Bobrisky ní òun gba Ọlọrun gbọ́ ju bí àwọn èèyan ṣe lérò lọ

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/ Instagram
Gbajumọ okunrin to maa n mura bii obinrin, Okuneye Idris Olanrewaju, ti ọpọ mọ si Bobrisky ti sọ pe ti oun ba fun obinrin loyun oun ko ni kọ oyun ọhun.
Bobrisky lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu gbajugbaja akọroyin to tun jẹ oniṣowo, Dele Momodu.
O ni kaka ki oun sẹ oyun naa, ni ṣe ni oun yoo ba obinrin naa ni ọrọ ajọsọ pe ki ọrọ ọhun má lu sita nitori irufẹ ipo ti oun wa lawujọ ati irufẹ oju ti awọn eeyan fi n wo oun gẹgẹ bii obinrin.
- Sunday Igboho ní ₦4m sí ₦3m ni ìkọ̀ọ̀kan amòfin mẹ́wàá ní Cotonou gbà láì dènà kí òun má lọ sẹ́wọ̀n
- Ìbálòpọ̀ àti nkán márùn-ùn míì tí o lè ṣé kí ará rẹ̀ fí jí pépé tó bá pé ogójì ọdún
- Buhari, dẹ́kun àwọn gómìnà tó ń ṣe òfin tako fífi ẹran jẹko- Miyetti Allah
- Níbo ni àìsàn aìmọ̀dí tó ń kọlù àwọn ọlọ́kadà àti 'mai-bola' ní ipinlẹ́ Ogun ti wọ́ wá?
Bobrisky sọ pe "Ohun gbogbo ni akoko wa fun, ti eeyan kan ba dede sọ pe oun loyun fun mi bayii, a oo jọ ni ọrọ ajọsọ pe awo ko gbọdọ ya ni.
Bobrisky ti wọn bi sinu idile ẹlẹsin Musulumi, to tun kọ keu sọ pe oun gbagbo ninu Ọlọrun gidi, oun si sunmọ Ọlọrun, lodi si nnkan ti ọpọ eeyan lero.
O ni "Emi gẹg̣ẹ bii ẹnikan, mo sunmọ Ẹlẹda mi gidi, ọpọ eeyan ni ko gbagbọ pe iru eeyan bi temi bayii le sunmọ Ọlọrun, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ."
"Ọlọrun to da wa gan sọ pe ki a maṣe ṣedajọ ẹnikẹni, bibeli sọ pe mi a ma ṣe da ẹnikẹni lẹjọ."

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222
"Igbagbọ temi ni pe eeyan ni lati wa aye lati maa sin Ọlọrun, boya eeyan gidi ni o tabi ẹni to ti yi lori, ohun to ṣe pataki ju ni p e ki eeyan ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Ọlọrun rẹ."
Bo tilẹ jẹ pe Bobrisky ti kọkọ kede ṣaaju pe oun ṣeṣẹ abẹ idi, ti irora naa sip ọ jọjọ, ṣugbọn o kọ lati sọrọ lori iṣẹ abẹ naa ninu ifọrọwerọ ọhun.
Ni ti pe boya o maa n ba okunrin ni ibalopọ, Bobrisky ni oun ti gba ọrọ naa oi nigba kan ri, ṣugbọn oun kii ba okunrin ni ibalopọ, bikoṣe obinrin nikan.
Bobrisky tun sọ siwaju si pe oun ko parada lati okunrin si obinrin, ṣugbọn oun kan maa n mura bii obinrin lasan ni.
Niti irufẹ oju ti awọn eeyan fi n wo Bobrisky lawujọ, o ni oun ko ri ara oun gẹgẹ bii apẹrẹ buburu fun iran to n bọ lẹyin.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222

















