Coronavirus in Nigeria: Ọmọ Italy tó kọ́kọ́ kó Coronavirus wọ Eko tún lọ́ sí ìpínlẹ̀ Ogun nàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileewosan Mainland Hospital ti wọn ti n tọju ajakalẹ aarun ni adugbo Yaba nilu Eko ni ọmọ orilẹ-ede Italy to ko aarun Coronavirus wọ ipinlẹ Eko ti n gba itọju lọwọlọwọ.
Dokita Abimbola Bowale to gba ẹnu ileewosan naa sọrọ sọ diẹ lara nkan to yẹ lati mọ nipa ọkunrin naa fun BBC:
- Ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni ọkunrin naa jẹ
- Gbogbo awọn ayẹwo bi ifunpa, ara gbigbona ati bẹẹbẹ lọ wa ni ipo to dara bayii
- Itọju ti wọn n fun n wọ ọ lara dara-dara
- O wa si orilẹ-ede Naijiria lati ṣe iṣẹ fun awọn ileeṣẹ kan ni
- Ọjọ keji to de Naijiria lo dubulẹ aisan, wọn si ṣayẹwo rẹ ni ileewosan ileeṣẹ naa
- Dokita to yẹ ẹ wo fura pe o ṣeese ko jẹ aarun Coronavirus lo ni nitori pe bi o ṣe ṣẹṣẹ de lati Italy, eyi lo si mu ki wọn o gbe lọ si ileewosan Mainland Hospital ni Yaba ni aarọ ana
- Nibẹ ni wọn si ti fidirẹmulẹ pe o ni i
Kìí ṣe ìpínlẹ̀ Eko nìkan ni ọkùnrin nàá dé, ó lọ sí Ogun nàá
Ọmọ orilẹ-ede Italy to kọkọ gbe aarun Coronavirus wọ ipinlẹ Eko, l'orilẹ-ede Naijiria tun lọ si ipinlẹ Ogun ni kete to de lati ilu Milan to jẹ olu ilu Italy ko to o di pe wọn fidirẹmulẹ pe o ni aarun naa.
Eyi ni nkan ti kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso sọ fun BBC lọjọ Ẹti.
Kíni ìjọba n ṣe láti dín ìtànkálẹ̀ ààrùn nàá kù?
Minisita fun eto ilera ni Naijiria, Osagie Ehanire naa si ti sọ pe awọn ti ran dokita to le ni ọgọta lọ si papakọ ofurufu Murtala Muhammad to wa l'Eko, lati ṣeranwọ ninu ayẹwo awọn arinrinajo to n wọle.
Minisita sọ pe awọn ti wa ni igbaradi lati doju ogun kọ aarun naa.
O sọ pe awọn ti ajọ to n mojuto aarun ni Naijiria, NCDC n ṣiṣẹ pẹlu ti ṣe idasilẹ ibudo itọju pajawiri kan, wọn o si maa ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko lati ka a lapa ko.

O sọ pe awọn kan wa to jẹ pe aisan diẹ ni yoo ṣe wọn ti wọn ba ni aarun naa, ti ara wọn yoo si ya.
Ṣugbọn awọn to ba ti darugbo, ati awọn to ba ti n ṣaiṣan ko to o mu wọn ni yoo le koko.
Ọjọbọ ni ileeṣẹ eto ilera Naijiria fidirẹmulẹ pe ẹnikan ti gbe aarun naa wọ ipinlẹ Eko.
Naijiria si ni o ni akọsilẹ ẹni akọkọ to ni aarun Coronavirus lagbegbe ilẹ olooru Afirika.
Awọn alaṣẹ ṣalaye pe ọmọ orilẹ-ede Italy kan to gunlẹ sorilẹede Naijiria lọjọ mẹta sẹyin ti ko aarun naa.
Ati wi pe ayẹwo ti wọn ṣe fun ọkunrin naa ni papakọ ofurufu ilu Eko ko fihan pe o ni aarun naa nitori pe aarun naa kii tete fi apẹẹrẹ han lara.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn ti ṣe agbeyẹwo akọsilẹ orukọ awọn to wọ baalu pẹlu rẹ, ti wọn si ti n wa wọn.
Botilẹjẹ pe iṣẹlẹ yii ti da ibẹru silẹ, ijọba sọ pe oun ko ni i titori eyi da awọn baalu to n wọle lati okeere duro. tabi fi awọn arinrinajo si ipamọ.
Atẹjade kan lati ọdọ minisita feto ilera, Dokita Osagie Ehanire, eyi tawọn ileeṣẹ iroyin abẹle gbe sita ṣalaye pe, "Ọmọ orilẹede Italy kan to n ṣiṣẹ lorilẹede Naijiria lo ko aarun naa wọle nigba to pada de si Naijiria lati ilu Milan ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun.
Alaisan naa wa labẹ itọju ni ileewosan fun wiwo ajakalẹ aarun to wa ni Yaba, nilu Eko, "
Wọn ti kọkọ fura aarun yii lorilẹ-ede Egypt ati Algeria, ṣugbọn ko tii yọju ni agbegbe ilẹ olooru .
Pupọ awọn orilẹede Afirika lo ni ajọṣepọ okoowo ati ọrọ aje pẹlu orilẹede China.
Ni Ọjọbọ ni igbakeji olori ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ ni ile aṣofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ajayi Borrofice ti bẹnu atẹ lu eto ti awọn alaṣẹ gbe kalẹ fun didena aarun Coronavirus.
Ni opin ọsẹ to kọja ni ajọ ilera agbaye, WHO ṣekilọ pe ọpọ awọn ilana eto ilera lawọn orilẹede Afirika ni ko duro deede lati koju ajakalẹ arun Coronavirus yii.














