World Breastfeeding week: "Ẹ yé fún àwọn ọkọ yín lọ́yàn mu mọ́, àwọn ọmọ ló lọyàn"

Oríṣun àwòrán, others
Kọmiṣọnna to n ri ọrọ ọkunrin ati obinrin nipinlẹ Enugu, Họnọrebu Peace Nnaji já gudugbẹ ọrọ lulẹ nigba to sọ pe kawọn obinrin ye fawọn ọkọ lọyan mu mọ.
Kọmiṣọnna ni awọn ọmọ lo ni ọyan kii ṣe baba wọn.
Kọmiṣọnna Nnaji sọrọ yii fawọn akọroyin nibi eto kan ti ajọ UNICEF to n ri sí ọrọ awọn ọmọde gbe kalẹ.
- BBC 100 Women 2019: ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ Afirika ń gbàràdá!
- Wo ilúbìnrin tí wọn ti ń ní ìbálòpọ̀, bímọ̀ láì ní ọkọ
- Gbogbo ìbéèrè tóo ní lọ́kàn nípa dída omira obìnrin lásìkò ìbálòpọ̀, ìdáhùn rèé
- Oríṣìí àrùn mẹ́jọ tó máa ń ṣáábà mú aláboyún rèé
- A kọ òfin gígé nǹkan ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin lòpọ̀ - Àwọn Alfa yarí
O ni ko t'ọna ki kawọn ọkunrin maa pin ọyan mu pẹlu awọn ọmọde nitori awọn ọmọ gan an ni Eledua jinki ọyan fun un.
Kọmiṣọnna Nnaji ni ko boju mu ki obinrin ma fun ọmọ lọyan daadaa tori ki ọmu maa ba dẹnu kọlẹ to ba ya.
Bakan naa ni kọmiṣọnna tun rọ àwọn obìnrin lati fún ọmọ wọn ni ọyan nikan ti wọn yoo fi pe ọmọ oṣu mẹfa.
Nnaji sọ pe anfaani to wa níbẹ ko lonka.










