McDonald's Burger ad: Obìnrin kan gbé McDonald's lọ ilé-ẹjọ́ torí ìpolówó Buger nínú àwẹ̀

Burger

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin ọmọ ilẹ Russia kan, Ksenia Ovchinnikova, ti gbe ile ounjẹ McDonald's lọ si ile ẹjọ lẹyin to sọ pe ipolowo cheeseburgers wọn ja oun laawẹ.

Ovchinnikova ṣalaye pe bi oun ti ri ipolowo burger yii ni oun pinnu lati ja awẹ oun lọdun 2019.

O ni asiko lẹnti yii gan an ni oun n gbiyanju lati jina si burger ati awọn ounjẹ mii lasiko awẹ ki oun to ri ipolowo burger yii to jẹ oju ni gbese.

Awọn ọmọ lẹyin Kristi ni Omsk to n tẹle kalẹnda Julian maa n yago fun ẹran jijẹ, ẹyin ati awọn nkan jijẹ mii ti wọn fi adiẹ ṣe lasiko lẹnti.

Ovchinnikova ni oun ko tii jẹ ẹran fun oṣu ki oun to ri ipolowo burger ti ile ounjẹ McDonald's gbe sita eleyii to mu ki oun ja awẹ ti oun n gba lọwọ ninu oṣu kẹrin ọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap

Ọmọbinrin Russia fẹsun kan McDonald's pe wọn tapa si ofin idaabo bo onibara ati ohun to tabuku ẹsin oun.

Ovchinnikova dẹbi ru McDonald's pe wọn ṣe ipolowo ọja ẹran lasiko tawọn ọmọlẹyin Kristi yago fun ẹran.

Nitori naa, o n beere fun owo dọla mẹrinla $14 gẹgẹ bi owo gba ma binu fun inira ti igbesẹ fa fun oun.

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

Lẹyin to ti gba awẹ fun ọdun mẹrindinlogun sẹyin, Ovchinnikova ko le mu mọ ra lati maa jẹ burger lẹyin to ri ipolowo McDonald's tan.

''Mo ti n gbaawẹ fun bi oṣu kan ki n to ri ipolowo ọja burger yii.

Ara mi ko gbaa mọ, mo ni lati lọ si ile ounjẹ ti ko jina si mi lati ra cheeseburger ni kiakia.

Mo si ti sọ fun ile ẹjọ lati ṣe iwadii rẹ lori ọrọ yii,'' Ovchinnikova ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde