Secret Cult: Ọjọ́ orí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà láàrin ọdún 14 sí 18

Police

Oríṣun àwòrán, @GreaterLagosNG

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu awọn ọdọ mẹrin kan, ti wọn fẹsun kan pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Wọn ni awọn afurasi naa tẹkọ leti lọ si ipinlẹ Eko lati Ogun lati ṣakọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun miran, to wa lawọn ile iwe girama kan lagbegbe Akinyele ati Alakukọ.

Gẹgẹ bii atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejobi fi lede, o ni awọn afurasi ọhun jẹ ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹrinla si mejidinlogun lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adejobi sọ pe meji lara awọn ọdọkunrin naa jẹ akẹkọọ ile ẹkọ girama Odewale Community High School to wa ni Ijoko, nipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Nigba ti awọn meji to ku jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Tunik Internation School, to wa ni Dalemo Alakuko.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe ni kete ti awọn agbofinro gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n mura lati kọlu awọn orogun wọn nile iwe miran ni wọn tọpaṣe wọn lọ.

Lara awọn ohun ija ti wọn ri lọwọ awọn afurasi naa ni ada, egboogi oloro, ati oriṣiriṣi oogun abẹnu gọngọ.

Àkọlé fídíò, Slain Ekiti Police woman: Ìyá rẹ̀ ní àìrìṣẹ́ṣe ló mú kí Bukola Olawoye gba iṣẹ́ ọlọ́pàá

Ẹwẹ, kọmiṣona ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti pasẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ si agọ wọn to wa ni Ikeja.

Lẹyin naa lo ni ki wọn bẹrẹ iwadii ni kikun ati ọna lati fi ṣikun ofin mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to jẹ orogun wọn, ti wọn n gbiyanju lati ṣakọlu si.