MC Oluomo-TOOAN Crisis: Ọ̀pọ̀ èèyàn farapa, márúwá jóná bí afurasí jàǹdùkú ṣe gba gárééjì lọ́wọ́ àwọn onímárúwá

Oríṣun àwòrán, RRS
Ija nla bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ onikẹkẹ Maruwa nipinlẹ Eko (TOOAN) ati awọn eeyan kan to n se atilẹyin fun alaga tẹlẹ fẹgbẹ awakọ ero NURTW nipinlẹ Eko, MC Oluomo.
Ohun to si sokunfa ija naa ni ariyanjiyan lori akoso garage ati igun to tọ lati maa ta tikẹẹti lawọn gareeji to wa labẹ akoso TOOAN.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni apapọ ẹgbẹ NURTW ni Abuja kede pe awọn ti yọ MC Oluomo bii alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ tètè jápa tí ìgbéyàwó yín bá ti la ìgbájú-ìgbámú lọ - Olori Silekunola
- Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati dupò ààrẹ
- Àwọn ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkọ olórin ẹ̀mí “Ekwueme” fẹ́sùn lílu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Oko kìí jẹ́ ti baba tọmọ kó mà ní ààlà; Mi ò ní ọmọ tó dàgbà tó le jáde láti dupò Ààrẹ- Tinubu
- Àwọn agbébọn ṣekúpa alága APC ní ìpínlẹ̀ Osun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé Osinbajo dalẹ̀ Tinubu pẹ̀lú bó ṣe kéde láti du ipò ààrẹ?
- Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dáná sun-ún
- "Ẹ̀yin onítíátà, ẹ gbàdúrà fún Kemi Afolabi, Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò já sí"
Lọgan naa si ni ijọba ipinlẹ Eko kede pe oun ti fofin de ẹgbẹ awakọ ero NURTW nipinlẹ naa, ti oun si se agbekalẹ igbimọ ti yoo maa se akoso awọn ibukokọ gbogbo labẹ akoso MC Oluomo.
Ki lo sokunfa akọtun aawọ naa?
Iroyin naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ TOOAN to jẹ onikẹkẹ Maruwa lo n sisẹ lọ lawọn ẹka gareeji wọn ni aarọ Ọjọ Aje, nigba ti awọn alatilẹyin MC Oluomo de ibudokọ wọn lati le wọn kuro.
Idi ree ti igun mejeeji se fi ija pẹẹta, ti ọrọ si di ẹni ori yọ, o dile.
Lasiko to n ba iwe iroyin Punch sọrọ, alaga fun ẹgbẹ TOOAN ni gareeji Agege, Opeyemi Taiwo ni deede aago meje abọ aarọ ni ija naa bẹrẹ.
O fikun pe se ni awọn ọmọ ọgbẹ oun fi ara pa yannayanna.
"Awa naa ti mọ pe awọn ọmọ MC Oluomo n bọ lati wa kọlu awọn gareeji wa, ta si ti fi ẹjọ wọn sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Pen Cinema ati Iju.
Ọkọ ni awọn n se akoso rẹ nigba ti awa wa labẹ ẹgbẹ TOOAN, kẹkẹ maruwa si ni awa n se akoso rẹ.
A ro pe wọn yoo ransẹ pe alaga wa fun ifikunlukun ni amọ wọn ko se bẹẹ, wọn kan de plu awọn afurasi janduku to le ni ọgọrun.
Gbogbo wọn si lo ko ibọn, ada, igo lọwọ, ti wọn si n se wa lese, bi o tilẹ jẹ pe a tiraka lati sa fun wn amọ sibẹ ọwọ wọn tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ wa kan.
Wọn se awọn eeyan naa lese, ti wọn si ti fara gbọgbẹ pupọ, ta si ti gbe wọn lọ sile iwosan fun itọju."
Bakan naa ni Taiwo ni awọn afurasi janduku ọhun tun jo awọn kẹkẹ maruwa wọn ni ina, ti wọn si sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ awọn pe awọn ti gba akoso gareeji naa lọwọ TOOAN.
Igbesẹ wo ni awọn ọlọpaa pajawiri ni Eko RRS gbe nipa isẹlẹ naa:
Igun awọn ọlọpaa to n dahun si ipe pajawiri, Rapid Response Squad (RRS) nipinlẹ Eko, eyi to wa labẹ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fesi lori isẹlẹ naa.
Awọn ọlọpaa RRS naa, nigba ti wọn n fidi isẹlẹ yii mulẹ loju opo Facebook wọn ni awọn ti mu alaafia jọba lawọn agbegbe ti laasigbo naa ti n waye nipinlẹ Eko.
Lara awọn agbegbe ti wọn darukọ ni Iju ati Fagba ti wọn lo wa labẹ ẹkun ileesẹ ọlọpaa G.
RRS ni se ni awọn afurasi janduku to pọ yanturu ya bo agbegbe naa lati da wahala silẹ, ti wọn si di lilọ bibọ ọkọ ati ero lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Rapid Response/Facebook
Bakan naa ni wọn fikun pe se ni ohun gbogbo dẹnu kọlẹ lawọn agbegbe ti rogbodiyan naa tan de, ti kata kara awọn olokoowo si dẹnu kọlẹ pẹlu.
Amọ Awọn ọlọpaa RRS ni awọn ti tu awọn afurasi janduku naa ka nibi ti wọn ti n dana irọ, ti alaafia si ti jọba pada sawọn agbegbe naa.



















