Ilé-iṣẹ́ ọmọogun mú ọmọbìnrin tó gbé ìbọn AK-47 kọ́rùn jó nibi ayẹyẹ kan-

Oríṣun àwòrán, other
Àwọn ọmọ ológun Naijiria ti mú afúnrasi ọdaran kan ti o ń jẹ́ Zainab Abubaka ni Ungwan Salaha Mararaban ní ìjọba ibilẹ Igabi abule àwọn Jos ni ìpínlẹ̀ Kaduna.
Àwọn ọmọ ogun sọ lọ́jọ́bọ pé nínú ẹrọ ìléwọ rẹ̀ ni àwọn ti kọ́kọ́ ri níbi ti o ti gbé ìbọn AK-47 kọ́rùn to sì n jó.
Ìròyìn fi yéni pé àwọn ọmọ ogun lábẹ́ Operation Mesa gbé Abubakar ni ọjọ Ajé.
Alábojutol ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ to n lọ nilé iṣẹ́ ológun Ọgagun Aminu IIiyasu, to fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn oníròyìn sọ pé àwọn ti mú ọmọbinrin to gbé ibọn kọ́run to si n jó ni bi ayẹyẹ kan.
Ikọ kan náà lo tun ṣe alabapade, àwọn kan ni abule Kirsa nijọba ibilẹ Anka ni Zamfara nibi ti ọkùnrin kan ti gbe ọmọbinrin kan sùgbọ́n ni kété to ri àwọn ọmọologun lo fi ọkada rẹ àti ọmọbinrin náà silẹ to si sa wọ igbó lọ, sùgbọ́n ọmọ ogun bá ibọn AK-47 ti o si ni ọta bi ọgbọ̀n ninu.









