PDP Crises: Secondus, Wike, BoT: A kò gbọdọ̀ tún ṣe àṣìṣe tí a fi kùnà ní 2015- PDP

Oríṣun àwòrán, Facebook/Peoples Democratic Party
Lẹyin ipade wakati mẹrin ti wọn ṣe nilu Abuja, igbimọ majeobajẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP ko ribi yanju aawọ to jẹ bi ipenija fun ẹgbẹ naa.
Ẹnu igbimọ yi ko ko lori boya ki alaga ẹgbẹ naa Uche Secondus ṣi wa lori oye tabi ko fi ipo silẹ gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ kọọkan ti ṣe n beere.
Ohun ti igbimọ naa sọ ni pe awọn yoo ṣe agbekalẹ igbimọ tuntun eleyi ti yoo joko lori ọna ati yanju gbogbo ọrọ to n fa gbọnmi si omi o to.
- Àríyànjiyàn Osinbajo àti PDP
- Bukola Saraki ṣe ìpàdé pẹ̀lú gómínà Seyi Makinde, Ayo Fayose lórí ọ̀rọ̀ adarí ẹgbẹ́ PDP
- Wike ti PDP ló borí ìdìbò sípò gómìnà Rivers
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń wa ẹnu lé ìyàwó ọmọ Ààrẹ Buhari torí àwọn aṣọ ìgbéyàwó rẹ̀ tó ṣí ara sílẹ̀
- Bí ènìyàn Ọ̀ọ́dúnrún ṣe fò ṣán'lẹ̀ kú rèé torí ààrùn onígbà méjì ní Kano ati Jigawa
- Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Osun bínú yabo iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìdigunjalẹ̀ tó gba ẹ̀mí eèyàn ní Iree
Wàhálà àti ìkùnsínú láàrin ọmọ ẹgbẹ́ PDP, kí ni ọ̀nà àbáyọ?
Ṣẹnẹtọ Walid Jibrin lo dari ipade naa eyi ti ko fẹnu ko boya ki wọn daba ijiya fawọn ọmọ ẹgbẹ to lọwọ ninu rukerudo to n damu ẹgbẹ ọhun.
Bi nkan ti ṣe ri bayi, ojutu ọrọ ko le ni iyanju ayafi ti ipade yi ba joko jiroro tan.
Sẹnẹtọ Bukola Saraki ati Sẹnẹtọ David Mark to ba awọn akọroyin sọrọ kọ lati sọ oju abẹ niko ṣugbọn wọn ni ipade tawọn ṣe so eso rere.
Nigba tawọn akọroyin beere lọwọ Bukola Saraki boya wọn yoo jẹ ki igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa pari saa wọn, o ni awọn yoo ṣe ipade laarin ọjọ meji si mẹta la ti le mọ ibi ti ọrọ n lọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/bukola.saraki
Wike vs Secondus nibo lọrọ de
Fakinfa laarin alaga ẹgbẹ PDP Uche Secondus ati Gomina Nyesom Wike wa lara nkan tawọn eeyan kan tọka si pe o n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ.
Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí aáwọ̀ tó fẹ́ dojú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bolẹ̀?
Bo tilẹ jẹ wi pe awọn mejeeji ko jade lati sọ pe ede aiyede wa, pupọ lo gbagbọ pe Gomina Wike ko dunnu si iṣakoso Secondus to si n pete pero lati yọ kuro lori oye.
Oṣu mẹta si mẹrin lo ku ti saa Secondus yoo fi pari ki awọn ọmọ ẹgbẹ to yan alaga mi.

Oríṣun àwòrán, Facebook/riversgovernmenthouse
Iṣẹlẹ ikọwefiposilẹ awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya meje ninu ẹgbẹ naa tubọ mu ki awọn eeyan sọ pe o ṣeese ki wọn yẹ aga nidi Secondus nibi ipade awọn majeobajẹ ẹgbẹ.
Amọ bi nkan ti ṣe ri yi, o ṣeeṣe ki wọn ri ọna naa yanju ti igbimọ majeobaje ba tun ṣe ipade lori ọrọ itẹsiwaju ẹgbẹ
A ko gbọdọ tẹri si aṣiṣe atẹyinwa
Ki ṣe akọkọ ree ti wahala yoo de ba ẹgbẹ oṣelu PDP.
Lọpọ igba ti ọdun idibo ba ti n sunmọ, orisirisi wahala lo maa n bẹ silẹ eyi to maa n ṣokunfa ki wọn yọ alaga ẹgbẹ naa.
Ninu ọrọ rẹ sawọn ọmọ ẹgbẹ,alaga igbimọ majeobajẹ ẹgbẹ Senatọ Walid Jibrin kesi awọn agbaagba ẹgbẹ lati woye nipa wahala to yọ awọn alaga ẹgbẹ to ṣaaju.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Facebook/riversgovernmenthouse
O ni bayi tawọn ọmọ Naijiria n foju wo PDP gẹgẹ bi ẹgbẹ ti yoo gba awọn ọmọ Naijiria silẹ, ko tọ ki wọn tun wa sa ara wọn sinu wahala ija ti ko nidi.
''Ki a baa le ṣe ẹkunrẹrẹ aseyọri a ni lati jawọ nibi gbogbo ija ti ko nidi laarin ara wa ki a ba ma ṣe ṣakoba fun adisọkan ẹgbẹ wa''
Ninu awọn alaga ẹgbẹ ana ti ko pari saa wọn labẹ ẹgbẹ PDP ni a ti ri
-Chief Audu Ogbeh
-Okwesilieze Nwodo
-Bamanga Tukur
-Ahmed Muazu ati
-Ali Modu Sheriff
















