Iyabo Ojo: Ìséde alẹ́ di àárọ̀ tí Sanwo-Olu ṣe kó bá ilé ìgbafẹ́ mi, gbèsè dé

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Iyabo Ojo ti ke gbajare si ijọba ipinlẹ Eko lori igbele alẹ si aarọ to wa ni ipinlẹ naa.
Igbele naa, tijọba gbe kalẹ lasiko igbele arun Coronavirus lati aago mejila oru si mẹrin aarọ, ni wn ko tii so rọ titi di akoko yii ni Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Seyi Makinde ló ṣàtìlẹyìn ètò ààbò fún ìwọ́de Oduduwa Nation"
- Àwọn olùpolongo Oduduwa Nation àti ọlọ́pàá kojú ara wọn ní Sagamu
- Ọlọ́pàá, fijilanté àti ọdẹ ìbílẹ̀ dóòlà obìnrin mẹ́ta lọ́wọ́ ajínjigbé l‘Oyo
- Èmi kọ́ ni mò n pín ìrẹsì lókè Ọya lásìkò àwẹ̀ yìí - Bola Tinubu
- Ìgbeyàwó mú kí àpọ́nlé tó pọ̀ wà fún mi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ - Tayo Sobola
- Akẹ́kọ̀ọ́ girama tó jẹ́ afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn mẹ́rin bọ́ sọ́wọ́ ọ̀lọ́pàá l‘Eko
- Olùwọ́de Oduduwa kò yọjú sí gbọ̀ngàn Mapo,báwọn ọlọ́pàá ṣe gbàródan
- Àwọn olùpolongo Oduduwa Nation àti ọlọ́pàá kojú ara wọn ní Sagamu
Iyabo Ojo ni ofin konile o gbele ni oru naa n pa oun lara, o ni gbese ti fẹ pa oun nitori igbele naa ti ṣe ipalara fun owo to yẹ ko wọle nile igbafẹ ti oun da silẹ.

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris
Oṣere naa lo fi ọrọ ọhun lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti bẹ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ati igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo, pe ki wọn ka igbele naa kuro nilẹ.
O ni "ibeere ti mo fẹ beere lọwọ ijọba ni pe, ki ni eredi gan ti ijọba ṣe paṣẹ igbele lati aago mejila oru si mẹrin idaji."
Bo tilẹ jẹ pe o sọ pe oun mọ pe igbele naa wa lode nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra, ṣugbọn oun ko ri idi ti igbele yoo ṣe wa lode laarin oru ti ko si si lọsan gangan.
Iyabo Ojo sọ pe "igbele yii ti n pa owo mi atawọn ẹlomiran to n ṣowo ile ijo ati ile igbafẹ lara."
"Ṣe ọganjọ oru nikan ni arun Coronavirus maa n rin laarin ilu ni? Ṣebi awọn n lọ sinu ọja lọsan gangan."
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
- Èmí kò leè bá obìnrin kankan jà lórí ọkùnrin, kò leè ye yín - Iyabo Ojo
- Ẹ má jẹ́ kí ayélujára tàn yín jẹ́, mẹ̀kúnnù lọ̀pọ̀ àwa òṣèré tíátà - Iyabo Ojo
- Wo fọ́tò àrà MC Oluomo, Pasuma àtàwọn òṣèré tíátà míì níbi ìṣílé Iyabo Ojo
- Ẹ gbà mí, Nàíjíríà gbá mi lórí àyẹ̀wò Covid-19 - Iyabo Ojo figbe ta
- Iyabo Ojo gé okùn àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú olóṣèlú nínú ẹgbẹ́ APC ati PDP
"Ẹyin ijọba, ẹ ni lati ṣalaye fun awa ara ilu idi ti ẹ ṣe fi igbele si aarin oru ti awọn kan maa ṣe owo ti wọn fi n bọ awọn mọlẹbi wọn."
O ṣalaye pe awọn eeyan bi oun to ni ile igbafẹ ti ọpọ eeyan maa n ba dowo pọ loru, ni ofin konile-o-gbele naa pa lara julọ.
Gbajumọ oṣere naa ni, "ko bojumu ki a da owo wa duro fun odidi ọdun kan gbako nitori Corona, nigba ti kii ṣe pe o ni owo kan pato ti ijọba n fun wa."
"Gbogbo igba ti mo ba n lọ sile loru ni awọn ọlọpaa maa n da mi lọna pe igbele wa, ti wọn si maa n gba owo abẹtẹlẹ lọwọ mi."
"Mo fẹ ki ijọba mọ pe mo ni awọn ọmọ, bẹẹ si ni mo ni awọn ẹbi ti mọ n bọ, ijọba ẹ ṣaanu wa o."
"Mo n sọrọ lorukọ gbogbo awa ti a ni ile ijo ati igbafẹ ti igbele yii pa lara julọ nitori ijọba ko fun wa lowo kankan.
Wọn sọ wa si igbele, bẹẹ si ni wọn tun maa n reti ki a maa san owo ori."
Iyabo Ojo pari ọrọ rẹ pe, awọn ọlọpaa n fi akoko igbele naa mọọmọ gba owo ti ko tọ lọwọ awọn eeyan ilu loru ọganjọ ni.
Lẹyin naa lo ke si ijọba lati ṣalaye pẹlu ẹri pe oru nikan ni arun Corona maa n rin tabi ki wọn ka igbele naa kuro nilẹ.




















