Desmond Elliot: Ìgbà kẹta rèé lọ́sẹ̀ kan táwọn ọ̀dọ́ yóò mú orúkọ rẹ̀ bọnu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/DESMOND ELLIOT
Desmond Olusola Elliot jẹ gbajumọ osere tiata lede oyinbo, to si ni orukọ ati oriki lorilẹede Naijiria.
Elliot, tii se ọmọ ile igbimọ asofin nipinlẹ Eko lọwọlọwọ bayii ni orukọ rẹ kii wọn lẹnu awọn ọdọ orilẹede Naijiria loorekoore.
Desmond Elliot lo n ṣoju ẹkun agbegbe Surulere ni Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òṣèré tíátà figbe ta torí ìhàlẹ̀ ikú àwọn Eléégún láàrin ọjọ́ méje
- Ikú tó fẹ́ pa Opeyemi Ayeola ṣí i ní fìlà, ló bá ń kọrin ẹ fọ̀rọ̀ mi kọ́gbọ́n
- Nǹkan pàtàkì mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Salawa Abeni bí ó ṣe pé ọgọ́ta ọdún.
- Ayé ń pè wá ní 'Yeyebrity' torí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, nǹkan bà wá lágbo tíátà Yoruba"
- Wo àwọn olówó ayé tí ìgbéyàwó wọn ti wó lulẹ̀
- Ìyá àláwo tó di àjíhìnrere òjijì fi àwọn òrìṣà rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà
- Eré orí ìtàgé kọ́ ni pé Baba Ijesha ń tẹ ọmọ lára, ẹ yé gbè sẹ́yìn mi lọ́nà àìtọ́ - Yomi Fabiyi
Lọwọ lọwọ bayii, orukọ Desmond Elliot ni awọn ọdọ Naijiria tun mu bọnu loju opo ibanidọrẹ Twitter, ninu ọsẹ yii nikan, igba kẹta ree ti orukọ rẹ n ja rain bii iji.
Eyi si maa n waye ti awọn ọdọ ba n jiroro lori ipo aida ti orilẹede naijiria wa ati bi nkan ko se rọgbọ lorilẹede yii.
Ni oṣu to kọja ni Desmond Elliot ki awọn eniyan ku oṣu Ramadan pẹlu ibeere pe, ki ni oun tun ṣe fun awọn eniyan bayii, ti wọn fi n pariwo orukọ oun.
Ohun to ya ni lẹnu ni pe, ọpọlọpọ ohun ti wọn n pe orukọ Elliot si, ni ko mọ nkankan nipa rẹ.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/DESMOD ELLIOT
Ọpọlọpọ aroko bii Desmond Elliot jẹbi eleyii '' 'I blame Blame Desmond Elliot for this' , 'Na Desmond Elliot cause am' ni wọn ma n kọ lati tabuku rẹ lori ẹrọ ayelujara.
Ni oṣu to kọja ni Desmond Elliot ni ki awọn eniyan ku oṣu Ramadan pẹlu ibeere pe, ki ni oun tun ṣe fun awọn eniyan bayii ti wọn fi n pariwo orukọ oun.
Ki ni Desmond Elliot gbe ni igba ọdọ Naijiria, ti orukọ rẹ kii fi wọn lẹnu wọn?
Ko han si wa yekeyeke igba ti awọn eniyan bẹrẹ si ni da ẹbi ru Desmond Elliot lori ayelujara, amọ igba ifẹhọnuhan Endsars to sọrọ ti ko tẹ awọn ọdọ lọrun ni wahala ti bẹrẹ fun ni oju opo ikansiraẹni Twitter.
Desmond Elliot nigba naa ni awọn ọdọ ko ṣe daradara lori ifẹhọnuhan Endsars pẹlu bi wọn ṣe ba awọn dukia ijọba ati ti awọn eniyan jẹ, to si pe wọn ni ọmọde.
Ọrọ naa ko bọ si ibi ire ni ara wọn, ti wọn si bẹrẹ si ni sọ oko ọrọ si lori ẹrọ ayelujara.
Lẹyin naa ni Elliot tọrọ aforiji ni ọwọ awọn ọdọ Naijiria wipe ki wọn dariji oun, amọ aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ, ọmọyẹ ti rin ihoho lọ ọja.


















