Oshogbo Heavy Rainfall: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá àìmoye mílíọ̀nú naira ṣòfò nínú ìjàmbá omíyale
Okere tan, oku eeyan mẹta lawọn aradugbo ti ri lẹyin ijamba omiyale agbara ya ṣoobu to waye ni Ipinlẹ Osun lỌjọru.

Oríṣun àwòrán, Jibola Oyekunle
Wakati mẹrin gbako ni ojo yi fi rọ tawọn adugbo kọọkan ni Osogbo ati Erin Osun si farakasa ojo arọrọda yi.
Ọpọ dukia lo ba iṣẹlẹ naa lọ eyi taa gbọ pe o bẹrẹ si ni rọ lati oru ọjọ Iṣẹgun ti ko si da titi di owurọ kutu Ọjọru.
Ni adugbo Oke Ijetu ati Oke Oniti, wọn ri oku eeyan meji ti awọn ile kọọkan naa si faragba omiyale yi.

Ṣoobu itaja ni Rasco, Obate, Atimowa, Testing Ground, Awosuru, Oke Ayepe ati ni Ita Olokan naa ko moribọ ninu ijamba yi.
- "DSS, ẹ mú ẹ̀rí jáde pé ilé Igboho lẹ ti rí àwọn ìbọn tẹ́ fi hàn"
- Afẹnifẹre kan sárá sí ẹka ètò ìdájọ Nàìjíríà lórí ìdájọ àwọn ti wọ́n kó nílé Sunday Igboho
- Ènìyàn 747 míràn ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì ààrùn Covid-19 ní Nàìjíria
- Ilé ẹjọ́ fún Sunday Igboho ní ànfààní láti rìn ní òmìnira láàrin ìlú
- Ẹ fún wa ní oṣù márùn ún láti fí lé àwọn ajínigbé Fulani kúrò nínú igbó- Olórí Fulani
- Kí ló mú kí géńdé múra bí obìnrin láti bá ọ̀rẹ́bìrin rẹ̀ kọ ìdánwò?
Ara aradugbo Oke Ayepe kan to ba iwe iroyin Naijiria Punch sọrọ ṣalaye pe o ṣoju oun nigba ti wọn gbe oku arabinrin kan sọkalẹ lori igi to ha si.

Oríṣun àwòrán, Facebook/honlekan.badmus.1
O ni awọn musulumi to fẹ ki irun ayila lo ri oku naa loju agbara odo Okooko nibi to ha si aarin igi ọpẹ meji.

Oríṣun àwòrán, Facebook/honlekan.badmus.1
Gomina Oyetola ba araalu kẹdun
Adugbo Alie nijọba ibilẹ Olorunda ni Gomina Adegboyega Oyetola ti duro ba awọn aradugbo kẹdun lori iṣẹlẹ omiyale.

Oríṣun àwòrán, Jibola Oyekunle
Lasiko to n kaakiri lati ri bi ojo ṣe ba nkan jẹ. o ni o ṣe pataki ki awọn araalu maa tẹle ilana itọju ayika ẹni paapa eyi to ni ṣe pẹlu oju agbara.
''Pẹlu nkan taa ri, o fi han pe oju agbara to di latari bi awọn eeyan ṣe n da panti soju agbara lo da wahala silẹ.Ni ọpọ ibi, niṣe lawọn eeyan gbegi dina oju agbara''
- Wo àwọn oúnjẹ́ tí yóò mú kí omi ọmú pọ̀ si fún ìyálọ́mọ́
- Ìwádìí ní gómìná New York fipá k'ẹnu ìfẹ́ sáwọn obìnrin, Biden rọ̀ ọ́ pé kó fipò sílé
- UAE yí ìpinnu padà,ìrìnàjò bàálù bẹ̀rẹ̀ padà láàrin Nàìjíríà àti Dubai
- Ilé ẹjọ́ fún Sunday Igboho ní ànfààní láti rìn ní òmìnira láàrin ìlú
- Ẹbí Rachael Oniga kéde ètò ìsìnkú òṣèré tó d'olóògbé















