Crime: Ọwọ́ ṣìnkún EFCC tẹ àfurasí ọmọ ‘Yahoo’ mẹ́fà n‘Ibadan

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc
Ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kansoso pere ni ti olohun, bi irọ ba si lọ titi fun ogun ọdun, ọjọ kan soso bayii ni otitọ yoo baa.
Bẹẹ lọrọ ri fun awọn gende ọkunrin kan ti wọn fura si pe wọn n lu jibiti jẹun, taa mọ si ọmọ Yahoo, tọwọ palaba wọn segi nilu Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀bí àti ọ̀rẹ̀ ní mo kó lọ sí Dubai fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọlọ́sẹ̀ kan fún màmá mi - Gbajabiamila
- Lẹ́yìn ò rẹyìn, Amotekun dòhun, gbogbo ilé aṣòfin nílẹ̀ Yorùbá fòǹtẹ̀ lu
- "N kò jalè rí, ọtí àmuyó ló jẹ́ kí ń jí káàdì ìpè àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀"
- Ile aṣòfin Kwara yí orukọ fásitì ìpínlẹ̀ náà kúrò ní fásitì Olusola Saraki
Atẹjade kan ti ajọ to n gbogun ti iwa ọdaran nilu owona, EFCC fisita, loju opo Instagram rẹ salaye pe, awọn afurasi ọmọ yahoo tọwọ tẹ naa jẹ mẹfa niye.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Atẹjade naa ni adugbo Oluyọle ati Alao Akala ni ọwọ sinkun awọn osisẹ ajọ EFCC ti ba awọn afurasi ọmọ Yahoo naa, ninu eyiti obinrin kan wa laarin wọn.
Ohun to wa yani lẹnu nipa awọn afurasi ọmọ Yahoo yii, ni ti posi kekere kan, to jẹ apoti oogun abẹnu gọngọ ti wọn ka mọ mọ wọn lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc
Inu ile ọkan lara awọn afurasi onijibiti naa, tii se ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ni awọn osisẹ ajọ EFCC ti ri posi oogun ọhun, to ni asọ funfun ninu, lasiko ti wsn ya bo ile rẹ lọjọ Aje to kọja.
- Ẹ jẹ́ ká dá ìbọn kọjá, tó bá jẹ́ pé Oluwo kò fìyà jẹ́ mí - Agbowu
- Ilé aṣòfin Oyo àti Ogun buwọ́lu àbádòfin ikọ̀ aláàbò Amotekun
- Nǹkan yan, kò sí àmì ìfẹ́ mọ́! Ìbọ̀wọ́ tàbí ìfẹnukora d‘èèwọ̀ torí Coronavirus
- "Ẹ gbà wá o! òru láwọn adigunjalè fi ń yọ gbogbo ẹ̀yà ara ọkọ̀ wa l‘Eko, dípò kí wọ́n ji gbé lọ"
Lasiko ti wọn fi ọrọ wa lẹnu wo lori ohun to n fi posi naa se, afurasi onijibiti naa ni igba ọsẹ ni ohun n lo posi kekere naa fun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc
Lara awọn eroja ti EFCC ri gba pada lọwọ awọn afurasi onijibiti naa ni ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin, ọpọlọpọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ olowo iyebiye ati aimọye kaadi ti wọn fi n gba owo lẹnu ẹrọ ATM.
"N kò jalè rí, ọtí àmuyó ló jẹ́ kí ń jí káàdì ìpè àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀"
Saaju la ti kọkọ sọ fun yin pe, ile ẹjọ Majistreti kan nipinlẹ Ebonyi ti ju ọkunrin ẹni ogun ọdun kan, si ẹwọn oṣu mẹta fun pe o ji kaadi ipe ẹrọ ibanisọrọ ati ẹrọ ibanisọrọ kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin naa sọ pe Elochukwu Sunday fi ipa gba ẹrọ ibanisọrọ alagbeka ati kaadi ipe lọwọ obinrin kan, Felicia Ezeaku, lẹyin naa lo tun gba ẹgbẹrun mẹrindinlogun naira lọwọ rẹ.
Wọn ni o ṣẹ ẹṣẹ naa ni adugbo Nkwogu nijọba ibilẹ Abakaliki nipinlẹ naa, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kinni ọdun 2020.
Eyi lo si mu ki wọn o gbe e lọ sile ẹjọ lẹyin ti ọwọ tẹ, wọn si fi ẹsun ole jija kan an.
Isipẹkitọ ọlọpaa to wọ ọ lọ sile ẹjọ sọ pe, ẹṣẹ to ṣẹ ni ijiya labẹ ofin iwa ọdaran ni Naijiria.
- Iléẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọ̀daràn tó jí owó àti ẹ̀rọ ìbáraẹni sọ̀rọ̀ l‘Ekiti
- "Àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn bí mo ṣe yípadà láti obìnrin sí ọkùnrin, ń kò bá tí ṣe bẹ́ẹ̀"
- "Ẹ gbà wá o! Òru láwọn adigunjalè fi ń yọ gbogbo ẹ̀yà ara ọkọ̀ wa l‘Eko, dípò kí wọ́n ji gbé lọ"
- Ẹ jẹ́ ká dá ìbọn kọjá, tó bá jẹ́ pé Oluwo kò fìyà jẹ́ mí - Agbowu
Ẹrọ ibanisọrọ naa ni wọn ni owo rẹ to ẹgbẹrun marun Naira, nigba ti kaadi ipe si to ẹgbẹrun mejila Naira.
Sunday jẹwọ pe, lootọ ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn ọti ti oun mu yo lo mu oun hu iwakiwa.
"Mo jẹbi. Ọti amuyo lo mu mi hu iwa naa. Mi o jale ri. Idanwo lo jẹ fun mi, ẹ dakun ẹ darijimi."
Amọ ninu idajọ rẹ, Adajọ Majistreti Esther Ezeugo sọ pe ṣiṣe idajọ maa n rọrun ti ẹlẹbi ba ti bẹbẹ fun aanu.
Ẹbẹ Sunday lo si ni o mu ki oun dajọ ẹwọn oṣu mẹta fun un laisan owo itanran kankan.













