Osinachi Nwachukwu: Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ olóògbé sọ pé lóòótọ́ ni ọkọ rẹ̀ n fi ìyà jẹ ẹ́, ohun tó mọ̀ rèé

Odinaka Ukanwa, ọrẹ Osinachi Nwachukwu

O ti le ni ọsẹ kan ti gbajugbaja akọrin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu, jáde laye.

Sugbọn ọrọ ko tii tán lori iku rẹ.

Lati igba to ti ku ni awọn eeyan kọọkan ti n sọ ni gbangba pe lílù ti ọkọ rẹ, Peter Nwachukwu, má n lu u lo ṣe okunfa iku rẹ.

Lara àwọn eeyan naa ni àwọn ọmọ oloogbe, ẹbi rẹ, ati awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ orin bii Frank Edwards.

Àwọn aláṣẹ ko tii fidi eyi mulẹ ṣa.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe rí ọ̀pọ̀ Mílíọ̀nù Nàírà tí mo sì dáà padà fún Ọlọ́pàá lọ́dún 1971 àmọ́ ǹkan t'íjọba sọ rèé - Baba Shonubi

Ẹni tuntun to tun sọrọ nipa iku Osinachi, ni ọrẹ rẹ timọtimọ, Odinakachi Ukanwa.

'Ọkọ Osinachi sọ fún un pé kò sùn sílè aṣẹ́wó dípò ilé mi'

Osinachi Nwachukwu ati ọkọ rẹ Peter

Oríṣun àwòrán, Peter Nwachukwu/Facebook

Ukanwa sọ fun BBC Igbo pe o ni asiko kan ti Osinachi rinrinajo lọ si ilu Eko, o ni ni ṣe ni Peter sọ fun iyawo rẹ pe ko lọ sun sile aṣẹwo, dipo ile òun ọrẹ rẹ.

O ni oun ti mura silẹ lati gbalejo rẹ, ki ọkọ rẹ to pàṣẹ fun un pe ko ma sun sile oun.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

" Bo ṣe de papakọ ọkọ ofurufu, lo pe mi pe ọkọ oun ni ile ìtura ni ki oun sun. Koda, ibẹ lo wa to ti n reti ki ọkọ fi owo ti yoo fi gba yaara ránṣẹ́ si i".

"Nigba to de ile itura naa, ni awakọ takisi to gbé e lọ síbẹ̀ salaye fun pe ile aṣẹwo ni ibẹ, kii ṣe ile ìtura."

Arabinrin Odinaka Ukanwa ṣalaye pe lẹyin iṣẹlẹ naa ni Osinachi sọ fun oun nipa nkan to n la kọja ninu igbeyawo rẹ.

Ati bo ṣe jẹ́ pe ọkọ rẹ lo n mojuto gbogbo owo to ba pa nibi orin kíkọ.

Odinaka Ukanwa, ọrẹ Osinachi Nwachukwu

Odinaka sọ pe ọrẹ òun jẹ ẹnikan ti ko fọwọ si tabi gbagbọ ninu ikọsilẹ tọkọtaya. Idi ni pe o gbagbọ pupọ ninu Bibeli.

O ni sugbọn, kii fẹ sọ̀rọ̀ nipa nkan to n la kọjá, ki ọrọ naa ma baa di wahala laarin oun ati ọkọ rẹ.

Lọwọlọwọ, ọkọ Osinachi, Peter, wa ni ahamọ ọlọpaa n'ilu Abuja.

Eyi waye lẹyin ti aburo oloogbe fi ẹjọ sùn ni agọ ọlọpaa, pe Peter lo lu iyawo rẹ pa.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Minisita fun ọrọ awọn obinrin ni Naijiria tilẹ sọ pe àṣírí tú nigba ti oun bẹ awọn ọmọ oloogbe wo pe Arakunrin Peter ni iyawo miran ni ikọkọ.

Mama Osinachi, Arabinrin Madu, sọ fun BBC pe lẹyin ọdun mẹjọ ni oun to fi oju kan ọmọ oun nigba to ṣe igbeyawo pẹlu Peter.

Bakan naa ni ẹbi naa sọ pe Ọgbẹni Nwachukwu ko gba ki Osinachi wa ẹbi rẹ tabi ki awọn naa o wa.

Koda, wọn sọ pe awọn ti gbe e kuro nile arakunrin naa ri, nigba to n fi iya jẹ ẹ. Ṣugbọn, oloogbe pada sile ọkọ rẹ "nitori pe ko fẹ ki ẹnikẹni tu nkan ti Ọlọrun ti so pọ".

Pásítọ̀ Paul Enenche to jẹ oludasilẹa ti adari ijọ ti wọn n lọ naa sọ nnkan tó mọ̀ nípa ikú akọrin Ekwueme, Osinachi Nwachukwu.

Lẹyin ọsẹ kan ti gbajugbaja akọrin ẹmi, Osinachi Nwachukwu, jade laye, pasitọ Paul Enenche, ti sọrọ lori iku rẹ.

Pasitọ naa sọ pe oun ko mọ tabi gbọ pe ọkọ obinrin naa ma n lù ú, titi awọn eeyan fi n sọrọ nipa rẹ lẹyin iku rẹ.