Ọọni Adeyeye gbé orúkọ àrẹ̀mọ rẹ̀ jáde, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ǹkan tí wọ́n fi gbàdúrà f'ọ́mọ ọba

Aworan Ooni

Oríṣun àwòrán, Ooniadimula

Ilẹ Yoruba ni asa isọmọlorukọ ara ọtọ

Bẹẹ idalu kuku ni iṣelu ni awon agba n sọ.

Awọn ohun eelo ati ohun ti ẹnu n jẹ ni awọn agba maa n ko sita fi ṣadura fun ikoko tuntun ti a ba bi nilẹ oodua.

Ni ọjọ mẹjọ si ni ikomọjade ọmọ tuntun nilẹ Yoruba.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Ni ibi isọmọlorukọ Arẹmọ Oba Adeyey Ogunwusi, Ojaja I to jẹ Oọni Ile Ife ni awọn ohun eelo ikomọjade tun ti jade.

Oyin. Orogbo, Obi, Iyọ suga, Ireke, Aadun, Igbin, Ẹja, ỌtiṢinaapu ati awọn nkan miran ni awọn agbaagba lo lati fi sọ ọmọ tuntun ti a bi na ni orukọ.

Awọn ohun eelo yii mu awọn adura ati asọtẹlẹ da ni fun ẹjẹ ọrun tuntun naa ni eyi to n mu aṣẹ dani ninu igbagbọ iran Yoruba.

Taa ni Ọọni àná tí Ọba Ogunwusi forúkọ ọmọ rẹ̀ sọ?

Ooni ile Ifẹ, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti muleri ṣẹ lori adehun to ṣe pe oun yoo sọ ọmọ rẹ tuntun lorukọ Ooni to ṣaaju rẹ .

Fun idi eyi o ti ni ọmọ tuntun naa yoo ma jẹ orukọ pẹlu Ooni Tadenikawo Adesoji Aderemi to jẹ Ooni ṣaaju.

Ikede yi waye loju opo Twitter Ooni lẹyin ọjọ kẹjọ tọmọ naa d'aye ti wọn si ti yoo si ṣe etutu ọlọsẹmẹta tori ki o baa le ri bi o ti ṣe yẹ ko ri.

Alaafin ni awọn kan si Ifa nipasẹ Araba Agbaye olori awọn onifa lagbaye ki awọn to sọ orukọ yi di mimọ faraye.

Ooni salaye siwaju pe Araba Agbaye fi orukọ ọmọ naa le Oloye Lowa ilu Ife Adekola Adeyeye lọwọ ki wọn to wa kede rẹ setigbọ ero to pe sita.

Ẹkunrẹrẹ orukọ ọmọ naa ni Tadenikawo, Adesoji, Aderemi, Eri-Ifeoluwasimi, Adeiwa, Inioluwa, Ademide, Adegbite, Diekoloreoluwa, ọmọ Ogunwusi.

Saaju ni Ooni ti ṣadehun pe oun yoo sọ ọmọ tuntun ti a bi lọjọ Kejidinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2020 lorukọ ọkan lara awọn Ooni to jẹ saaju rẹ.

Ooni Tadenikawo Adesoji Aderemi ni o jẹ Ooni ikọkandinlaadọta ni Ile Ife.

Lasiko igbe aye rẹ, o jẹ oye Gomina adulawọ akọkọ laye eebo amunisin.

Ọba Adesọji Aderẹmi

Oríṣun àwòrán, @oluwole_dada

Àkọlé àwòrán, O jẹ ara awọn eeyan to kọkọ laju, o kọ ẹkọ iwe, o lowo, o lọla, o gbajumọ, o si jẹ asaaju ilu.

A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020 ni Ooni Ile Ife, Adeyeye Enitan Ogunwusi, kede lori ayelujara pe Olori oun, Naomi Ogunwusi, ti bi ọmọ ọmọkunrin tuntun.

Bi ọpọ awọn eeyan ṣe n ki Onirisa ayọ abara tintin, lawọn miran n sọ pe Ọba lọla lo de yẹn.

Àkọlé fídíò, Lagos King: Mátikú ọba tó lo lo ọdun mẹta lórí oyé latari rogbodiyan Eko

Ṣugbọn ṣe ootọ ni pe ọmọ tuntun ti Ooni ṣẹṣẹ bi ni yoo jẹ Ooni lọjọ iwaju?

Idi ree ti ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba ṣe kan si Araba awo ilu Oṣogbo, Ifayemi Elebuibọn lati tanj imọlẹ si ọrọ naa.

Ooni Adeyeye

Oríṣun àwòrán, Oniadimula

Elebuibọn ni, pe Ooni bi ọmọ ọkunrin ko tumọ si pe ọmọ naa ni yoo gori itẹ lọjọ iwaju.

O ni, bi wọn ṣe n yan ọba nilẹ Yoruba tẹlẹ ko to di pe ijọba ati ọlaju de, ti ijọba si n lọwọ ninu ọba yiyan.

Elebuibọn ni ki wọn to yan Ooni, tabi Ọba nilẹ Yoruba, idile ti oye ba kan lo maa fa ẹni ti wọn ba n fẹ ko dori itẹ silẹ, ti awọn afọbajẹ yoo si di ifa lati mọ boya asiko irufẹ Ọba bẹẹ yoo san awọn ara ilu.

O ni "wọ maa pe idilẹ ti oye bá kan, lẹyin naa ni wọn yoo to bi ifa lere."

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

"Awọn idile ti oye kan yoo da'fa, bẹẹ ni awọn afọbajẹ naa yoo da'fa."

O ni kii ṣe akoko niyii lati maa sọ pe ọmọ tuntun ti Ooni bi ni yoo di Ọba lọla "nitori wọn ko mọ iru ori to yan, Ọba le bi ọmọ mẹwaa, kii si ṣe dandan ni pe akọbi ni yoo gori itẹ lẹyin baba rẹ, o le jẹ abigbẹyin."

Fun gbogbo awọn to n sọ pe Ooni ti bi Ọba lọla, Elebuibon sọ pe ti wọn ni wọn n sọ yẹn nitori gbogbo igi kọ lo maa n so olu.

Araba awo ilu Oṣogbo pari ọrọ rẹ pe, ifa lo ma n yan Ọba laye atijọ, ṣugbọn bayii oju ni wọn fi n yan ẹni to lọla tabi to lorukọ lawujọ lati di ọba.

O ni "eeyan le lowo lọwọ ṣugbọn ko ma lori oye."

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Oluwo Ìwo ṣ'àlàye lori oyé oba oni lawàni