Coronavirus: Ọmọ Nàìjíríà di agbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ tó ní ààrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan to jẹ agbabọọlu ni Italy ti di agbabọọlu ta akọkọ to ni aatun coronavirus.
King Paul Akpan Udoh to n gba bọọlu fun Pianese ninu idije Serie C, ni ayẹwo fihan pe o ni aarun naa.
Iroyin si sọ pe o ya ara rẹ sọtọ ni kete ti o n ri apẹẹrẹ aarun naa.
Nibayi, awọn agbabọọlu ti n fi ibẹru wọn han lori ipa ti aarun coronavirus yoo ni, paapa bi wọn ti ṣe kan si awọn ẹgbẹ agbabọọlu nitori ibẹru pe o ṣeeṣe ki wọn o fi dandan mu wọn lati gba bọọlu nibi ti aarun naa wa
Ninu atẹjade kan ti ajọ agbaye kan, Fifpro fi sita, o sọ pe ewu wa ninu bọọlu gbigba , nitori o le di ọna ti aarun naa yoo ma gba tan kalẹ.
"Ijiroro wa pẹlu awọn to ni nkan ṣe pẹlu bọọlu gbigba tun bojuwo pe ki wọn o sun awọn idije agbaye si ọjọ miran, to fi mọ igbaradi fun Tokyo Olympics ati ife agbaye FIFA World Cup 2022.








