Yoruba Taboo: Èèwọ̀ ni fún ọba láti gbé Bibeli tabi Kurani dání dípò ifá- Elebuibon, Agẹṣin Àdìmúlà

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo oba adeyemi lamidi III
"Ọpọlọpọ ọba ti a n pe ni ọba ni ilẹ Yoruba bayii ni ko ba" iyẹn ni pe wọn kii ṣe ọba.
Eyi ni ọrọ ọkan lara awọn afọbajẹ ilẹ Yoruba kan, Oloye Fagbenle Adedayọ Agẹṣin Adimula ati afọbajẹ ilu Ila Ọrangun ọkan lara awọn ilu iṣẹmbaye ilẹ Yoruba.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Agẹsin Adimula ilu Ila Ọrangun ṣalaye pe awọn ọbalaye kan wa lori itẹ ti wọn kii ṣe ọba bayii eleyi to si n faa ti eku ko fi n ke bi eku ti ẹyẹ ko si maa ke bi ẹyẹ mọ lawọn apa kan ilẹ Yoruba bayii.
- Ìgbín, iṣu, epo, àádùn, obì, iyọ àti oyin wa lára ohun ti a fi sọ ọmọ tuntun Ọọni Ifẹ lórúkọ!
- Àwọn Olúkọ ìpínlẹ̀ Oyo fakọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà púpọ̀
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Wo bí wọ́n ṣe sìnkú àwọn àgbẹ̀ 43 tí Boko haram dúmbú ní Borno
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara
Bakan naa ni Araba ti ilu Osogbo, Oloye Fayẹmi Ẹlẹbuibọn pẹlu kin ọrọ yii lẹyin ti wọn ni ọba ti ko ba ṣe oro ibilẹ ki o to de ori oye kii ṣe Ọba.
Oloye Ẹlẹbuibọn ni ohun to mu ki ọba yatọ si awọn eeyan yoku naa ni "oro ti ọba nṣe, ẹkọ ti wọn kọ ọba, awọn nnkan ibilẹ bii ifoju ba odu ati mimu wọn tẹ ifa pẹlu ṣiṣe oro idile gbogbo ti wọn jọba le lori fun wọn. Nnkan to jẹ ki ọba o yatọ si eeyan lasan niyẹn. Ọba ti ko ba si ti ṣe kii ṣe ọba niyẹn".
Oloye Adedayọ ṣalaye pe Ọba yoo wu to ba dori aleefa ni ilana Bibeli tabi Kurani kii ṣe Ọba gẹgẹ bi ilana Ọba jijẹ ni ilẹ Yoruba.
"Ọba ti a lee pe ni Ọba, ti aṣa Yoruba wa lori rẹ, ti awọn eewọ Yoruba si wa lori rẹ ni awọn ọba to jẹ wi pe bi awọn baba nla wa ṣe nfi ọba jẹ ni wọn ṣe fi wọn jẹ,"
O ni ọba ti yoo ba pe ara rẹ ni ọba ni ilẹ Yoruba gbọdọ jẹ ọba ti wọn ṣe iwadii rẹ lati inu ifa, to si de ipebi to si lo iye ọjọ to yẹ ko lo ni ipebi; to si jẹ gbogbo nnkan to yẹ ko jẹ, to si yẹ ko mu mu.
Baba Ẹlẹbuibọn ni Ọba to ba rọ mọ Bibeli tabi Kurani lori oye gbọdọ ranti pe ilẹ Yoruba ni oun ti jẹ ọba kii ṣe ilẹ Larubawa tabi Isrẹli. O ni ọpọ ohun ti awọn ọba n dimu lara ẹsin ilẹ okeere lo n tako ilana ilẹ Yoruba ati ohun ti ọba ni lati mọ.

Oríṣun àwòrán, Ile oodua
O ni ẹnikẹni to ba ti mọ pe oun yoo tẹle ẹsin okeere dipo atọna iṣẹmbaye ti wọn fi jọba gbọdọ fi oye silẹ fun awọn ọmọ oye ti wọn 'setan lati tẹle ilana ọpakutẹlẹ fun ọba jijẹ nilẹ Yoruba.
Oloye Agẹsin Adimula naa fara kin ohun ti baba Ẹlẹbubọn ṣe ni alaye. O ni ko si ohun ẹni to lee fi atọna miran to yatọ si ifa jẹ ọba nilẹ Yoruba ti ko ni ta ko awọn eewọ gbogbo ti ipo naa da le lori ti yoo si ni ipa lori ilu.
Ọba maa n jẹ ẹdọ eeyan ko to de ipo ọba, ṣe ootọ ni ọrọ yii?

Oríṣun àwòrán, Ile oodua
Lati ọjọ pipẹ lawọn igbagbọ kan ti waye nipasẹ iroyin tawọn eeyan ti gbọ nipa jijẹ ọba nilẹ Yoruba. Lara rẹ ni pe gbogbo ẹni ba ti n jẹ ọba lo gbọdọ jẹ ẹdọ tabi ọkan eeyan ki o to jọba?
Gẹgẹ bi alaye ti Araba ti ilu Oṣogbo, oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ṣe fun BBC News Yoruba, ko si ọba to n jẹ ọkan ki o to de ori itẹ. Oloye Ẹlẹbuibọn ni ara ọna ti awọn ẹlẹsin okeere fi ba ẹsin abalaye jẹ niyi ki awọn eeyan lee maa fi oju ibajẹ wo ẹsin naa.
Baba ni lootọ oro wa ti wọn maa n ṣe fun ẹni to ba fẹ jẹ ọba ni ilẹ Yoruba,oro yii ni wọn maa ni ki ọba jẹ ti wọn yoo si bii pe ki lo jẹ o ti oun naa yoo si dahun pe oun ti jẹ ọba, amọṣa gẹgẹ bi ayipada ti ṣe ba ọpọlọpọ nnkan lawọn ẹsin okeere wọnyii naa ni ayipada ti de ba ọpọlọpọ nnkan ni iṣẹṣe nilẹ Yoruba.
Oloye Agẹṣin adimula ila pẹlu ṣalaye pe, lootọ laye atijọ awọn eeyan kan maa n sọ ọ kiri pe ọba n jẹ ẹdọ eeyan ki o to jsba, amọṣa kii ṣe otitọ.
O ni ara awọn agbekalẹ ti awsn eeyan kan ti ko mọ nipa ọrọ ọba jijẹ nilẹ Yoruba maa n sọ kaakiri ni eyi lati lee gbin ẹru ati ọwọ yii ipo ọba ka.
"Aye ọjọun lawọn kan n parọ, ọba kan kii jẹ ẹdọ, irọ ni wọn n pa. Ohun ti a n pe ni ijẹ ọba inu ẹsẹ ifa lo wa"
Ifa ni yoo yan Ọba gẹgẹ bi oloye Agẹṣin Adimula ṣe sọ, koda, ifa ni wọn n ṣe fun ọba to fii di Ọba alade ni ilẹ Yoruba, kii ṣe ẹdọ jijẹ gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe maa n sọ.
O ni gbogbo ahesọ ọrọ bẹẹ lo wa ki awọn eeyan lee maa bẹru ọba ati paapaa ki wọn le maa wo o pe hee,
Ipalara to wa fun ilu ti ọba ba gba ẹsin to yatọ si ilana iṣẹmbaye

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo Oba Adeyemi Lamidi III
Gẹgẹ bi baba Ifayẹmi ẹlẹbuibọn ṣe sọ, ipalara wa fun ilu ati Ọba gan to jẹ laifi ti ilana ijọba ni ilẹ Yoruba ṣe.
Baba ṣe apẹlrẹ ilu ile ifẹ nigba ti awọn ijoye Ọọni ba fẹ kii, wọn a ni "eku a jiṣẹ, ẹja a jiṣẹ, ẹran a jiṣẹ, owo a jiṣẹ" Riran ni wọn n ran awọn nnkan wọnyii ni iṣẹ gẹgẹ bi iwure ni.
Bi ọba kan ba wa kọ to ni ilana larubawa tabi Isrẹli loun yoo tẹlẹ, ohun ti wọn fi sọri ilẹ Yoruba yatọ si ohun ti wọn fi sọri ilẹ awọn ilu ti ẹsin okeere wọnyii ti wa.
O nigẹgẹ bi gbogbo eewọ ṣe ni atunbọtan naa ni igbesẹ ọba lati yẹ kuro loju opo iṣẹṣẹ ti eto ijẹọba nilẹ Yoruba dale naa ṣe ni atunbọtan.














