Bill and Melinda Gates: Wo àwọn olówó ayé tí ìgbéyàwó wọn ti wó lulẹ̀

Ẹbi Bill Gates ati Jeff Becos tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Owo ṣe pataki, o sẹ koko ni igbesi aye ọmọ eeyan.

Koda, ọpọ gbagbọ pe owo wa lara nnkan ti ọkunrin fi n ṣe ọkọ obinrin.

Iwe mimọ bibeli tiẹ sọ pe ''owo ni kẹkẹ ihinrere'' ati pe ''owo ni idahun si ohun gbogbo.

Awọn kan tiẹ gbagbọ pe, obinrin ko le fi ọkọ rẹ silẹ ti Eleduwa ba fi owo jinki ọkunrin naa.

Ṣugbọn ọrọ kii ṣaaba rii bẹẹ nigba mi, ọkan lara apẹẹrẹ iru rẹ ni ọlọrọ kan to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, Bill Gates to wa ni ipo kinni ninu awọn to lọrọ julọ lagbaaye fun ọpọ ọdun.

Wọnyii ni awọn ọlọrọ ti wọn ti kọ iyawo silẹ ti aye gbọ.

1. Bill Gates

Bill ati Melinda

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Aje, ọjọ kẹta oṣu karun ọdun 2021 ni Gates kede pe irinajo ọdun mẹtadinlọgbọn laarin oun ati iyawo oun, Melinda ti para.

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan nigba ti kede oun ati Melinda ko ni jọ maa ṣe pọ gẹgẹ bi ọkọ ati aya mọ.

Ọrọ ipinya Gates ati Melinda wa lara ọrọ tawọn eeyan n sọ julọ lori ayelujara.

Ọmọ mẹta ni Gates ati Melinda bi fun ara wọn nigba ti wọn jọ gbe gẹgẹ bi ọkọ ati aya.

Gates ni ọrọ to le ni biliọnu lọna ọgọfa $ 124bn (£ 89bn), oun si ni oludasilẹ ileeṣẹ kọmputa Microsoft.

2 . Jeff Bezos

Jeff Bezos ati Mackenzie lọdun 2017

Oríṣun àwòrán, Mackenzie Scott pictured with her ex-husband Jeff

Oludasilẹ ileeṣẹ Amazon, Jeff Bezos naa kede ipinya oun ati iyawo rẹ, Mackenzie lọdun 2019.

Ọdun mẹẹdogbọn ni awọn mejeeji fi jọ gbe gẹgẹ bi ọkọ ati aya ki wọn to pinya,

Bezos ti ọrọ rẹ to $136.2bn lo wa ni ipo kinni ninu awọn to lọrọ julọ lagbaaye.

Bezos to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgọta naa lo ni Washington Post ati Blue Origin.

3 . Alec Wildenstein

Ọkan lara awọn to lọrọ julọ lagbaaye, Alec Wildenstein ti kọ iyawo tiẹ, Jocelyn Wildensteina silẹ lati ọdun 1999.

Wildenstein to jẹ ọmọ orilẹede France n gbe ni orilẹede Amerika.

Ọdun mọkanlelogun loun ati iyawo rẹ fi gbe papọ ki wọn to pinya.

Ipinya oun ati iyawo rẹ jẹ ki iyawo rẹ gba owo gba mabinu ọgọrun miliọnu naira fun ọdun mẹtala.

4 . Bill Gross

Bill da Sue Gross

Oríṣun àwòrán, Ann Chatillon

Ọkan lara ipinya awọn ọlọrọ lagbaaye to ya awọn eeyan lẹnu julọ ni ipinya laarin Bill ati Sue Gross.

Ọgbẹni Gross ni oludari ileeṣẹ Pimco eyi to o si tun ti jẹ ọkan lara awọn to dokoowo si ileeṣẹ naa.

Ọdun 2016 ati 2017 ni arabinrin Sue pe fun ikọsilẹ ọkọ rẹ.

Owo rọgurọgu ni Sue tẹwọ gba to fi mọ ile nla ni Laguna to to miliọnu mẹrindinlogoji.

Bill ja kuro ninu ẹgbẹ awọn ọlọrọ julọ laye lọdun 2018 lẹyin to ti wa lara awọn ọlọrọ naa fun ọdọ mẹrinla.

5. Rupert Murdoch

Rupert Murdoch

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Rupert Murdoch

Ọlọrọ Rupert Murdoch ati iyawo Anna Torv kọ iyawo rẹ silẹ lẹyin ti wọn ti jọ wa papọ fun ọdun mọkanlelọgbọn gẹgẹ bi lọkọ laya.

Ọmọ mẹta lo wa laarin Murdoch ati iyawo Anna lasiko ti wọn fi jẹ ọkọ ati iyawo.

Ọdun 1999 lawọn mejeeji fi ọbẹ ge okun to so awọn mejeeji pọ gẹgẹ bi lọkọ laya.

Iroyin kan tiẹ sọ pe Anna Torv gba owo to din diẹ ni biliọnu meji owo dọla($ 1.7bn).

6. Elon Musk

Elon Musk atiTalulah Riley

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọlọrọ to ni ileeṣẹ Tesla ati SpaceX, Elon Musk kọ iyawo rẹ, Justine Musk silẹ lọdun 2008.

Iroyin sọ pe ile ẹjọ ti bawọnb mejeeji pin ohun ini wọn.

Ọmọ marun lo wa laarin awọn mejeeji nigba ti wọn fi fẹ ara wọn.

Elon ṣe igbeyawo pẹlu obinrin miran, Talulah Riley lọdun 2010, tii ṣe ọdun meji lẹyin to pinya tan pẹlu Justine.

Ìdí rèé tí ìgbéyàwó ọdún 27 tú ká láàárín Bill àti Melinda Gates

Lana ode yii ni Bill ati Melinda Gate kede pe awọn ti fadagba eto igbeyawo ọdun mẹtadinlogun rọ pẹlu akọle pe "a o lero pe a le jọ dagba mọ gẹgẹ bi tọkọtaya mọ."

"Lẹyin ọpọlọpọ arojinlẹ ati ọpọlọpọ isẹ ti a ti ṣe ninu ibasepọ wa, a ti pinu lati fi opin si igbeyawo wa," bayii ni awọn mejeeji se kọ soju opo Twitter wọn.

Ọdun 1980 ni wọn kọkọ pade nigba ti Melinda wọ isẹ nile iṣẹ Microsoft ti Bill jẹ oludasilẹ rẹ.

Awọn olusowo olowo yii bi ọmọ mẹta ti wọn si jumọ sowọpọ lati maa tukọ ile iṣẹ wọn ti wọn pe ni Bill & Melinda Gates Foundation.

Ile ișẹ naa ti na obitibiti owo lati gbogun ti ajakalẹ aarun ati lati gba orileede niyanju lori abẹrẹ ajẹsara to fun awọn ọmọ wẹwẹ.

Awọn Gates pẹlu ọkan ninu awọn oludokoowo wọn Warren Buffett lo wa lẹyin ẹjẹ ififunni, eyi to n ke si awọn ọlọrọ lati maa fi eyi to pọ ninu ọrọ wọn fun iṣẹ rere ati awọn alaini.

Bill Gates ni ẹnikẹrin to ni owo julọ lagbaye gẹgẹ bi iwe iroyin Forbes se sọ, o si ni owo to to biliọnu mẹrinlelọgọfa dọla (£89bn)

O ri owo rẹ lati ara ile iṣẹ to jumọ da silẹ ni ọdun 1970, Microsoft to jẹ ile iṣẹ to tobi julọ fun eroja nnkan elo kọmputa.

Awọn tọkọtaya yii jumọ se ikede ikọsilẹ wọn loju opo Twitter ni.

"Laarin ọdun metadinlọgbọn wa, a tọ omo mẹta bakan naa ni a mu idagbasoke ba isẹ eleyinju aanu wa ti o si ṣíṣẹ ni gbogbo orileede agbaye, lati mu ki awọn eniyan gbe igbeaye ilera, ati aye to ni itumọ," bi atẹjade wọn ṣe sọ.

" Titi di asiko yii iwoye wa lori iṣẹ isin n tẹsiwaju, a o jọ maa ṣe iṣẹ wa lọ sugbọn a nigbagbọ pe a le jọ dagbapọ mọ gegebi lọkọlaya ni ipele to ku ninu aye wa yii.

"A tọrọ fun aaye to gbooro fun ebi wa, bi a o se maa tẹsiwaju ninu irinajo aye wa tuntun."

Àkọlé fídíò, Tóò bá fẹ́ràn àti máa pọ́n ọ̀rọ̀ tàbí èèyàn lé, ẹ̀kọ́ ráńpẹ́ yìí yóò wúlò fún ọ

Bawo ni wọn ṣe pade Gan?

Minda ẹni ọdun mẹrindinlọgọta bayii darapọ mọ ile iṣẹ Microsoft gẹgẹ bi alakoso awọn ọja tuntun nile isẹ náà lọdun 1987 awọn mejeeji joko pọ nibi wẹjẹ-wẹmu to niṣe pẹlu eto ọrọ aje wọn ni New York ni lọdun naa.

Wọn bẹrẹ si ni fẹ ara wọn, sugbọn gẹgẹ bi alaye6ti Bill ṣe fun Netflix ẹ̀ka itan sísọ. "a maa n biita pupọ fun awọn eniyan a si maa n sọ nkan mejini o le ṣẹlẹ, yala ki a tuka tabi ki a ṣe igbeyawo."

Melinda ni oun ṣe awari Bill, nipa ilana eniyan, ni ki a maa "kọ nkan ti a ńṣe ati eyi ti a ko gbọdọ ṣe soju patako, eyi to niṣe pẹlu ọkan nipa igbeyawo."

Wọn ṣe igbeyawo lọdun 1994, ni Hawaiian Island ni Lanai iroyin sọpe gbogbo ọkọ ofurufu agbegbe naa ni wọn gba lati ri daju pe ko si awọn alejo ti wọn ko fi iwe pe maa fo kọja laaiko naa.

Ọdun to kọja ni Bill ẹni ọdun marunlelọgọta fi ipo silẹ ninu igbimọ alaṣẹ Microsoft to si gbaju mọ isẹ ẹlẹyinju aanu to yan laayo.

Awon lọkọlaya naa ti pinya lasiko ajakalẹ aarun Covid-19

Kini Gates Foundation?

Ọdun 2000 ni awọn lọkọlaya naa ṣe idasilẹ Bill & Melinda Gates ni Seattle.

Nkan ti wọn saba maa n moju to ju ni eto ilera ara ilu, eto ẹkọ ati ọrọ ayika to n yi pada.

Owo iranwọ ti wọn ti na to 1.7biliọn dọla fun iṣẹ iwadii lati ipese abẹrẹ ajẹsara lasiko ajakalẹ aarun Covid19.

Lodun 2019, ajọ eleyinju aanu Bill & Melinda Gates ni idokoowo to le ni biliọnu metalelogoji, lẹtin eyi ni awọn mejeeji tun ko biliọnu mẹrindilogoji si laarin 1994 ati 2018 gẹgẹ bi akọsilẹ Reuter News Agency.

"Dede ni ipo emi ati Bill" gẹgẹ bi o se sọ fun Associated Press (AP) ninu ifọrọwanilẹnuwo ti se lọdun 2019." "Ọkunrin ati Obinrin yẹ jẹ deede lẹnu iṣẹ."

Ninu akọsilẹ ti o ṣe laipẹ to pe akọle rẹ ni The Moment of Lift, lo ti salaye nipa asiko rẹ gẹgẹ omode, awọn ippenija rẹ ni idakọnkọ, bi o ṣe jẹ iyawo bọrọkini ènìyàn lawujọ ati bi o ṣe jẹ obinrin to n joko sile lati tọju ọmọ mẹta.

O ni bi awọn ṣe jọ n ṣe iṣẹ pọ ran ibasepọ awọn lọwọ pupọ. O ni awọn ọkunrin gbọdọ kọ bi a se n ba obinrin dọgba. Bakan naa ni ko ti kọ bi a ṣe n mura giri lati de ipo ti ọkunrin wa

Yatọ si iṣẹ rẹ gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu, o se agbekalẹ oko-owo to moju to awọn obinrin ati ẹbi wọnl lọdun 2015.

"Aye ti n ji giri si ootọ pe ko si ẹni ti o le tẹ siwaju ti apa kan rẹ ba wa lẹyin" o sọ ni asiko naa. "Akọsilẹ ti fi han pe ti a ba rọkun sapa obinrin, wọn yoo mu ayipada ba awujọ".