Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adekunle Makama ti Kuta

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Ẹ jẹ́ kí Gómìnà kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ 'Restructuring' ni ìpínlẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ríró ìjọba ìbílẹ̀ lágbárá- Olowu ilẹ̀ Kuta

A mọ́ awọn Fulani Abalaye a dẹ tun mọ ti awọn to n gbe ibọn pe wọn yatọ sira wọn- Oba Kuta

Oba Ahmed Adekunle Makama ti Olowu Kuta sọrọ ilẹ kun lori oriṣi awọn Fulani to wa ni Naijiria bayii ati nkan to yẹ ki ijọba se fun koowa.

Bakan naa lo ni o yẹ ki ijọba pada si riro awọn ijọba ibilẹ lagbara ni ki alafia le jọba.

Oba Kuta

Oríṣun àwòrán, @Oba Kuta

Oba Kuta tun gba imọran pe ki atunto bẹrẹ lati ipinlẹ Gomina kọọkan.

O ni ile la ti n ko ẹṣo rode ni ọrọ Naijiria ba de bayii pẹlu ijiya to tọ si ẹnit o ba huwa aitọ.