2022 Easter Holiday: Ìjọba àpapọ̀ kéde ìsinmì lẹ́nu isẹ́ nítorí ọdún àjínde Jesu

Ajinde 2022

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ajinde 2022

Ijoba Naijiria kede isinmi lẹ́nu ise lati ọjọ Eti ati ọjọ́ Aje

Eyi ni isinmi ki awon Onigbagbo le fi saami ayeye odun ajinde Jesu Kristi to je olugbala araye.

Ojo keedogun ati ojọ́ Aje ọjọ́ kejidinlogun, osu kerin, ọsun 2022 yii ni won yoo fi sami ayajao ọjọ́ Eti rere ati ọjọ́ igbasoke Jesu to goke re ọ̀run ni ojọ́ Aje.

Minista fun ọ̀rọ̀ abẹ́le, Ogbeni Rauf Aregbesola lo fi ikede yii sita loni ọ́jọ́ Isegun.

Kini Atejade naa tun so?

Ogbeni Shuaib Belgore t je akowe agba fun ileese ijoba apapo lori ọ̀rọ̀ abẹ́le lo buwọ́lu atejade naa loruko Minista Aregbesola.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Nibe naa lo ti ki awon omoleyin Kristi kaakiri orile-ede Naijiria ku odun Ajinde.

Shuaib Belgore tun fi idaniloju han pe ijoba Naijiria ko ni sinmi lati gbogun ti awon onise ibi to n sosẹ́ lopopona kaakiri Naijiria.

O ni pe ọ̀rọ̀ eto aabo ti di ankoo fawẹ́ẹ́li fun gbogbo ọmọ Naijiria bayii ati awọ́n ajoji ti o wa lati ilẹ̀ okeere sugbọ́n ti wọ́n n gbe ni Naijiria naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

Kini Pataki ọdun Ajinde?

Pataki ọdun Ajinde ni lati sami ijiya ti Jesu Kristi jẹ́ lori igi agbelebu.

Awon onigbagbo tun gbagbọ́ pe o wa lati fi se iranti iku Jesu Kristi lati fun awọ́n elẹ́sẹ̀ ni ominira lati bọ́ lọ́wa igbekun aisi igbala.

O tun wa fun lati sami ayọ́ ati ireti ajinde lẹ́yin oku ti awọ́n Onigbagbọ́ gbagbọ́ ninu re.

Eyi waye leyin ti Jesu Kristi jinde lọ́jọ́ kẹ́ta kuro ninu isa oku ni eyi to je ireti nla pe o ti gba kọ́kọ́ra lọ́wọ́ iku atinisa oku fun enikeni to ba gbagbo ninu re