Coronavirus in Nigeria: Sanwo-Olu ní ètò wà nílẹ̀ láti káwọ́ Coronavirus l'Eko

ayewo fawon eeyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede pe ọmọ orilẹede Italy kan ti ko aarun gbẹmigbẹmi Corona virus wọ orilẹede Naijiria, ijọba ipinlẹ Eko nibi ti wọn ti kẹẹfin arakunrin naa ni awọn ti gbe igbesẹ lati dojukọ arun naa ni kiakia.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo twitter rẹ, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ni kete ti awọn kẹẹfin pe eeyan kan ti ko arun naa ni wọn fi to ijọba apapọ leti.

O ni iṣejọba oun ti bẹrẹ si ni tẹmpẹlẹ mọ igbesẹ lati rii pe arun naa ko di tọrọ fọnka le ni ipinlẹ Eko.

O ni igbesẹ yii wa nikalẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu igbimọ ojulalakan fii ṣọri onisọri-isọri ti wọn gbe kalẹ labẹ akoso ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC.

O ni ijọba ti tan ina ibudo eto pajawiri silẹ bayii lẹyẹ-o-ṣọka lati moju to ọrọ naa ki wọn si mu iṣẹ ṣe lori igbesẹ to ba yẹ ni didena rẹ.

O wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko lati maṣe ko ọkan soke. Ki wọn maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ ki wọn si maa ṣamulo awọn eto imọtoto gbogbo to yẹ.

Coronavirus: Okùnrin ọmọ Italy kan ti kó àrùn Coronavirus wọ Naijiria- Iléeṣẹ́ ètò ìlera

Ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si iṣakoso arun ti sọ pe arun Coronavirus ti apẹle rẹ n jẹ COVID-19 ti tan de Naijiria.

Gẹgẹ bi ọrọ to fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni "Minisita fun eto ilera ti fi idi rẹ mulẹ pe arun Coronaviorus ti ṣeyọ nilu Eko."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe, wọn fidi arun ọhun mulẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn Oṣu Keji ọdun 2020, leyi to jẹ akọkọ iru rẹ ni Naijiria lati igba ti arun na ti ṣeyọ loṣu Kinni ọdun lorilẹ-ede China.

Ẹni to ni arun naa jẹ ọmọ orilẹ-ede Italy to n ṣe iṣẹ aje ni Naijiria.

Okunrin naa rinrin ajo wa si ilu Eko lati ilu Milan lọjọ karundinlọgbọn Oṣu Keji, ki wọn to ṣayẹwo rẹ nile ẹkọṣẹ iṣegun to wa ni Fasiti ipinlẹ Eko.

Eyii ni igabkeji ti awọn eleto ilera yoo fidi arun naa mulẹ nilẹ adanlawọ lẹyin ti wọn ti ṣaaju fidi rẹ mulẹ ni lorilẹ-ede Algeria ati iha Ariwa Afrika.

Àkọlé fídíò, Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀

Ni bayii, ajakalẹ arun Coronavirus ọhun ti tan de orilẹ-ede ti ko din ni ogun kaakiri agbaye lagbegbe Asia, Yuroopu, ati Afrika.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ti kọkọ sọ ko si aarun coronavirus ni ipinlẹ naa, lẹyin ti ayẹwo fihan pe ọmọ orilẹ-ede China kan ko ni aarun COVID-19 ọhun.

Ẹwẹ, minisita fun eto ilera Naijiria, Osagie Ehanire ti sọ ninu atẹjade kan pe ijọba apapọ n ṣe isẹ takuntakun lati ri pe arun naa ko tan kalẹ ju boṣe lọ ni Naijiria.

Osagie ni iṣe n lọ lọwọ lati ṣawari gbogbo awọn ti okunrin ọhun ba pade ninu irinajo rẹ lati ilẹ Italy si ilu Eko.

O wa rọ awọn ara ilu lati ma lo oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye lati maa pin awọn iroyin ofege nipa arun naa, leyi to lee fa ibẹru sọkan awọn eeyan.

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'