Ekiti Robbery: Ọ̀daràn kan rí ìkú he nítori o ji owó àti fóònù ní Ekiti

Oríṣun àwòrán, other
Ile ẹjọ giga kan ti da ẹjọ iku fun ọkunrin kan, Isa Abdulkareem fun ẹsun ole jija.
Adajọ Mosunmola Abọdunde lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ sọ pe, awọn olupẹjọ fihan gbangba pe lootọ ni olujẹjọ naa jẹbi ẹsun naa.
Lasiko igbẹjọ naa, ẹsun ti wọn fi kan Abdulkareem ni pe o ja Adeya Olalekan ni ole owo toto ẹgbẹrun lọna mẹrinlelaadọrin naira ati foonu Infinix Note 2 kan.
Bakan naa ni wọn lo tun fi ibọn ati ada gba owo to to ẹgbẹrun lọna aadọfa naira lọwọ ọkunrin kan, Taiwo Olomola, to si tun gba awọn foonu Techno lọwọ rẹ.
Eniyan mẹrin ti iṣẹlẹ naa waye ni oju rẹ sọ wi pe, arakunrin naa lo ibọn meji, ọta ibọn mẹta ati ẹrọ ilewọ, ọdun 2016 si ni iṣẹlẹ yii waye ni ilu Ado Ekiti ni ipinlẹ Ekiti.
- Nàíjíríà, ẹ fakọyọ lórí ìdènà Coronavirus àmọ ìròyìn òfegè léè ṣọṣẹ́ tẹ̀ bá ṣọ́ra - WHO
- Àfagbárawọ̀ ló jẹ́ fáwọn arìnrìnàjò láti wọ pápákọ̀ òfurufú Nàíjíríà torí Coronavirus! Àwòrán rèé
- Nàíjíríà kò gba gbẹ̀rẹ́ lórí Coronavirus, wo itú tà ń pa láti dènà alárùn ní pápákọ̀ òfurufú wa
- Ọmọ Nàìjíríà di agbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ tó ní ààrùn Coronavirus
Iwadii fihan wi pe, nibi ti arakunrin naa ti jale ni wọn ti mu, ti awọn eniyan to wa nibẹ si jẹri pe lootọ lo huwa aida naa.
Koda, olujẹjọ ọhun, Abdulkareem naa fihan gbangba pe oun jẹbi ẹsun naa, ki adajọ to da ẹjọ yii.








