2023 General Elections: Èmi ni mo kájúẹ láti di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà – Tinubu

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Adarí àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Bola Tinubu ti ní òun ni ẹni tó tọ́ láti jẹ Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní kété tí Ààrẹ Muhammadu Buhari bá ti gbésẹ̀.
Tinubu ní òun ní gbogbo ìgboyà àti àmúyẹ tí Ààrẹ tó le mí àyípadà ọ̀tun àti ìdàgbàsókè tó lòòrìn bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Níbi ìpàdé àti ìjíròrò ọlọ́jọ́ kan èyí tí Tinibu ṣe pẹ̀lú àwọn Abẹnugan àti àwọn ìgbákejì Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Eko ló ti ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí.
- ''Àti ọmọ ọdún mẹ́fà ni mo tí ń fa Cocaine, bí mo ṣe fipá bá Tosin lòpọ̀ rè é, tí mo sì pa á''
- Ìwúlò Buhari fún Nàíjíríà tí tán, kò búrú tó bá kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn
- Ẹ̀yà Yorùbá kò mọ̀ sí ìwọ́de onímílíọ̀nù kan èèyàn tí IPoB ń gbèrò - Ilana Omo Oodua
- Mo fẹ́ pokùnso torí ìjákulẹ̀ tí ọ̀gá mi, Yekini Ajileye fún mi, ọpẹ́ tọ́ọ́gì kan... - Abija
- Ó ti tán fún Nàìjíríà bí ará Àríwá bá tún di Ààrẹ lọ́dún 2023 - Adebanjo
- Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi
Ó sọ wí pé ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wà lọ́wọ́ bí àwọn adarí bá ṣe lè ronú àti bí wọ́n bá le ṣe jí gìrì sí ojúṣe wọ́n sí.
"Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò mi gẹ́gẹ́ bí èmi náà ṣe nílò Nàìjíríà nítorí mo jẹ́ ẹni tó le ronú tó sì ní ìgboyà láti mú àyípadà ọ̀tun bá a."
"Ẹni tó ní ìgboyà ní Ọlọ́run dá mi tó sì ń ṣe iṣẹ́ fún mi, mo sì fẹ́ lò ó fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà."
- Ẹ dákun, ẹ gbà mí, Auxillary ń lépa ẹ̀mí mi - Olopoeyan kọ̀wé sí ọlọ́pàá, DSS
- Ó seése kí Boris Jhonson àti Rishi Sunak sanwó ìtanràn nítorí wọ́n tàpá sófin kónílé-ó-gbélé
- Kà síi nípa ìkìlọ̀ pàtàkì lórí ayédèrú mílíkì tó gba ìgboro kan- NAFDAC
- Ìjọba Nàìjíríà kéde ìsinmì lẹ́nu isẹ́ nítorí ọdún àjínde
- "Àwọn ọmọ ogun Russia fipá bá mi lòpọ̀, wọ́n tún pa ọkọ mi"
- Àkàrà tú sépo fún ayédèrú ọ̀gágun tó fi Khaki lú jìbìtì N266.5m












