Coronavirus: Báyìí ni nkan ṣe n lọ ní pápákọ̀ ọkọ̀ òfurufú l'Eko lẹ́yìn tí Coronavirus wọ́lé

Gbogbo awọn to n wọle, tabi jade kuro ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed lo n gba abẹ ayẹwo kọja
Àkọlé àwòrán, Gbogbo awọn to n wọle, tabi jade kuro ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed lo n gba abẹ ayẹwo kọja
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Yatọ si irinṣẹ ti wọn n mu dani, ẹrọ kan tun wa bi kamẹra to n ṣe ayẹwo awọn eero baalu fun apẹẹrẹ aarun Coronavirus
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi awọn oṣiṣẹ eto ilera lo wa ni ikalẹ ni papakọ ofurufu ilu Eko fun ayẹwo awọn arinrinajo
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Koda, wọn gbe omi aporo kokoro aifojuri 'sanitizer' silẹ fun awọn arinrinajo
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Ati oṣiṣẹ ati eero baalu lo n lo iboju lati ba ara wọn sọrọ nitori Coronavirus
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Kii ṣe ita papakọ ofurufu nikan ni ikiyesara ti n waye, gbagbaagba ni kaluku n boju-bomu ninu ọfiisi.
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Ẹrọ ayaworan wa tun gbe oṣiṣẹ eto ilera kan to wa lẹnu iṣẹ t'oun ti iboju ati ìbọ̀wọ́
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Ṣugbọn o, Coronavirus ko da wiwọle ati jijade ni Naijiria duro ni papakọ ofurufu naa. Kẹti-kẹti ni eero n ya lati wọ baalu.
Awọn eero ni papakọ ofurufu Eko
Àkọlé àwòrán, Igbesẹ oju lalakan fi n sọri ọhun ko yọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n risi iwọle-wọde (Immigration) silẹ. Iboju lawọn naa fi ṣe koju o ma ri ibi.