṣofin wọn.
Eyi tunmọ si pe ki iṣẹ yi nikan ma jẹ nkan ti wọn gbaju mọ.Ni ṣoki, o fẹ ki o jẹ iṣẹ 'part-time' fun wọn bi aṣa awọn oloyinbo.
Bakan naa Afe Babalola sọ pe aar ti kii ṣe apaṣẹ waa lo y kiiwe ofin yi faaye silẹ fun.
Nibo ni ki wọn ti mu awọn ti yoo ṣe ijọba fidihẹ wa?
Lori aba yi, Babalola sọ pe ki wọn yan awọn aarẹ to ti jẹ kọja sẹyin to ba wa laye sinu ijọba fidihẹ yi.
Bẹẹ lo nikawọn igbakeji aarẹ,awọn minisita kọọkan ati awọn aṣoju ẹgbẹ to lorukọ ni Naijiria.
Ninu awọn ẹgbẹ to da laba pe ki wọn wa ninu ijọba yi ni ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun(NMA),ẹgbẹ awọn amofin,NBA, ti tawọn osiṣe NLC, akọroyin,NUJ,ti fasiti, ASUU ati awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan.
O ni wọn ko gbọdo yan aṣoju kankan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu kankan.
Babalola sọ pe o ṣeni laanu pe iwe ofin ọdun 1999 ti awọn ologun gbe le Naijiria lọwọ ko bojumu.
Bakan naa lo sọ pe iwe ofin yi ti sọ iṣ oṣelu di eleyi to mu wowo wa fawn eeyan ni Naijiria.
Kini iwe ofin tuntun yi yoo tunmọ si faraalu?
Ninu ọrọ rẹ Babalola to jẹ oludasilẹ fasiti Afẹ Babalola ni idibo kankna to ba waye labẹ ofin eleyi to wa nilẹ yi ko le so eso olori rere kankan.
O da laba pe wọn gbọdọ seto iwe ofin tuntun eleyi ti ijọba fidihẹ yoo ṣamojuto rẹ ti yoo si ṣalaye ofin to de iru amuyẹ awọn to ba f du ipo ninu eto idibo.
Lakotan, Afẹ Babalola ni nikni to ba fẹ jẹ ipo aarẹ ko gbọdọ kọja ọgọta ọdun ti iru ẹni naa si gbọdọ ni iwe ẹri fasiti.















