Peter Fatomilola: Mo ṣe àìgbọràn sí ìyá mi púpọ̀ nítorí ẹran ìrúbọ ati ẹ̀bùn ọ̀fẹ́

Peter Fatomilola

Oríṣun àwòrán, others

Agba oṣere, Peter Fatomilola ti ṣalaye pe ọmọ to ni agidi ni oun nigba ti oun jẹ ọmọde, paapaa lori ọrọ ileewe ati ile ijọsin lilọ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch, ni Alagba Fatomilola ti ṣalaye pe oun nikan ni ọmọ ti iya oun bi lẹyin ọpọlọpọ ọdun to fi wa lai lọmọ.

Amọ, ọlọmọ pupọ ni baba rẹ, nitori pe iyawo mẹsan-an lo ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ṣalaye pe nigba ti oun wa nibi ọmọ ọdun mẹrin, ti oye nkan to n ṣẹlẹ ti n ye oun. Oun ṣakiyesi pe awọn iyawo baba oun to ku ma n lọ si ṣọọṣi. Iya oun naa si ma n darapọ mọ wọn.

"Ṣugbọn, ni gbogbo igba to ba ti fẹ lọ fun isin ni ṣọọṣi, lo ma n pe mi ki n mura lati tẹle, amọ mo ma n kọ."

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola ní àìsí ẹ̀kọ́ ń mú káwọn òṣèré tíátà ó máá ṣe oun tí kò tọ́.

Kilo fa aigbọran ti Fatomilola maa n ṣe si iya rẹ?

Alagba Fatomilola ni awọn anfaani ti oun ma n jẹ lara awọn to ba wa si ọdọ baba oun fun isin Ifa lọsọọsẹ, lo jẹ afojusun oun nigba naa.

O ni "ti awọn yoku ba ti lọ si ṣọọṣi, awọn eeyan ma n wa si ọdọ baba mi lati d'ifa, wọn si ma n gbe oriṣiriṣi nkan bi adiyẹ, ewurẹ, iṣu sisun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

"Ipa pataki ni mo ma n ko lasiko ti a ba n peelo ẹbọ pẹlu awọn nkan ti awọn eeyan ko wa.

Emi ati awọn ẹgbọn mi ọkunrin ma n jẹ lara ẹran naa, mo si gbadun rẹ ju ki n ma lọ si ṣọọṣi nibi ti ko ti si nkan jijẹ."

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, nkan naa gbadun mọ oun debi pe oun bẹrẹ si ni sa nileewe nitori ẹbun toun n ri gba lọwọ awọn to wa difa lọwọ baba oun.

Amọ ṣa, Fatomilola tun eero rẹ pa lẹyin ọdun diẹ to gbọn si i. O ni aanu iya rẹ ṣe oun , oun si ronu pe ti wọn ba ni ki awọn eeyan o mu ọmọ wọn jade ni ṣọọṣi, iya oun ko ni i ri ọmọ kankan, nitori pe oun kọ lati tẹle lọ.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Isi si niyi to fi di ẹni to n lọ si ṣọọṣi.

Yatọ si pe Fatomilola bẹrẹ si ni lọ si ṣọọṣi, o di akinkanju ninu isẹ isin, debi i pe o darapọ mọ ẹgbẹ akọrin.

Bakan naa, oun lo tun ma n ṣi ilẹkun ṣọọṣi, o di ẹni to n lu agogo, to si tun n tun ori pẹpẹ iwaasu ṣe.

Bawo lo tun ṣe wa a di ẹni to n difa?

Alagba Peter Fatomilọla tun ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo naa lori awọn apẹẹrẹ to fi mọ pe oun yoo di ẹni to n difa.

O ni lasiko ti awọn ẹlẹsin Ifa ba ti fẹ ẹ ṣe isin wọn nile baba oun, ṣe ni oun tete ma n ji lati tun ile ipade wọn ṣe.

"Lẹyin ti mo ba tun ṣe tan, emi ni ma a kọkọ joko si ibi ipade. A ma n kọrin, a ma n jo,bẹ ẹ si ni iwaasu ma n wa. Gbogbo nkan ti a n ṣe, ko yatọ si ti ṣọọṣi.

"Ki n to o pe ẹni ọdun mejidinlogun, mo ti mọ bi a ṣe n difa daadaa."

O ni nipasẹ awọn oriṣiriṣi eto to ma n waye nibi ijọsin awọn Onifa, ni oun fi bẹrẹ si ni ṣe ere ori itage, kọ ere ori itage, to si fi di ogbontarigi.

Amọ ṣa, Fatomilọla sọ pe ẹkọ iwe ko jẹ ki ọmọ oun kankan o foju si bi wọn ṣe n difa.