Iniobong Umoren story: Ìjọba Akwa Ibom pè fún ìdájọ́ òdodo lórí ìwádìí ikú ọ̀dọ̀bìnrin tó dàwátì tórí ó ń wá iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ijọba ipinlẹ Akwa Ibom ti fi aidunnu wọn han lori iroyin iku Iniobong Umoren to ku lẹyin ti afurasi kan, Uduak Frank Akpan jii gbe to fi ipa baa lo ko to tun gbẹmi rẹ.
Gomina ipinlẹ Akwa Ibom to dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa fun fifi panpẹ ofin mu arakunrin naa ṣalaye pe ijọba ti kan sawọn ọlọpaa ni ipinlẹ ọhun lati rii daju pe afurasi naa foju wina ofin bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.
O ni ijọba ipinlẹ Akwa Ibom ba awọn ẹbi oloogbe naa kẹdun ọmọ wọn to ku to si fi kun un pe ohun ti ijọba n lepa ni ipinlẹ naa ni alaafia ati abo fun tonile talejo to n gbe nibẹ.
Ọrọ ti ijọba ipinlẹ naa sọ yii n waye lẹyin ti awọn ọlọpaa ti kọkọ kede pe ọwọ awọn ti tẹ Uduak Frank Akpan, ọmọ ogun ọdun kan ti wọn fura si pe oun lo ji Iniobong gbe, to fipa baa lo pọ to si tun pa a.
Báyìí ni Ọlọ́pàá ṣe mú ayédèrú agbanisíṣẹ́ tó fipá bá Iniobong tó ń wá iṣẹ́ lòpọ̀ tó tún pa á

Oríṣun àwòrán, Twitter/Happiness Activist
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti fi panpẹ ofin mu afurasi ayederu agbanisiṣẹ kan to fipa ba arabinrin to n wa iṣẹ lo pọ to tun pa a ni agbegbe Airport Road, ilu Uyo.
Iroyin to gbode kan ni pe Umoren n wa iṣẹ lori ayelujara ni l'Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni Akpan ba fi ọgbọn fi iṣẹ ayederu kan lọ ọ to si fun un ni adirẹsi ọfiisi rẹ.
Ẹwẹ, ko pẹ to fi ọrọ ori foonu ranṣẹ si ọrẹ rẹ Umoh Uduak pe oun n lọ fun ifọrọwanilẹnuwo ni adirẹsi ti wọn fi ranṣẹ ni foonu rẹ ko lọ mọ.
Ni Uduak ba figbe ta lorii Twitter, o ni oun ngbọ ti ọrẹ oun n kigbe ninu ọrọ ori foonu oniṣẹju aaya kan pere to fi ranṣẹ si oun to si ni pabo ni igbiyanju oun lati ri i ba sọrọ n ja si.
Igba naa lo bẹrẹ #FindHinnyHumoren lori ayelujara ti wọn si fi oju Akpan ati adirẹsi rẹ hande.
Pẹlu Hashtag ti wn n pin lori ayelujara ni wọn fi ṣawari ibi ti o n gbe. Kete to mọ pe wọn ti n wa oun ni iroyin sọ pe afurasi ọhun ti na papa bora.
Bakan naa, iroyin ni wn bo oku arabinrin naa mọlẹ labẹ iho ti ko jin rara lẹyin ti wọn fẹsun kan pe akpan fipa ba a lopọ to tun pa a.
Ileeṣẹ Ọlọpaa wa fesi loju opo Twitter tiwọn @PoliceNG ti wọn ni ọwọ ti t afurasi meji lori ọrọ naa.
Wọn ni "ikọ ọlọpaa Akwa Ibom to n gbogun ti iwa ijinigbe ti kara bọ iwadii. Ọwọ ti tẹ eeyan meji, a o si maa fun yin ni ẹkunrẹrẹ iroyin bo ba ṣe n yọju.
Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ naa, Odiko Macdon lo fihan ninu ọrọ rẹ pe afurasi naa jẹwọ pe oun fipa ba a lo pọ oun si pa a.
Atjade ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ka bayii pe: Ileeṣẹ Ọlọpaa Akwa Ibom ti mu Ọgbẹni Uduak Frank Akpan ẹni ogun ọdun fun ẹsun ijinigbe ati ipaniyan to ṣe si Arabinrin Iniobong Umoren.
Bí Àwọn ọlọ́pàá tí wú òkú Iniobong Umoren tó dàwátì lọ́jọ́ díẹ̀ sẹ́yìn lẹ́yìn tó jáde lọ wá iṣẹ́ lọ
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti wu oku Iniobong Umoren, akẹkọjade to wa iṣẹ lọ ti awọn agbenipa kan si gba ẹmi rẹ.
Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin kan sọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Akwa Ibom, Odiko MacDon ṣalaye pe wọn ti mu afurasi kan lori iku rẹ, o si ti jẹwọ .
O ni afurasi naa lo mu wọn lọ si ibi ti wọn da erupẹ bo oku ọdọbinrin naa sii.
O fi kun un pe wọn ti gbe oku ọmọbinrin naa lọ sile igbokusi kan lati lee ṣe awọn ayẹwo gbogbo to yẹ eyi ti yoo tubọ ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.
Wọn ni afurasi naa fipa ba ọmọbinrin ọhun lopọ, o si tun fi iya jẹ.
'Wọ́n ti pa ọ̀rẹ́ mi o, wọ́n ti sín in'! Ọ̀rẹ́ Iniobong Umoren tó dàwátì ní Akwa Ibom pariwo síta

Oríṣun àwòrán, Twitter
"Wọn ti pa ọrẹ mi o, wọn dẹ tun ti sin ọrẹ mi"
Ariwo ti arabinrin kan @UmohUduak labẹ apejẹ orukọ 'Happiness Activist' fi sita loju opo twitter ree.
Happiness Activist ti kọkọ pariwo sita lọjọ diẹ sẹyin pe ọrẹ oun kan to lọ fun ifọrọwanilẹnuwo fun igbanisiṣẹ lagbegbe Airpot road ni Akwa Ibom di awati.
- Àlàyée Fídíò bí Baba Ijesha ṣe ṣe aṣamaṣe pẹ̀lú ọmọ Princess rèé
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí ètò àbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria kó tó pẹ́ jù - Alaafin, Ooni
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo
- Àsìkò ti tó kí wọ́n yọ Buhari lórí oyè kí àlááfíà lè padà sí Naijiria - PFN, Kukah, Ighodalo
"Ẹyin eeyan mi, ọrẹ mi @HinyHumoren ti wọ inu wahala o si nilo iranlọwọ wa...ṣaaju loni lo sọ fun mi pe oun lọ fun ifọrọwanilẹnuwo fun igbanisiṣẹ lagbegbe Airpot road eyi to jina si ile rẹ."
Nigba ti yoo fi di owurọ ọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu karun un ọdun 2021 ni 'Happiness Activist'ba tun bọ sori Twitter lati kede pe wọn ti pa ọrẹ oun o bẹẹ ni wọn si tun da erupẹ bo o mọlẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ninu ọrọ to ba BBC News sọ arabinrin @UmohUduak to sọrọ pẹlu ẹkun ṣalaye pe "wọn ti pa ọrẹ mi o, wọn ti sin ọrẹ mi"
Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Akwa Ibom, Odiko MacDon ṣalaye fun BBC pe "a ti n pari iwadii lori rẹ, atẹjade yoo jade nipa rẹ laipẹ". Iniobong Umoren, ọmọbinrin to sọnu lọjọ diẹ sẹyin lẹyin to tọ ipasẹ iṣẹ kan ti wọn fun un lati ipinlẹ Akwa Ibom lọ ti jade laye.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Aṣe agba adura ni awọn Yoruba maa n ṣe pe bi a ṣe n wa ohun ti a o jẹ lọ, ki a maa pade ohun ti yoo jẹ wa.
Ọmọbinrin kan, Iniobong Hiny Umoren to wa lati ipinlẹ Akwa Ibom to n wa iṣẹ lo ti di awati bayii.
Awọn ẹbi ati ọrẹ ọmọbinrin naa ko dakẹ rara lori ayelujara papaa julọ lori ẹrọ Twitter ati Facebook lati igba ti Iniobong ti di awati.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Happiness Activist
#FindHinyHumoren lo gbori ẹrọ Twitter eleyi tawọn eeyan lo le lẹgbẹrun lọna ọgọfa n sọrọ le lori.
Ọpọ eeyan lo n beere lori Twitter pe nibo ni ọmọbinrin naa le wa lati ọjọ yii.
- Senior Bukky Black, ìtìjú ńlá lẹ jẹ́ fún ìran obìnrin àti ìyá- Iyabo Ojo
- A kò bá ti lé Baba Ijesha àmọ́ kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, a kò sì fọwọ́ sí ìwà tó hù - Mr Latin
- Àwọn ọlọ́pàá ti fi ṣìkún òfin mú 25 nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa tó ń ṣe ìwọ́de l'Abeokuta - Ilana Omo Oodua
- Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè tún fi tírélà kó ìrẹsì lọ lóru mọ́jú ní Ọjà'ba nílú Ibadan
- Fr Mbaka kọ ẹ̀yìn sí Buhari nítorí kò rí nǹkan jẹ lábẹ́ rẹ̀ - Iléeṣẹ́ Ààrẹ
- Obìnrin tó n wá orí adé láti fi ṣe ọkọ pàdánù ₦51m sọ́wọ́ gbájúẹ̀ l'Eko
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti kede pe ohun ti fọwọ ofin mu eeyan lori bi Iniubong ṣe di awati.
Happiness Activist @UmohUduak1 to jẹ ọmọbinrin naa sọ loju opo Twitter rẹ pe Hiny sọ fun pe oun n lọ fun ifọrọwanilẹnu wo fun iṣẹ nigba ti awọn rira kẹyin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Uduak ṣalaye pe oun fi fọnran kan ṣọwọ si Hiny lori ẹrọ Whatsapp, lẹyin naa loun pe lori ago bo ya o fẹ ba oun sọrọ.
Ṣugbọn Uduak ni ohun ẹkun ọrẹ oun ni oun gbọ nibi to ti n kigbe pe kawọn eeyan gba oun.
Hiny ti kọkọ sọ loju opo Twitter rẹ pe oun n wa iṣẹ eleyii ti ọpọ eeyan si gba a ni imọran lori ibi ti o ti le wa iṣẹ lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ọpọ lo ti gbadura pe ki Hiny pada wale fun ra rẹ laaye lẹyin to ti di awati lati Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹrin.














