Osinachi Nwachukwu: Àwọn ẹ̀rí tuntun farahàn nípa ikú akọrin Ekwueme

Arabinrin Osinachi

Oríṣun àwòrán, PETER NWACHUKWU FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn aṣiri miran tun ti tu lori iku gbajúgbajà akọrin ẹmi, Osinachi Nwachukwu.

Eyi jẹyọ ninu ọrọ ti minisita fun ọrọ awọn obinrin ni Naijiria, Pauline Tallen, sọ lasiko to kopa lori eto kan nileeṣẹ amohunmaworan NTA.

Arabinrin Tallen sọ pe ọrọ ti oun ba awọn ọmọ oloogbe sọ fihan pe ẹni ẹ̀rù ni baba wọn jẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Awọn ọmọ naa sọ fun mi pe ti baba awọn ba jade nikan ni inu awọn ma n dun ninu ile.

"Wọn sọ fun mi pe baba awọn lo ma n gba gbogbo owo ti iya wọn ba pa nibi orin kikọ, ti ko si ni apo asunwọn lorukọ rẹ."

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

Minisita Tallen tẹsiwaju pe ẹni to jẹ akojanu ile aṣofin, to jẹ ọmọ abule kan naa pẹlu oloogbe Osinachi naa ṣe abẹwo si ile oloogbe.

Nibẹ lo ni awọn ọmọ naa ti gbe iwe aworan kan jade, eyi to fihan pe Ọgbẹni Nwachukwu ni iyawo si ibi kan lẹyin Osinachi.

"Ọmọ naa sọ fun mi pe gbogbo igba ni inu iya awọn kii dun, nitori bi baba wọn ṣe ma n lu u ni gbogbo igba."

O ni oun gẹgẹ bi ẹnikan yoo ri daju pe idajọ ododo waye lori iku Arabinrin Osinachi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Amin iyasọtọ kan

Pásítọ̀ Paul Enenche sọ nnkan tó mọ̀ nípa ikú akọrin Ekwueme, Osinachi Nwachukwu

Lẹyin ọsẹ kan ti gbajugbaja akọrin ẹmi, Osinachi Nwachukwu, jade laye, pasitọ ijọ rẹ, Paul Enenche, ti sọrọ lori iku rẹ.

Ṣaaju iku rẹ, Arabinrin Osinachi jẹ adari akọrin ninu ijọ Dunamis International Gospel Centre, Abuja.

Ọpọ eeyan to jẹ ojugba obinrin naa, to fi mọ ẹbi rẹ lo n fi ẹsun kan ọkọ rẹ, Peter Nwachukwu, pe oun lo ṣokunfa iku rẹ nitori bo ṣe ma n lu u.

Lara awọn ẹsun ti ọpọ eeyan si tun n fi sita ni pe o yẹ ki pasitọ̀ ijọ wọn, Enenche, mọ pe iru nkan bẹẹ n waye ninu idile awọn ọmọ ijọ rẹ.

Pasitọ Paul Enenche ni oludasilẹ ijọ Dunamis, Abuja, ti oloogbe Osinachi ati ẹbi rẹ n lọ

Oríṣun àwòrán, PAUL ENENCHE

Àkọlé àwòrán, Pasitọ Paul Enenche ni oludasilẹ ijọ Dunamis, Abuja, ti oloogbe Osinachi ati ẹbi rẹ n lọ

Kini Pasitọ Paul Enenche sọ nipa iku oloogbe Osinachi Nwachukwu:

Ninu fídíò kan to fi sita lori ayélujára rẹ, lọjọru, Pasitọ Enenche sọ pe oun ko mọ pe oloogbe n koju iwa ipa ninu igbeyawo rẹ.

O ni lootọ ni Osinachi ati ọkọ rẹ wa si ọdọ oun ni bi i oṣu meji aabọ sẹyin, ti wọn si sọ fun oun pe arabinrin naa ni irora ni àyà rẹ, ti ko si le mí daadaa.

"Mo gbadura fun. Nigba ti nkan to n ṣe ko lọ, mo gba wọn ni imọran pe ki wọn o lọ ọ ri dokita kan ti mo juwe fun wọn."

"Ayẹwo akọkọ ko fi ohunkohun han, ṣugbọn ni ileewosan ijọba ni Gwagwalada ni wọn ti sọ pe wn yoo sẹ ayẹwo ẹdọforo rẹ."

Pasitọ Enenche ṣalaye pe lẹyin asiko diẹ, ara rẹ bẹrẹ si ni yá.

"Inu gbogbo wa dun. Koda, ojoojumọ lo ma n pe mi lati jẹ ki n mọ ipo ilera rẹ. Eyi lo mu ko ya mi lẹnu nigba ti mo gbọ iroyin iku rẹ."

Pasitọ naa sọ pe oun ko mọ tabi gbọ pe ọkọ obinrin naa ma n lù ú, titi awọn eeyan fi n sọrọ nipa rẹ lẹyin iku rẹ.

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, OSINACHI NWACHUKWU

O ni ibeji Osinachi, olootu orin rẹ, ati awọn ọmọ arabinrin naa fidi rẹ mulẹ fun oun pe iru nkan bẹẹ n waye.

"Olootu orin sọ fun mi pe ọkọ rẹ (Osinachi) ti gba eti rẹ ri loju oun ninu ibudo orin. O ni ṣugbọn, Osinachi funra rẹ lo bẹ oun pe ki oun ma sọ fun ẹnikẹni, tabi koju ọkọ oun."

Pasitọ Enenche sọ pe gbogbo ọmọ ijọ Dunamis lo mọ pe oun ko faaye gba iwa ipa ninu igbeyawo rara.

"Nitori o san ki eeyan o wa laye ju ko ku nitori igbeyawo lọ

"Amọ o nira lati mu ayipada ba ẹni ti ko ba fẹ yipada."

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ni Arabinrin Osinachukwu jade laye lẹni ọdun méjìlélógójì, nilu Abuja.

O gbajumọ fun orin rẹ 'Ekwueme'.