Ifa Worshippers: Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń fẹ́ kíjọba pín èrè òṣèlú alágbádá yíká gbogbo ẹ̀sìn
Yoruba ni tiwa n tiwa, akisa ni ti aatan, ọmọ kii si ba ipele iya rẹ, ko si asọ da.
Ẹsin abalaye ti kọja bẹẹ pẹlu awọn agbelarugẹ to ti baa ati ọpọn imọ to wa ninu rẹ.
Lasiko ti BBC Yoruba lọ jọsin pẹlu awọn onisẹse ti ijọ Imọlẹ Olodumare, a ri pe diẹ ni iyatọ to wa laarin bi wọn se n jọsin nibẹ ati nile ijọsin tawọn ọmọlẹyin Kristi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
Se ti orin aladun lati ẹnu awọn ẹgbẹ akọrin wọn ni abi ọna tawọn ẹlẹyinju ẹgẹ obinrin ati alakọwe n gba jere ọkan si iwa rere lawujọ wa.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Ọmọwe Ifayemi Ifatunde ni awọn onisẹse n fẹ ki ijọba pin ere iselu alagbada de ọdọ gbogbo ẹsin pata pata.
Bakan naa lo tun n fẹ ki ijọba pese gbogbo anfaani to n fun awọn Kristiẹni ati Musulumi de ọdọ awọn onisẹse.