Operation Falcon: Omi tẹ̀yìn wọ̀gbín lẹ́nu fáwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta tó lu èèyàn 50,000 ní gbájúẹ̀ jákèjádò àgbáyé

Aworan awọn afurasi ti ọwọ tẹ

Oríṣun àwòrán, Interpol

Awọn afurasi ọmọ Naijiria mẹta kan to lu ijọba ati awọn ọlọdani lorileede to le ni aadọjọ ni gbajuẹ lọwọ ti tẹ nilu Eko.

Agbarijọpọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ati akẹgbẹ wọn lati Interpol ni wọn pawọpọ mu awọn afurasi wọn yi.

O le ni ọdun kan tawọn agbofinro ti n tọ pinpin wọn ti wọn si ti ri eeyan ẹgbẹrun lọna aadọta ti wọn ti ko si ọwọ awọn aṣebi yi.

Gẹgẹ bi alaye ti Interpol fi sita ninu atẹjade, wọn ni ''niṣe lawọn afurasi wọn yi fọna ẹburu lu awọn eeyan ni gbajuẹ nipa fifi imeeli ayederu ransẹ''

Wọn tẹsiwaju pe wọn lo awọn ''virus'' buruku ti wọn fi ranṣẹ yi wọ inu akoto owo ileeṣẹ ijọba ati awọn ileeṣẹ ọlọdani to le ni aadọjọ kaakiri agbaye.

Interpol ko darukọ wn lẹkunrẹrẹ ninu atjade naa ṣugbọn wn ni awọn tọwọ tẹ wa lara ikọ onigbajuẹ to pin si ẹka lorisirisi.

Wọn ni awọn ṣi n wa awọn to ku ti iwadii ṣi n tẹsiwaju.

Awọn onwoye sọ pe lasiko ajakalẹ Coronavirus yi, niṣe ni ọwọja awọn to n lu gbajuẹ oju ayelujara n pọ si.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá