Odunlade Adekola yarí, ó ní kí àwọn òṣèrébìnrin tí òun bá sùn yọjú síta

Odunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Instagram/odunlade adekola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oṣere tiata lọkunrin, Odunlade Adekola ti fesi si iroyin kan to n lọ lori ayelujara, paapaa Instagram pe o ma n ba awọn obinrin ni ibalopọ, ko to o fi wọn sinu ere.

Ninu fidio kan to fi sita ni ọsan Ọjọbọ lo ti fesi si iroyin naa.

Ọjọ diẹ sẹyin ni akọroyin ori ayelujara Instagram kan, Gistlovers blog gbe iroyin sita pe Odunlade Adekola ma n ba awọn oṣerebinrin to wa labẹ rẹ ni ibalopọ ko to o fun wọn ni iṣẹ ṣe.

Iroyin naa sọ pe ilana fẹyin lelẹ ki n ba ọ sun, ko o ṣe ninu ere mi ni Adekola n lo.

Ko tan sibẹ o, iroyin ọhun tọka si awọn gbajumọ oṣerebinrin mẹta, Taiwo Aromokun, Eniola Ajao ati Bukola Adeeyo, gẹgẹ bi awọn ti Adekola ṣe iru nkan bẹẹ fun.

Àkọlé fídíò, Lóòtọ́ orin mi àti Lagbaja jọra ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ díẹ̀ wà níbẹ - Labule

Bakan naa lo tẹsiwaju pe koda, ibalopọ na kii yọ awọn smọbinrin to jẹ akẹkọọ ere ori itage lọdọ Odunlade silẹ.

O fikun niṣe ni ikọọkan awọn ọmọbinrin ti Odun ba ti yan laayo bẹẹ ma n ri iyawo ile rẹ fin, ti wọn si ma n fi abuku kan.

Koda, o ni lọwọlọwọ, ọkan lara awọn akẹkọọbinrin rẹ to n jẹ Nike, lo wa loju ọpọn Odun bayii.

Ẹsun ti Gistlover fi kan Odunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Instagram/gistlovers_blog

Àkọlé àwòrán, Ẹsun ti Gistlover fi kan Odunlade Adekola

Amọ lẹyin ọjọ kẹta ti iroyin naa ti n ja kiri ori ayelujara, Odunlade Adekola ti fesi.

Eyi lo ṣe ninu fidio oniṣẹju mẹsan-an kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ ni ọsan Ọjọbọ pe oun nilo lati fesi si iroyin naa, nitori ọjọ iwaju.

Odunlade sọ pe kii ṣe eeyan bi t'oun ni yoo ma a ṣe iru nkan bẹẹ.

"Kii ṣe eeyan bi temi Odunlade Adekola, ọmọ Seriki Balogun, ni ma a ṣẹṣẹ ni ki ọmọ kan gbe idi wa ko to o di pe mo fun ni iṣẹ ṣe ninu fiimu mi."

O ni Ọlọrun lo n sọ eeyan di irawọ oṣere, kii ṣe eniyan.

"Gbogbo ẹyin ọmọbinrin ti ẹ ti gba ọdọ mi kọja gẹgẹ bi oṣere, ẹ bọ sita lati sọ boya lootọ ni mo n ba yion ni ibalopọ ki n to fi yin sinu fiimu mi.

"Ọlọrun ko ni i bo eyikeyi ninu yin to ba bo aṣiri mi."

Ọgbẹni Adekola to sọrọ pẹlu ibinu sọ pe lati bi ọdun mẹẹdọgbọn ni oun ti n ba iṣẹ oṣere bọ, ti oun ko si ni i gba ki akọroyin kankan ba orukọ oun jẹ tabi ba iṣẹ oun jẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

O ni oun kesi iru awọn oniroyin bẹẹ lati mu ẹri jade pe lootọ ni oun n fẹ Nike Hamzat lọwọlọwọ, to fi mọ awọn ọmọbinrin yooku ti wọn sọ pe oun ti ba ni ibalopọ ri.

O ṣalaye pe o ti to eeyan mẹẹdọgbọn to ti ara oun dide, ti wọn si ti di irawọ oṣere.

Ọrọ naa lo n sọ lọwọ ti iyawo rẹ naa fi dasi ọrọ naa pe irs ni pe Nike wa sinu ile wọn lati ba oun ja nitori pe o n fẹ ọkọ oun.

Odunlade sọ pe awọn akọroyin to gbe iru iroyin bẹẹ jade n gbiyanju lati ṣi awọn ololufẹ oun lọna, nitori okiki ara wọn.

To si tun fi epe ranṣẹ si awọn to n gbe iru iroyin naa sita.