Ìwádìí ní gómìná New York fipá k'ẹnu ìfẹ́ sáwọn obìnrin, Biden rọ̀ ọ́ pé kó fipò sílé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eleyii ko ṣẹyin bi abọ iwadii kan ti fihan pe Ọgbẹni Cuomo ti fi ipa dọwẹkẹ ifẹ sawọn obinrin kan.
Biden sọrọ yii lẹyin ti agbẹjọro agba, Letitia James sọ pe Cuomo ti tapa si ofin ipinlẹ ati ti ijọba apapọ pẹlu.
Ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Cuomo ni oun ko fọwọ kan ẹnikẹni lọna aitọ ri.
Cuomo ni mimi kan ko le mi oun lori aleefa ipo gomina ti oun wa nitori oun ko jẹ gbi, oun ko si ni b'awọn ku gbi.
O ṣeeṣe ki wọn yọ Cuomo nipo, bakan naa ni o tun jẹjọ lori ẹsun iwa ọdaran mii.
"Ero mi ni pe o yẹ ki Cuomo kọwe fipo silẹ.
Mo gbọ pé ile igbimọ aṣofin le yọ ọ nipo.
Mi ko tii lanfaani lati ka alaye lori ẹsun ti wọn kan Cuomo," Biden lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, @Brook
Lọdun to lọ ni iwadii bẹrẹ lori ọrọ Ọgbẹni Cuomo lẹyin tawọn obinrin kan fi oríṣìíríṣìí ẹsun kan an.
Igbimọ ọhún ba awọn obinrin to to igba sọrọ to fi mọ awọn oṣiṣẹ rẹ, bakan naa ni wọn ṣe ayẹwo ẹgbẹẹgbẹrun akọsilẹ.
"Ọgbẹni Cuomo fi ọwọ ra ọrun ẹnikan.
Oun ati oṣiṣẹ rẹ kan tun gbẹsan lára oṣiṣẹ rẹ tẹlẹ rí nitori o fẹsun kan an.
- Báwo ni Joe Biden yóò ṣe mú ìyípadà bá òfin tí Trump fi de orílẹ̀èdè àgbáyé?
- Kí ní Desmond Elliot ṣe fáwọn ọ̀dọ́ tí orúkọ rẹ̀ kò wọ́n lori ayelujara?
- Wo awọn ‘Apps’ to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn àdúgbò tó ta lẹ́nu jùlọ nílùú Ibadan
- Kí ló ṣe ọkùnrin yìí tó dédé ń sá lọ láàrin ìgboro ní ìhòhò ọmọlúàbí?
Awọn obinrin mii sọ pe Cuomo fi ipa dẹnu ko awọn lẹnu, nigba t'awọn kan ni gomina ni k'awọn joko sori itan oun.
Amugbalẹgbẹ Cuomo ni gomina New York ki ọwọ bọ aṣọ oun lati le tẹ oun lọyan.
O tun beere fun Ibalopọ lọwọ amugbalẹgbẹ rẹ ọhún," agbẹjọro agba lo ṣalaye bayii.
Àmọ́, Cuomo duro lori ẹsẹ rẹ, o ni oun ti pe ọgọta le mẹta ọdún laye.
Igbe aye ilumọọka si ni oun ti gbe nigbogbo ayé òun.
Cuomo ni oun kọ ni wọn n sọ nípa rẹ.
- Wo àwọn oúnjẹ́ tí yóò mú kí omi ọmú pọ̀ si fún ìyálọ́mọ́
- Ilé ẹjọ́ fún Sunday Igboho ní ànfààní láti rìn ní òmìnira láàrin ìlú
- Ṣàǹgbá fọ́! Ìrètí Nàìjíríà fún góòlú, Adekuroye pòfo nínú ìjànkadì ní Tokyo 2020
- Kí ló mú kí géńdé múra bí obìnrin láti bá ọ̀rẹ́bìrin rẹ̀ kọ ìdánwò?
- Ẹ fún wa ní oṣù márùn ún láti fí lé àwọn ajínigbé Fulani kúrò nínú igbó- Olórí Fulani
- Olórí ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ PDP sọ àbùkù ọ̀rọ̀ sí Ààrẹ Buhari àti SGF, ẹ̀wọ̀n jàntò ló rí he!















