Dejo Tunfulu: Alfa Buhari ọmọ Musa ní káwọn onítíátà máa fura torí ikú tó ń ojúgbà ẹni òwe ló ń pa fún ni

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Kò sí ẹni tí kò ní kú, kò sì ẹni tí ìta baba rẹ̀ kò ní hu koríko.
Gbajúgbajà oní wáàsí ẹ̀sìn Islam, Alfa Buhari ọmọ Musa ti rọ gbogbo àwọn ènìyàn pàápàá àwọn oníṣẹ́ tíátà láti máa rántí ikú nínú gbogbo ìṣe wọn.
Alfa Musa sọ èyí níbi àdúrà ọjọ́ mẹ́jọ fún olóògbé Kunle Adetokunbo, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Dejo Tunfulu.
- Wèrè ọlọ́mọ ní Dejo Tunfulu, ọmọ mẹ́rin ní ìyá wa dà sílẹ̀ fún, tó sì bá ọkọ míì lọ - Ọmọ olóògbé
- Ikú Dejo Tunfulu ti kó ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn bá mi, ń kò le kópa nínú eré tà ń yà mọ́ - Ọ̀gá Bello
- A máa ń lọ yọjú wo Yinka Quadri tó bá ń ṣe fíìmù ládùúgbò wa - Ẹ wo bí Dejo Tunfulu ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Tíátà
- Àlàyé rèé lórí aìsàn tó pa Dejo Tunfulu àti ilé ìwòsàn tó dákẹ́ sí
Ní ilé Dejo Tunfulu ní ìpínlẹ̀ Eko ní àdúrà Fidau náà ti wáyé láti fi ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún olóògbé náà.
Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹrin, ọdún 2022 ni Dejo Tunfulu jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́ díẹ̀.
Kìí ṣe àwọn òṣèré tíátà nìkan ni ikú ń pa:
Alfa Buhari ọmọ Musa ní kí àwọn onítíátà rí ikú tó ń pa àwọn akẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àdánwò nítorí kìí ṣe agbolé tíátà nìkan ni ikú ti ń ṣọṣẹ́ ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn onítíátà lókìkí ni ariwo ikú wọn ṣe máa ń pọ̀.
Alfa Buhari rọ àwọn onítíátà láti máa fi ikú tó ń pa àwọn ojúgbà ṣe ọgbọ́n nítorí ikú tó ń pa ojúgbà ẹni òwe ló ń pa fún ni.
Bákan náà ló ní nǹkan kan ni yóò pa èèyàn láyé nítorí gbogbo ẹ̀dá ni yóò tọ ikú wò, gbogbo ohun tó ń ṣe ẹ̀mí ni yóò di ìtàn ní ọjọ́ kan.
Àti wí pé kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tí òun yóò lọ nítorí òjijì ni ikú máa ń dé bá ni àti wí pé ta ló mọ ẹni tí ikú kàn lágbo eré tíátà.
Ó wá pàrọwà sí gbogbo ènìyàn láti máa ṣe iṣẹ́ rere ní gbogbo ìgbà nítorí kí ikú le ká iṣẹ́ rere mọ́ wọn lọ́wọ́ lásìkò tí ọlọ́jọ́ bá dé àti pé kí àwọn ènìyàn le máa ròyìn wọn pẹ̀lú ìwà dada lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ tán.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Oluwo ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó gbé ìyàwó tuntun
- Ṣé lóòtọ́ ni Yemi Osinbajo fẹ́ kojú Tinubu fún ipò ààrẹ Nàìjíríà?
- Bí Sunday Igboho bá sọ èròǹgbà rẹ̀ nípa Yoruba Nation, inú gbogbo ọmọ Yorùbá yóò dùn - Banji Akintoye
- Ìtara láti du ẹ̀mí mi gbópọn si torí ìfẹ́ tẹ fi hàn mí - Kemi Afolabi
- Mo gbìyànjú láti ṣẹ́yún àkọ́bí mi saájú ìgbeyàwó - Iyabo Ojo
- Àgùnbánirọ̀ ya fọ́tò Bàbá Onílù láti tà á, òjò owó rọ̀ fún bàbá
- Tí mo bá di ààrẹ, ìwúrí ni màá jẹ́ fọ́mọ Nàíjíríà - Tunde Bakare
- Mò ń bọ̀ nílé láìpẹ́, ìjọba yóò sanwó tó jẹ mí - Sunday Igboho
- Awuyewuye ń lọ lóri pé ìgbéyàwó òṣèrébìnrín Yewande Adekoya forí sánpọ́n
Ẹ máa rántí àwọn ọmọ Dejo Tunfulu:
Alfa Buhari rọ àwọn òṣèré tíátà láti ṣẹ̀yìn Dejo Tunfulu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣojú.
Ó pàrọwà sí wọn láti máa tọ́jú àwọn ọmọ tí olóògbé náà fi sáyé nítorí ẹni tó ṣojú kò dàbí ẹni tó ṣẹ̀yìn.
Bẹ́ẹ̀ náà ló tún rọ wọ́n láti ṣe àwọn ohun mánigbàgbé fún àwọn ọmọ náà.
Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ náà láti ṣe ara wọn lọ́kan, tó sì rọ àkọ́bí Dejo láti kó àwọn àbúrò rẹ̀ mọ́ra nítorí ẹ̀jẹ̀ kan ni gbogbo wọn.
Ó gbà wọ́n lámọ̀ràn láti tẹ apá mọ́ṣẹ́ nítorí kò sí ẹni tó le ṣe ìṣe bàbá fún wọn mọ́ àti wí pé gbogbo ènìyàn náà ló ní bùkátà láti gbọ́.
Àwòkọ́ṣe ni àwọn onítíátà jẹ́ fún àwọn ènìyàn
Alfa Buhari ọmọ Musa tún tẹ̀síwájú láti sọ wí pé àwòkẹ́ṣe ní àwọn onítíátà jẹ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ọ̀pọ̀ ló máa ń wo àwọn sinimá wọn láti fi mú ọgbọ́n kan tàbí òmíràn kọ́.
Ó fi kun pé iyọ̀ ayé ni wọ́n jẹ́ àti pé Àlùfáà ni wọ́n pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti tò nítorí fíìmù tí wọ́n wò.
Bákan náà ló wá kọminú wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ṣe wàhálà nídìí iṣẹ́ tíátà ni kò dúró jẹ pàápàá àwọn olùdarí eré, olóòtù àti àwọn òṣèré tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ eré tíátà ní ìpìlẹ̀.
Alfa Buhari ṣèrántí wí pé àwọn ènìyàn kìí tẹ̀lé àwọn onítíátà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ṣùgbọ́n ó wú Ọlọ́run ló ṣe fi wọn hàn lásìkò yìí àti pé àlùbáríkà tí wọ iṣẹ́ náà ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Oríṣun àwòrán, KEMIAFOLABIADESIPE INSTAGRAM
Alfa buhari ṣàdúrà fún Kemi Afolabi
Níbi wáàsí náà ni Alfa Buhari ti tún ṣe àdúrà fún Kemi Afolabi, ẹni tí àìsàn lupus ń yọ lẹ́nu.
Alfa Buhari ka àwọn ẹsẹ̀ Àlùkùránì láti fi tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún Kemi Afolabi láti gbà á lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣe.
Ó ní Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò jásí àmọ́ kí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ máa fi àdúrà ráńṣẹ́ si.





















