Ọ̀rọ̀ kò wọ̀ mọ́, Messi kò ní kúrò ní ẹgbẹ́ Barcelona

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilumọọka agbabọọlu, Lionel Messi ti sọ pe oun ko ni kuro lẹgbẹ agbabọọlu Barcelona mọ.

Iroyin yi tawọn eeyan ti n reti paapa awọn alatilẹyin Barcelona jẹyọ lẹyin ti ipade fori sanpọn laarin Messi ati Barcelona lori iye ti wọn fẹ ki awọn ti yoo ra san.

Messi ni ko si ẹgbẹ agbabọọlu kankan ti yoo san owo ti o wa ninuiwe adehun ohun nitori naa oun ko ni kuro ni Barcelona.

Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ọmọ orilẹede Argentina naa fi iwe ranṣẹ si ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lọjọ Iṣẹgun ọsẹ pe oun ṣi fẹ wa lọdọ wọn.

Eyi wa ni ibamu pẹlu iwe adehun eyi ti o faye gba a lati kuro nigba to ba wu uṢugbọn ẹgbẹ naa sọ pe ẹgbẹ to ba fẹ ra a gbudọ le san iye owo 700m (£624m).Airi owo yi san ni ko ni jẹ ki Messi lọ ibi kankan.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

"Mo ti ro pe to si da mi loju pe mo lee kuro nigbakuugba, Messi sọ fun ileeṣẹ iroyin Goal.''

O fi kun un pe "aarẹ maa n sọ ni gbogbo igba pe bi saa bọọlu yii ba ti pari, mo lee pinu boya mo fẹ duro tabi kuro.''