Iyabo Ojo: Mo fẹ́ wọ fásitì láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin lásìkò tí mo lóyún, ọmọ ọdún 5 ni ọkùnrin ti ń ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú mi,

Iyabọ Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo ojo / instagram

Gbajumọ oṣere tiata, Iyabọ Ojo ti sọrọ jade pe ṣaaju ki oun to ṣe igbeyawo, ni oun ti loyun ọmọ ọkunrin oun, inu oun ko si dun si bi oyun naa ṣe waye nigba naa.

Iyabo Ojo ni inu oun bajẹ to bẹẹ ti oun fi gbiyanju lati ṣẹ oyun naa nigba naa.

Iyabọ Ojo to sọrọ lori eto ifọrọwerọ pẹlawọn ilumọọka obinrin ti wọn da pe ni 'The Real Housewives of Lagos' ṣalaye pe, lootọ ẹni ọdun mọkanlelogun ni oun ti lọ sile ọkọ.

Amọṣa, o ni oun ti kọkọ loyun ṣaaju igbeyawo naa, eleyi ti ko si dun mọ oun ninu nigba naa.

Iyabọ Ojo ni ọmọ ọkunrin loun pada wa fi oyun naa bi.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

Amọṣa o fi kun un pe lara ohun to mu ki oun gbimọran ati ṣẹ oyun naa nigbanaa, ni bi oun ṣe ṣẹṣẹ gba iwe igbaniwọle si fasiti ilu Eko nigba naa lati kẹkọ nipa ofin.

O ni oyun nini kọ lohun to kan fun oun nigba naa, idi si ree ti oun se gbiyanju lati sẹ oyun naa.

Ki lohun toju gbajumọ oṣere naa ri lati igba ewe wa?

Iyabọ Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo ojo/ instagram

Bakan naa ni gbajumọ oṣerebinrin yii tun mẹnu le ọrọ nipa ohun toju rẹ ri nigba ewe rẹ, paapaa julọ bi awọn ọkunrin ṣe ṣe aṣemaṣe pẹlu rẹ.

Iyabọ Ojo sọ eyi kun ara ohun to mu ki oun duro gbagbagba lẹyin akẹgbẹ oun Princess, nigba ti iṣẹlẹ kan waye nibi ti wn ti fi ẹsun kan gbajumọ oṣere miran, Baba Ijesha pe o ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọ rẹ.

"Ohun toju emi naa ti ri ri ni iṣẹlẹ ọmọ Princess. Ọpọlọpọ igba lawọn eeyan ti ṣe aṣemaṣe pẹlu mi nigba ewe.

Lati nnkan bii ọmọ ọdun marun un si mẹfa ni mọlẹbi mi kan ti fi aṣemaṣe lọ mi, ki n to gbe ina ọrọ ọhun ko o loju nigba ti mo wọ ọgbọn ọdun."