Messi leaves Barca: Ìpínyà wáyé láàrin Lionel Messi àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Barcelona lẹyìn ọdún méje

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awo Lionel Messi ti o ti fi odidi ọdun meje wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ti pada wa lọ bayi.

Bẹẹ ni. Ikede ipinya laarin Messi jẹ eleyi to ya ọpọ ololufẹ ere bọọlu lẹnu paapa nitori bi o ti ṣe waye.

Lọjọbọ ni ẹgbẹ agbabọọlu naa fi ikede yi sita pe lẹyin agbeyẹwọ awọn ti pada wa ri pe Messi ko ni le duro pẹlu awọn mọ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita ṣe wi, ipinya yi ko ṣẹyin bi awọn ko ti ṣe le ri owo to n beere tawn jijọ fẹnu ko san nitori ọrọ aje awọn to dẹnu kọlẹ.

Wọn fi kun pe o fọwọ kan awọn lẹmi ṣugbọn awọn dupẹ lọwọ Messi fun iṣẹ takuntakun ati ibaṣepọ to wa laarin awọn.

Kete ti ọrọ yi jade niṣe ni awọn onwoye ati ololufẹ ere bọọlu gba oju ayelujara ti orukọ Messi ati Barcelona si di nkan tawọn eeyan n ran lẹnu.

Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo ti lẹ jẹ pe ikede yi ba awọn eeyan kan lojiji paapa nitori pe Messi ati ẹgbẹ Barcelona jijọ ti fẹnuko lori iye owo ti yoo gba awọn ti ọrọ ye ni ko si igba ti ma ku ko ni pada ku.

Amọ Bayi ti Messi ko lokun lọrun mọ, ibeere tawọn eeyan n beere ni pe nibo ni ogbontarigi agbagbọọlu yi yoo lọ bayi?

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Ko si idiwọ mọ

Lọdun to kọja ni Lionel Messi sọ fun Barca pe oun fẹ kuro lẹgbẹ naa laisan owo kankan ṣugbọn Barca fariga pe a fi ko san ẹẹdẹgbẹrin miliọnu dọla,

Bayi ti ipinya de, ko si ohun to jọ bẹ mọ.

Lara awọn ibi tawọn eeyan n foju si pe o le lọ ni Man City nibi ti akọnimọọgba tẹlẹ rẹ ni Barca, Pep Guardiola ti n dari nkan.

Lionel Messi ati Pep Guardiola

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Paris St Germain naa wa lara awọn ibi to ṣeeṣe ko lọ nitori ẹgbẹ yi ni owo ti wọn le san.

Koda wọn ti sọ nigba kan ri pe ti Barca ba nifẹ si, awọn ni owo nilẹ lati ra Messi lọwọ wọn.

Awọn ibomiran ti Messi le lọ ni Bayern Munich, Chelsea, Inter Milan, Juventus ati Newell's Old Boys ni Argentina.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...